Àwòrán àwọn ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ṣe àbẹ̀wò sí ilẹ̀ Adúláwọ̀ fún ìbáṣepọ̀ tó dánmọ́rán

Àkójọpọ̀ àwọn àwòrán lórí àwọn ìbáṣepọ̀ tó dára láàárín Ọbabìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Adúláwọ̀ nígbà ayé rẹ̀.

Ọbabìnrin àti Olusegun Obasanjo lọ́dún 2003

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin Elizabeth àti Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo nígbà tí ọbabìnrin náà ṣe àbẹ̀wò sí Nàìjíríà fún ìgbà kejì lọ́dún 2003. Nígbà ìjọba ológùn lábẹ́ ìdarí Sani Abacha ni Commonwealth ti fi òfin de Nàìjíríà lọ́dún 1995 fún títẹ ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn lójú mọ́lẹ̀ kí wọ́n tó gba Nàìjíríà wọlé padà lọ́dún 1999 nígbà tí ìjọba padà sọ́wọ́ alágbádá. Níbi ìṣíde ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀ èdè Commonwealth ni Ọbabìnrin àti Obasanjo ti ya àwòrán yìí.
Ọbabìnrin Elizabeth II

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin Elizabeth II, lásìkò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ṣàbẹ̀wò sí àwọn orílẹ̀ èdè tó lé ní igba, ní èyí tó ṣ òkunfà bí àwọn orílẹ̀ èdè kan ṣe gba òmìnira lábẹ́ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àjọ̀ṣe kan pàtàkì tó wà láàárín ilẹ̀ Britain àti àwọn orílẹ̀ èdè tó wà ní abẹ́ Commonwealth èyí tí Ọbabìnrin ń darí. ìbáṣepọ̀ náà jẹ́ èyí tó dánmọ́rán àmọ́ tó ní ìpèníjà nínú.
Queen Elizabeth pẹ̀lú Oba Adenji-Adele II

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìgbà àkọ́kọ́ tí Ọbabìnrin Elizabeth yóò ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́dún 1956 nígbà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣì wà lábẹ́ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọbabìnrin Elizabeth nínú àwòrán yìí ń bá Ọba Èkó ìgbà náà, Ọba Adeniji-Adele II sọ̀rọ̀ ní ìlú Èkó. Bákan náà ló tún ṣàbẹ̀wò sí Calabar, Enugu, Jos, Kaduna, Kano àti Port Harcourt.
Ọbabìnrin Elizabeth II àti Nelson Mandela

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin Elizabeth àti Ààrẹ Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ fún orílẹ̀ èdè South Africa, Nelson Mandela ní ìbáṣepọ̀ tó dára tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́. Ọbabìnrin buwọ́lu ìwé tó kọ ránṣẹ́ sí Ààrẹ Mandela pẹ̀lú ọ̀rọ̀ pé "Ọ̀rẹ́ rẹ̀ pàtàkì, Elizabeth R" tí wọ́n sì máa ń pé ara wọn ní orúkọ èyí tó yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe máa ń bá orí ade sọ̀rọ̀.
Ọbabìnrin Elizabeth II balẹ̀ sí pápákọ̀ Durban, South Africa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwòrán Ọbabìnrin Elizabeth ní pápákọ̀ òfurufú Durban nígbà tó ṣàbẹ̀wò ọlọ́jọ́ mẹ́fà sí South-Africa lọ́dún 1995. Ọdún náà ni ojó rọ̀ jù ní South Africa lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí irú òjò bẹ́ẹ̀ ti rọ̀ sẹ́yìn èyí tó fàá tí wọ́n fi fun ní oríkì Motlalepula, tó túmọ̀ sí "Amójòwá.
Ọbabìnrin Elizabeth II ń bá Ààrẹ Kwame Nkrumah jó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ní ọdún 1961 ni Ọbabìnrin Elizabeth ń bá Ààrẹ àkọ́kọ́ Ghana, Kwame Nkrumah jó nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè náà lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí Ghana gba òmìnira. Orin kan tí wọ́n kanlẹ̀ ṣe fún Ọbabìnrin tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní Káàbọ̀ Ọlọ́lájùlọ ni wọ́n ń jó sí.
Ọbabìnrin ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ni Ọbabìnrin Elizabeth wà nínú àw]orán yìí nígbà tó ń jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfarajìn rẹ̀ sí iṣẹ́ ìsìn Commonwealth gẹ́gẹ́ bí ọmọọbabìnrin nígbà náà lọ́hùn-ún ní ilé ìjọba South Africa ní Cape Town láti ṣàmì ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀. "Gbogbo ibi tí mo dé ni South Afrrica yìí...àwọn ènìyàn ń fi ìfẹ́ hàn sí èmi, àwọn òbí mi àti àbúrò mi èyí tó jẹ́ kó dàbí wí pé ilé náà ni a wà."
Àwòrán Ọbabìnrin Elizabeth pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ ní Ethiopia lọ́dún 1965

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin àti Ọmọọba Philip nínú àwòrán pẹ̀lú Emperor Haile Selassie I ti Ethiopia ní Addis Ababa nígbà tí wọ́n 'ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè náà lọ́dún 1965. Ní ọdún 1936 sí ọdún 1946 ni emperor náà lọ se àtìpó ní United Kingdom nígbà tí àwọn ara Italy gba ìlú mọ lọ́wọ́ kí wọ́n tó da padà sórí oyè lọ́dún 1941 lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Commonwealth ṣẹ́gun fún-un.
Ọbabìnrin Elizabeth àti Ààrẹ Sudan El Tigani El-Mahi ti Sudan nínú ọkọ̀ lọ́dún 1965

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin Elizabeth àti Ààrẹ Sudan El Tigani El-Mahi nínú ọkọ̀ nígbà tí wọ́n kúrò ní pápákọ̀ òfurufú lọ́dún 1965 bákan náà. Àbẹ̀wò rẹ̀ sí Sudan dá lórí ìdíje ràkúnmí gígùn àti àbẹ̀wò sí Roseires Dam tí wan ń kọ́ lọ́wọ́ sí Blue Nile èyí tí wọ́n parí ní ọdún tó tẹ̀le.
Ní ilé ìtura Treetops ni Ọbabìnrin Elizabeth àti ọkọ rẹ̀, Duke ti Edinburgh ti ya àwòrán yìí lọ́dún 1952.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ní ilé ìtura Treetops ni Ọbabìnrin Elizabeth àti ọkọ rẹ̀, Duke ti Edinburgh ti ya àwòrán yìí lọ́dún 1952. Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n ya àwòrán yìí ló gba ìròyìn wí pé bàbá rẹ̀, Ọba George VI ti jáde láyé, tí yóò sì di ọba.
Ọbabìnrin Elizabeth II àti Ààrẹ Yoweri Museveni

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìrìnàjò tí Ọbabìnrin Elizabeth ṣe si ilẹ̀ adúláwọ̀ ní ọdún 2007 ni èyí tó ṣe kẹ́yìn tí ọlọ́ja fi dé. Ìgbà náà ló pàdé ààrẹ tó pẹ́ jùlọ lórí oyè ní ilẹ̀ adúláwọ̀, Yoweri Museveni ti Uganda. Ó ti ṣaájú ṣe àbẹ̀wò sí Uganda lọ́dún 1954 nígbà tó ń lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri ilẹ̀ adúláwọ̀.
Ọbabìnrin Elizabeth fi oyè knighthood dá Ààrẹ Zimbabwe, Robert Mugabe lọ́lá lọ́dún 1994.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọbabìnrin Elizabeth fi oyè knighthood dá Ààrẹ Zimbabwe, Robert Mugabe lọ́lá lọ́dún 1994. "Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí nǹkan kò dán mọ́ láàárín ìjọba Zimbabwe àti ti United Kingdom nítorí ètò kan tí Mugabe ṣe àti àwọn ẹ̀sùn títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ ni Zimbabwe kúrò ní Commonwealth lọ́dún 2003 tí wọ́n ssì gba oyè náà kúrò lọ́wọ́ Mugabe lọ́dún 2008.
Àwòrán Ọbabìnrin Elizabeth pẹ̀lú Ààrẹ Tanzania, Julius Nyerere lọ́dún 1979

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ní ọdún 1979 ni Ọbabìnrin ṣe àbẹ̀wò sí Tanzania fún ọjọ́ mẹ́ta. àwòrán yìí ṣàfihàn Ọbabìnrin Elizabeth àti ààrẹ Tanzania, Julius Nyerere. Fún ọdún méjìdínlógún ṣáájú àkókò náà ni Nyerere gba òmìnira fún orílẹ̀ èdè náà lọ́wọ́ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó sì di olóòtú ìjọba àkọ́kọ́ àti ààrẹ àkọ́kọ́ fún orílẹ̀ èdè náà. Nígbà tó yá ló bẹ̀rẹ̀ sí ní tako ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Yúróòpù àmọ́ síbẹ̀, ìjọba UK gbàá lọ̀gàá fún bó ṣe mú ẹkùn rẹ̀ dúró ṣinṣin.