Glaucoma in Nigeria: Ààrùn Glaucoma lè fọ́ gbogbo ènìyàn lójú

Ènìyàn 1.8 mílíọ̀nù nínú ènìyàn 180 mílíọ̀nù péré ló mọ̀ pé àwọn ni Glaucoma.

Ààrùn ojú glaucoma ló wọ́pọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ Afíríkà ìwọ̀-òrùn àti pé ọ̀pọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà le fọ́ lójú nítorí rẹ̀.

Dókítà Ugochukwu Eze, to n ṣíṣẹ́ pẹ̀lú National Eye Centre Kaduna só pé ààrùn glaucoma tó ń pa àwọn ènìyàn díẹ̀-díẹ̀ nípa bíba àwọn okùn tó so ojú pọ mọ́ ọpọlọ jẹ, tí okùn yìí bá si ti kú tán, ojú ti fọ́ níyẹn.

Olè tó máa n jẹ́ ki ọ̀pọ̀ fọ́ lójú ní ilẹ̀ ìwọ̀-òòrùn Afrika ni Glaucoma jẹ́.

Àkọlé fídíò, 'Tí mi ò bá rí ògùn rà fún ọmọ mi, á máa gé ara rẹ̀ jẹ tí ẹ̀jẹ̀ yóò máa ṣàn'

Tí o bá ṣẹlẹ̀, ẹni náà yóò ma rí ǹkan to ba wà ni tòsí rẹ̀. ṣùgbọ́n yóò dàbi pé ènìyàn ń wo ǹkan níní ihò ni.

Ìròyìn fi yé ní pé ènìyàn 1.8 mílíọ̀nù nínú ènìyàn 180 mílíọ̀nù péré ló mọ̀ pé àwọn ni ààrùn Glaucoma.

Ajó to n moju tó ìgbógun ti ààrun Glaucoma sọ pé, àwọn ènìyàn yìí kéré jọjọ, ọ̀pọ̀ sì ló wà ti kò mọ̀ pé àwọn ni ààrùn ọ̀hún.

Andrew Ikilama

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Andrew Gani Ikilama sọ pé lẹ́yìn àwọn ìlànilóye àwọn míràn yóò l tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ wọn.

Andrew Ikilama to jẹ́ alága àti olùdári ìlànilóye fun awọn afójú ni Kaduna sọ pé, kò sí àmì kankan ti aarun náà má n fi hàn àfi to bá fọ́ ẹni náà lójú pátápáta, ṣùgbọ́n ǹkan tó ṣe pàtàkì ni láti maa ṣe àyẹ̀wò láti ìgbà dé ìgbà.

Àwọn onímọ̀ nípa afójú àti àwọn to ni ìpèníjà ojú nínú ìwádìí wọn sọ pé láti ọmọ ogójí ọdún ni Nàìjíríà ló ni Galucoma jùlọ.

Ìdí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì kò ṣe mójú tó idí tí ọ̀pọ̀ ọmọ Naìjíríà kò ṣe mójú tó ọ̀rọ̀ náà kò yé ẹnikẹni, ṣùgbọ́n wọ́n ni gbogbo ọmọ Naijiría ló wà lábẹ́ ewu náà.

Ǹkan marún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Glaucoma

Bí ole ni Glaucoma ṣe n ṣe. olé kii kéde fún onílé kó tó wá, bẹ́ẹ̀ni kìí kìlọ̀.

  • O sábà máa n tọ ìràn, tí ẹnikan bá ti ni nínú ìdílé, ó ṣe pàtàkì kí àwọn tó kù lọ ṣe àyẹ̀wò ojú wọ́n
  • Ẹni to ba ti pe ọgọta ọdun yóò wa ninú ewu gidigidi.
  • Glaucoma o ni ìwòsàn, sùgbọ́n wọ́n le maa lo òògun ojú lati mu àdínkù tàbí
  • Bí glaucoma bá tilẹ̀ wá jẹ́ kí o fọ́ lójú, ayé rẹ kò le parí síbẹ̀