Security In Nigeria: Afenifere ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìhà tíjọba àpapọ̀ kọ sẹ́kùn Gúúsù àti Àríwá

Ikọ Amotekun

Ẹgbẹ́ Afenifere, tii se ẹgbẹ to ko gbogbo ọmọ Yorùbá papọ, ti fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn lórí ìhà tí ìjọba àpapọ̀ kọ sí àwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ ti ẹkùn gúúsù orílẹ̀ èdè yìí.

Afenifere ní ìyàtọ̀ wà láàárín bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ń ṣe sí àwọn ènìyàn tó wá láti ẹkùn árìwá àti àwọn tó wá láti gúúsù Nàìjíríà.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Afenifere, Jare Ajayi fi síta ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tí ìjọba àpapọ̀ ti ṣe láti fi ìyàtọ̀ láàárín gúúsù àti àríwá pọ̀ púpọ̀ ṣùgbọ́n èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni àwọn fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí.

Ajayi ní ohun tó fa ìdí tí àwọn fẹ́ fi sọ̀rọ̀ lórí èyí ni pé ìpalara tó ń kóbá ètò ààbò àti ìgbáyégbádùn àwọn ènìyàn tó wà ní ilẹ̀ Yorùbá àti ẹkùn gúúsù Nàìjíríà kò kéré.

Ó ní ìròyìn tó jáde pé ìjọba àpapọ̀ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina láṣẹ láti gbà kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí ìpínlẹ̀ náà gbé kalẹ̀ láti máa lo ìbọn àti àwọn ohun ijà tó fi mọ́ AK47 tí kò sì gbà kí àwọn ìpínlẹ̀ ẹkùn gúúsù ṣe bẹ́ẹ̀ kò dára tó.

Ó ní ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí ni ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina kéde èròńgbà láti gba ẹgbẹ́rùn mẹ́ta àwọn ènìyàn sí ikọ̀ Fijilanté láti máa kojú ètò ààbò ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó fi kun pé ẹgbẹ̀tá nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n sì ti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún lórí lílo àwọn nǹkan ìjà ogun tó lágbára tó fi mọ́ AK47.

Ìwà àbòsí ni kí ìjọba àpapọ̀ fi àyè gba ẹ̀ṣọ́ ààbò fijilanté Katsina láti máa lo AK47 ṣùgbọ́n kí wọ́n kọ̀ fún Amotekun láti gbébọn

Ajayi ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu wí pé ìjọba àpapọ̀ le fàyè gba èyí bó ṣe jẹ́ pé ìjọba fárígá láti gba àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun tí àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá gbé kalẹ̀ ní ọdún méjì sẹ́yìn láti jẹ irú àǹfàní yìí.

Ajayi tẹ̀síwájú pé ìdí tí àwọn gómìnà yìí ṣe gbé ẹ̀ṣọ́ Amotekun kalẹ̀ kò yàtọ̀ sí ìdí ìpínlẹ̀ Katsina náà fi ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí à ti lè kojú ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra pàápàá ilẹ̀ Yorùbá.

Ó ní nígbà náà ìjọba kọ̀ láti fún Amotekun láṣẹ láti máa gbé ìbọn ní èyí tí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.

Bákan náà ló tún ní ìjọba kò fàyè gba Amotekun láti máa gbé àwọn tí wọ́n bá mú lọ sí ilé ẹjọ́ fúnra wọn àyàfi kí wọ́n fà wọ́n lé ọlọ́pàá lọ́wọ́.

Ó fi kun ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n fà lé ọlọ́pàá lọ́wọ́ yìí kí wọn kìí kojú ìgbẹ́jọ́ tó péye tí wọ́n sì máa ń tú kalẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láì fi ìyà tó tọ́ jẹ wọ́n.

Agbẹnusọ Afenifere ní tún tẹ̀síwájú pé tí kìí bá ṣe pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn figbe ta lórí àwọn agbébọn ìjọba kò fẹ́ kéde wọn gẹ́gẹ́ bí agbéṣùmọ̀mí àmọ́ ní kíákíá ni ìjọba kojú ìjà sí àwọn ẹkùn gúsúsù tó ń pè fún yíya kúrò lára Nàìjíríà.

Ajayi fi kun pé láti inú oṣù Kẹjọ ni gómìnà ìpínlẹ̀ Benue, Samuel Ortom ti ń bèrè kí ìjọba àpapọ̀ gba àwọn ikọ̀ fijilanté ìpínlẹ̀ náà láyè láti máa lo ìbọn ṣùgbọ́n tí ìjọba àpapọ̀ fi àáké kọ́rí.

Tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kò bá ní lo ìbọn kí ni wọ́n ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún

Ó ní ìdí nìyí tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo ṣe fa ìbínú yọ lórí ọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ ẹ̀ṣọ́ ààbò ìpínlẹ̀ Katsina.

"Gbogbo ohun tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Katsina ń sọ láti fi fún Akeredolu lésì pé àwọn kò gbé ìbọn AK47 lé àwọn fijilanté lọ́wọ́ kò mu tó."

"Tí wọn kò bá ní èròńgbà láti fún wọn ní ìbọn AK47 kí ní wọ́n ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ fún wọn sí? Àti pé ṣe ọwọ́ lásán ni wọ́n fẹ́ fi lọ kojú àwọn agbébọn ni?"

Ìdásílẹ̀ ọlọ̀pàá ìpínlẹ̀ ló le tán ìṣòro ààbò

Afenifere ní ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ kọjá ọ̀rọ̀ láti fi àyè gba Amotekun láti máa lo Ak47 lásán.

Ajayi ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti wà ní ìpele tó jẹ́ wí pé a ò le ṣe láì sí ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.

Ó ní ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ló le tán ìṣòro Nàìjíríà àti pé gbogbo ìpínlẹ̀ tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ló yẹ kí ìjọba àpapọ̀ fún láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Amin iyasọtọ kan

Osinbajo rí ìwé ìpe gbà, yóò sójú ààrẹ Buhari níbí ìsìnkú Obabìnrin Elizabeth ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Aworan Igbakeji aarẹ Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo

Igbakeji aarẹ Naijriia Yemi Osinbajo yoo gbera kuro ni Naijiria lọjọ Abamẹta yi lati lọ kopa nibi ayẹyẹ isinku Ọbabibrin ilẹ Gẹẹsi ni London.

Lasiko irinajo rẹ, yoo ṣoju Naijiria nibi awọn eto kan ti wọn la kalẹ nibi isinku Ọbabinrin Elizabeth to waja laipẹ yi.

Ninu rẹ ni isinku ti ijọba ṣeto fun Ọbabinrin naa.

Ikede to wa lati ọwọ agbẹnusọ igbakeji aarẹ Laolu Akande sọ pe ''ṣaaju eto isinku gaan, Igbakeji aarẹ Osinbajo yoo wa lara awọn eekan ti Ọba Charles ati iyawo rẹ Camilla yoo gba lelejo.''

Bẹẹ lo fi kun pe igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo yoo ṣe ipade kan pẹlu Minisita ilẹ okere ilẹ Gẹẹsi, James Cleverly.

Iwe ipe fawọn eekan ti yoo kopa ninu isinku Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi jẹ eleyi ti awọn eeyan n sọrọ nipa rẹ ni paapa lati mọ ẹni ti yoo wa nibẹ ati ẹni ti ko ni wa.

Ọpọ awọn olori orileede ni yoo wa nibi ayẹyẹ yi ṣugbọn awọn miran ko ni si nibẹ.

O fẹẹ to awọn alejo pataki ẹẹdẹgbẹta ti wọn fiwe pe sibi eto isinku yi kaakiri agbaye.

Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo yoo pada si Naijiria lọjọ Aje lẹyin eto isinku yi.

Nibo laarẹ Buhari yoo wa lasiko isinku yi?

Aarẹ̀ Buhari ati ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi Elizabeth nigba aye rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ,Aarẹ Naijiria ko ni kopa nibi eto isinku yi ko si ni ohun ṣe pẹlu boya wọn ko fi iwe pe aarẹ Buhari.

Lasiko isinku yi, aarẹ Buhari ati iyawo rẹ Aisha Buhari yoo gbera lọ si New York lati kopa nibi ipade apero ajọ isọkan agbaye,UN.

Nibi apero yi, a gbọ pe ọjọ Aiku ni aarẹ Buhari yoo gbera kuro ni Naijiria ati pe yoo sọrọ niwaju ipade naa lỌjọru tii ṣe ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹsan.

Yatọ si eyi, aarẹ yoo tun kopa nibi awọn ipade ti yoo da lori ọrọ aje ati ajọṣepọ laarin Naijiria ati awọn ilẹ mii.