Àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí àwọn ajìjàgbara Niger Delta ṣèlérí láti kọlu Eko àti Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lẹyin ti awọn ajijagbara Niger Delta ṣeleri pe awọn yoo ṣakọlu si ilu Eko ati Abuja.Ṣaaju ni awọn ajijagbara naa, ti wọn pe ara wọn ni Egbesu Liberation Fighters, ti kọkọ sọ pe awọn yoo kọlu awọn ohun amayedẹrun kan, eyii ti yoo ṣakoba fun eto ọrọ aje Naijiria.Awọn eeyan naa fi ẹsun kan ijọba apapọ pe o mọọmọ kọ lati mu idagbasoke ba agbegbe wọn, ati pe o da owo to n san fun awọn ajijagbara naa duro labẹ eto aforiji.
- Ọkọ mi ni èmi ni mo sòkùnfa ǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Faizat lati inú oyún- Ìyá Faizat
- Fayemi: Àfàìmọ̀ kí ìjọba má bá àwọn jàndùkù ajínigbé sọ̀rọ̀, àmọ́ onímọ̀ nípa ètò àbò ní ...
- Ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ti buwọ́lu àwọn ọ̀gágun tí ààrẹ Buhari yàn sípò, Olonisakin, Buratai gẹ́gẹ́ bi aṣojú Naijiria ní òkò òkun
- Sir Shina Peters ní ẹ ṣé, ìjà ti parí lórí ọ̀rọ̀ tó kan ọmọ olóògbé Funmi Martins; Damilare rẹ́rìín músẹ́ láì sọ̀rọ̀
Agbẹnusọ awọn eeyan naa to lo iboju sọ pe, "lẹyin ti ijọba fọwọ si iwe adehun pẹlu awọn ajijagbara Niger Delta, ko si ile ẹkọ, ko si omi to mọ geere, ko si ina, bẹẹ naa ni ko si ile iwosan ati ọna to dara fun awọn eeyan wa."O ni ko si igbesẹ to lamilaaka kankan ti ijọba apapọ n gbe nipa fifọ epo kuro lori ilẹ Ogoni.Wọn fẹsun kan ijọba apapọ pe o ti sọ ọrọ idagbabsoke agegbe awọn di ọrọ oṣelu, eyii to mu ki awọn eeyan naa maa jiya.Agbẹnusọ awọn eeyan ọhun tẹsiwaju pe "fun ọpọ ọdun, awọn eeyan wa ti gbiyanju lati mu ayipada to to yanranti ba agbegbe wa, ṣugbọn ijọba ko gba fun wọn bẹẹ si ni ko fi ọwọ paaki mu ọrọ naa."Lẹyin naa lo sọ pe awọn ti n gbaradi lati kọlu awọn ileeṣẹ ijọba ati awọn ohun amayedẹrun Naijiria to ṣe pataki lọna ati da oju ọrọ aje Naijiria ru.Ẹwẹ, awọn ajijagbara naa ni wọn fa Aarẹ ana, Goodluck Ebele Jonathan ati gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike kalẹ lati ṣe alarena laarin awọn ati ijọba apapọ ti ijọba ba fẹ ki ọrọ naa yanju.Igbesẹ ti awọn eeyan naa gbe yii ti fa oriṣiriṣ ọrọ lati ẹnu ọpọ ọmọ Naijiria.Bi awọn kan ṣe n sọ pe ohun ti wọn yoo jẹ ni wọn n wa, lawọn miran n sọ pe o yẹ ki wọn mu ileri wọn ṣẹ nitori igbesẹ naa nikan ni ọna kan ṣoṣo ti ijọba apapọ le fi gbo tiwọn.









