Mide Martins: Sir Shina Peters ní ìjà ti parí, Damilare rẹrin músẹ́

Oríṣun àwòrán, Mydemartins
Aridaju fihan pe ẹẹkan pere ni gbajugbaja oṣere, Mide ọmọ oloogbe Funmi Martins da si ọrọ aburo r ti wọn atoun ati Sir Shina Peters ti ololufẹ rẹ nigba naa bi i fun ko tọju.
Lẹyin igba to kọ atẹjade kan soju opo instagram to fi ṣalaye iha tirẹ si ọrọ naa, gbajugbaj oṣere yii ko tun tii kede tabi sọ ohunkohun amọ ọpọ ọrọ lo ti n jade latẹnu Sir shina Peters, Damilare ati ẹgbọn iya rẹ to n gbe lọdọ rẹ.
Gbajugbaja olorin Juju ọmọ Yoruba nni, Sir Shina Peters ti fihan faraye pe ko si aawọ kankan mọ laarin oun ati ọmọ to kọkọ ṣẹnu ku sọ pe "wọn ni oloogbe Funmi Martins bi fun mi". Amọ ohun taa mọ ni pe ko si ẹgbọn rẹ nibẹ lasiko naa.
- Kí ló ṣe ọkùnrin yìí tó dédé ń sá lọ láàrin ìgboro ní ìhòhò ọmọlúàbí?
- Ó ti tó ọdún mẹ́fà, méje tí mo ti rí Àùntí Mide Funmi Martins gbẹ̀yìn, wọ́n tún ṣẹ̀ ń ṣèlérí - Damilare
- Bí àsìkò ikú òṣèré Funmi, ìyá Mide Funmi Martins ṣe roo lágbo òṣèré nígbà náà nìyìí
- Glaucoma lè fọ́ gbogbo ènìyàn lójú tán níbí - Dókìtà Nàìjírìà
- Òní ni ìsìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja
O ti wa han gbangba bayii wipe ọmọ rẹ ni Damilare gẹgẹ bi awọn mejeji iyẹn baba ati ọmọ to fi mọ ẹgbọn iya rẹ to n gbe lọdọ rẹ latọjọ yii ṣe fipade pọ nibi kan lati jọ sọrọ.
Ninu fọnran ti gbajugbaja olorin naa ti n sọrọ o n dupẹ lọwọ awọn eeyan to da si ọrọ yii lati ibẹrẹ.
"Ẹ̀yin ọmọ Naijiria rere, ẹ ṣe o, Damilare ree, baba Deji ree, emi naa Shina Peters ree. Ko si ija ko si ẹta mọ".

Oríṣun àwòrán, Yetunde Olugbenga
Nigba to bi Damilare pe abi bẹẹ kọ lo ri, ẹgbọn oloogbe Funmi Martins dahun pe bẹẹ ni amọ Damilare kọkọ rẹrin musẹ.
"Gbogbo rẹ ti lọ ilẹ, Esu ti pofo o, ẹ ṣe gan ni, Ọlọrun a bukun yin". Lo ba ni ki Damilare ba awọn araale sọrọ.
"Ẹ ṣe gbogbo ẹyin Naijiria. Mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn "fans" mi, lọtun a bukun yin gidi gan lorukọ Jesu".
Lẹyin eyi ni Shina Peters rẹrin gbooro ti oun ati baba Deji si bọ ara wọn lọwọ.
Ẹwẹ, awọn araalu to n woye bi gbogbo nkan ṣe n lọ atawọn to n gbe ọrọ naa ka ti tun kẹnu bọ ọ wipe o ti lọwọ ọlọpaa ninu torii ti Shina Peters ba gbiyanju lati ṣe ohun ti ko tọ lẹyin igbesẹ yii.
Awọn eeyan ni ko sohun ti Shina fẹ ṣe, awọn yoo si da owo lati ran Damilare lọwọ.
















