Ta ni Ọba Charles Kẹta?

Àkọlé fídíò, Ní ọdún 1948 ni Ọlọ́run fi Ọba Charles ta Ọbabìnrin Elizabeth àti Duke Edinburgh lọ́rẹ
Ta ni Ọba Charles Kẹta?

Ní ọdún 1948 ni Ọlọ́run fi Ọba Charles ta Ọbabìnrin Elizabeth àti Duke Edinburgh lọ́rẹ.

Ní ọdún 1957 ló bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ tó sì darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ọmọ ogun lọ́dún 1971.

Ó dá àjọ ẹlẹ́yinjú àánú tó pè ní Prince Trust sílẹ̀ lọ́dún 1976.

Ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Diana Spencer lọ́dún 1981 tí wọ́n sì bí ọmọ méjì, William àti Harry, kí wọ́n tó pínyà lọ́dún 1996.

Ọdún 2005 ló fẹ́ ìyàwó míì, Camilla tó di olorì tuntun fún orílẹ̀ èdè UK báyìí.