Akure, Ondo fire: Ọkẹ́ àìmọye ilé ń jó lọ́wọ́ ní Oyemetu, àwọn ará adúgbò ń tara

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ilu Akurẹ nipinlẹ Ondo ni pe awọn ile ti ko lonka ti gbina ni adugbo Oyemetu.
Gẹgẹ bi awọn ara adugbo ṣe sọ fun akọroyin BBC Yoruba to n ka gbogbo bi iroyin naa ṣe ṣẹlẹ, awọn ni wọn n bu omi, ọṣẹ, iyẹpẹ ati gbogbo ohun ti ọwọ wọn ba ba lati pa ina naa.
Àwà "boys" àdùgbó là ń fara kó iná, gbogbo àwọn panápáná ló sá padà
"Awọn oṣiṣẹ panapana sa lọ, gbogbo ara mi lo tin gbona lataarọ, mo fẹ lọ sile lọ lo ogun".
Ọkan lara awọn ara adugbo to n gbiyanju lati pa ina niyii to mba BBC sọrọ.
Wọn tun sọ fun BBC Yoruba pe ọpẹlọpọ iranwọ ti ọpọlọp n ṣe lo ran awọn lọwọ ti ko fi bọ si ile keji lati eyi to wa laja to kọkọ bẹrẹ si ni jo.
"Ile epo wa lẹgbẹ ile yii amọ a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ọpọlọpọ eniyan n ran wa lọwọ ti ko fi re si ile epo yẹn".
Iroyin ti a tun gbọ ni wipe ile iwe alakọbẹrẹ kan wa lara awọn ile to n jo papọ yii amọ nitori eto iburawọle gomina to n lọ lọwọ lonii ni ko jẹ ki awọn ọmọ wa si ileewe tori gomina ti kede ọjọ naa bi ọjọ isinmi.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post















