Ọba Charles Kẹta yóò ṣe àìsùn lẹ́gbẹ́ẹ̀ òkú ìyá rẹ̀, Ọbabìnrin Elizabeth

Oríṣun àwòrán, AP
Nibayii, wọn ti gbe posi oku Ọbabinrin Elizabeth Keji sori pepele ni ijọ St. Giles Cathedral ni Edinburgh. Ohun to si kan lalẹ yii ni pe Ọba Charles Kẹta yoo pada lọ si ijọ St. Giles Cathedral ni Edinburg láti ṣe àìsùn mọ́jú lati yẹ oloogbe iya rẹ si. Yoo duro si ẹgbẹ kan lori pepele ti posi oku Ọbabinrin wa. Bakan naa, ireti wa pe awọn ọmọ iya rẹ naa yoo to ara wọn si igun mẹta to ku.
Ki ni eyi tumọ si?

Ilana yii ti wọn n pe ni "Aisun awọn Arẹmọ - ni wọn kọkọ ṣe iru ẹ ni ọdun 1936 nigba ti Ọba dward Kẹjọ ati awọn arakunrin rẹ mẹta to ku, Arẹmọ Albert, Henry ati George duro si ẹba posi baba wọn to di oloogbe, Ọba George Karun lati ṣe aisun. Lati igba naa lọhun, ẹẹkan ṣpṣo ni wọn tun ti ṣe iru eyi. Asiko naa si ni igba isinku Iya Ọba lọdun 2002. Ọba nigba naa ti a mọ si Arẹmọ Charles wa lara awọn to duro ti oku naa lọjọ ọhun.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju alẹ lonii?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eyi jẹ asiko ti ọpọlọpọ eeyan ni Edinburgh ti n duro de lati aarọ - anfani lati bojuwo posi oku Ọbabinrin ki wọn si ṣe ibọwọ ikẹhin fun un. Wọn fun awọn to ni ipenija ara ti wọn joko sori kẹkẹ arọ lanfani naa lati wọ inu ile. Lati ago meje owurọ ni awọn eeyan kan ti n to lati rii pe wọn ri ẹgba ọwọ ti wọn fi n raye wọle gba. Gba gba gba lawọn ọmọ ogun King’s Body Guard ti Scotland duro yi posi naa ka ati pe Ọba Charles yoo duro ṣe aisun lẹgbẹ posi naa lalẹ oni.

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, Reuters









