Rotimi Akeredolu: Oluwarotimi Akeredolu di gómìnà fún ìgbà kejì ní ìpínlẹ̀

Iburawọle Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, @GboyegaOyetola

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti ṣe ibura lati sin ipinlẹ Ondo ati orilẹede Naijiria.

Gomina Akeredolu ṣe ibura naa lasiko ti wọn burawọle fun un gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ondo ni saa keji.

Lucky Aiyedatiwa to dije dupo gẹgẹ bi igbakeji Akeredolu naa ni wọn ti bura wọle fun ni igba akọkọ gẹgẹ bi igbakeji gomina.

Àkọlé fídíò, Ondo Fulani Herdsmen: Àgbe mẹ́ta ní àwọn Fulani darandaran tún pa Ọ̀wọ̀, Ondo

Aiyedatiwa to wa lati iha guusu ipinlẹ Ondo, wa si ini iburawole naa pẹlu omo ati iyawo rẹ.

Aiyedatiwa ti fi igba kan jẹ kọmisonna fun Ajọ Niger Delta Commission ni ipinlẹ Ondo, ko to di igbakeji Gomina.

Iyawo gomina Akeredolu, Betty Anyanwu, ọmọ ati ọmọọmọ gomina naa lo wa si ibi iburawọle naa.

Àkọlé fídíò, 'Tí mi ò bá rí ògùn rà fún ọmọ mi, á máa gé ara rẹ̀ jẹ tí ẹ̀jẹ̀ yóò máa ṣàn'

Awọn gomina to fi mọ ọkan lara awọn adari ni ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu wa nibi iburawọle to waye ni gbagede Dome, ni ilu Akure, nipinlẹ Ondo.

Saaju ni gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti kede isinmi fun awọn oṣiṣẹ loni ọjọ iburawọle rẹ ni ipinlẹ naa.

Ọpọlọpọ iṣoro lo n koju ipinle naa, to fi mọ eto aabo to dẹnukọle, ijinigbe ati ija laarin awọn agbẹ ati darandaran to ti mu ọpọ ẹmi ṣofo nipinlẹ naa.