Adájọ́ pàṣẹ́ kí LASTMA sàn N750,000 fún awakọ tí wọn gbà N20,000 lọ́wọ́ rẹ

Oríṣun àwòrán, followlastma
Ile ẹjọ giga nipinlẹ Eko ti dajọ wipe ki ajọ to n mojuto irinna ọkọ loju popo ni ipinlẹ Eko,LASTMA ko laṣẹ lati ni ki awakọ ti wọn fura si pe o tapa sofin san owo itanran lalae gbaṣẹ lọwọ ile ẹjọ.
Adajọ Olalekan Oresanya lo gbe idajọ yi kalẹ lasiko to n gbẹjọ ti awakọ kan,Aliyu Toyin Lawal gbe wa sile ẹjọ nibi to ti pe agbẹjọro agba nipinlẹ Eko,ijọba Eko ati ajọ LASTMA lẹjọ.
Ninu iwe ipẹjọ, Lawal beere lọwọ adajọ pe ki wọn kede pe iwa to lodi sofin ni LASTMA hu nigba ti wọn ṣe idiwọ fun loju popo, ti wọn fipa wọ ọkọ rẹ lọ ti wọn si fi ọkọ naa si ahamọ lọdọ wọn.
Bẹẹ lo sọ pe ki adajọ kede pe iwa ti ko bofin mu ni LASTMA hu nigba ti wọn gba owo itanran ẹgbẹrun lọna ogun Naira ati ẹgbẹrun mẹwaa Naira lowo pe wọn wọ ọkọ rẹ lọ.
Lawal ṣalaye fun ile ẹjọ pe wọn gbe igbesẹ yi lalae gbaṣẹ ile ẹjọ ti eleyi si tako ẹtọ rẹ gẹgẹ bi ẹdamọniyan to lẹtọ lati rin nibi to wu.
Lawal beere miliọnu marun-un Naira lowo gba ma binu
Lati oṣu kọkanla ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ LASTMA ti gba ọkọ agbẹjọro yi ni tipa ti wọn si ti bẹrẹ si ni fa ọrọ naa.
Ninu nkan ti arakunrin Lawal beere pe ki ile ẹjọ ṣe fun oun ni ki wọn paṣẹ ki LASTMA, ijọba ipinlẹ Eko ati agbẹjọro agba ipinlẹ naa san owo gba ma binu miliọnu marun un fun oun.
Adajọ gbọ ẹjọ yi lootọ to si ni oun yoo gba gbogbo ibeere ti Lawal gbe wa siwaju ile ẹjọ.
Awọn nkan wọnyi ni pe ki LASTMA da owo itanran N20,000.00 ti wọn gba pada, ki wọn da owo ti wọn gba pe awọn fi wọ ọkọ rẹ,N10,000.00 ati pe ki wọn si san owo gba ma binu fun agbẹjọro yi.

Oríṣun àwòrán, TEMILOLA KOFOWOROLA SOBOLA
Kini adajọ wo to fi da awakọ lare to da LASTMA lẹbi?
Ninu nkan ti adajọ wo to ṣe koko ti awọn araalu mi le jẹ anfaani nibẹ ni pe LASTMA ko gba iwe aṣẹ lọdọ ile ẹjọ ki wọn to fidi ọrọ mulẹ lọwọ ara wọn pe arakunrin naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Gẹgẹ bi adajọ Olalekan Oresanya ṣe wi, ko si ẹri aridaju ti LASTMA mu wa lati le fi kin iwa ti wọn hu yi lẹyin labẹ ofin.
''Mo gbe idajọ kalẹ pe gbigba owo itanran ati owo ti LASTMA gba pe awọn fi wọ ọkọ olupẹjọ yi lalae gba iwe aṣẹ lọdọ ileẹjọ tokajuẹ jẹ ohun tolodi si ofin ti ko si fẹsẹ mulẹ.Tori naa ki wọn san owo itanran ti wọn gba pada fun arakunrin to pẹjọ''
O tẹsiwaju pe ki wọn san owo gba ma binu ẹgbẹrun lọna ọta leni ẹẹdẹgbẹrin Naira N750,000 tori pe wọn tapa si ẹtọ rẹ gẹgẹ bi ẹdamọniyan.
Adajọ fi kun ọrọ rẹ pe ko si ẹri ninu iwe ofin to de iṣakoso irina loju popi to fun wọn laṣẹ lati kọdi ẹtọ araalu lati le lọ ki wọn si bọ lalae si idiwọ.
''Awọn ileeṣẹ ijọba ko gbọdọ hu iwa to lodi si ti yoosi tapa si ẹtọ araalu eleyi ti iwe ofin Naijiria fidi rẹ mulẹ fun wọn''
Bakan naa ni adajọ sọ pe LASTMA wọ ọkọ ti nkankan ko ṣe loju popo ti ẹni to ni ọkọ ko si foju tabi iwa han wipe oun ko ṣetan lati jọwọ ọkọ naa fun wọn.
LASTMA ko le da nikan paṣẹ sisan owo itanran lai bun ile ẹjọ gbọ
Lori ọrọ owo itanran ti LASTMA paṣẹ ti wọn si gba lọwọ awakọ naa, adajọ sọ pe LASTMA lo da nikan fẹsun kan arakunrin naa ti wọn si da ẹjọ koda wọn tungbe ijiya kalẹ lalae fun ni anfaani awijare niwaju ileẹjọ.
Adajọ ṣalaye pe lẹyin agbeyẹwo finifin ohun ti ofin LASTMA sọ ni abala 27 (1) b, c, d ati e, awọn ko ri ibi to ti sọ pe LASTMA le gba owo itanran lọwọ awakọ, lai gbe onitọhun lọsi iwaju ileẹjọ.
Idajọ yi jẹ eleyi ti ọpọ ọmọ Naijiria ni paapa awọn awakọ nipinlẹ Eko ti ri gẹgẹ bi ohun to fi idajọ odoo mulẹ.
Lọpọ igba ni awọn araalu ti n sọ pe gale gale LASTMA pọ ati pe wọn a maa ṣe ofin to wu wọn nipa mimu awakọ ati gbigba owo itanran lọwọ wọn.
LASTMA ko ti fesi si idajọ yi, a ko si mọ boya wọn yoo pẹjọ kotẹmilọrunlori rẹ.












