Queen Elizabeth II: Wo bí àwọn ìlànà ìsìnkú Ọbabìnrin yóò ṣe wáyé lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ọpọ ọjọ ti wọn ti tẹ posi oku Ọbabinrin nitẹ ẹyẹ, iyoku ara rẹ yoo bẹrẹ irinajo ikẹyin laarọ oni ọjọ Aje gẹgẹ bi ara eto isinku alarinrin ti wọn la kalẹ - yoo kọkọ lọ si ile ijọsin Westminster Abbey, fun akanse isin idagbere niwaju ẹgbẹlẹgbẹ eeyan, lẹyin naa ni yoo lọ si Winsor Castle fun isin idagbere miran, ki wọn to wa lọ sin oku rẹ ni idakọnkọ.
Oni yoo jẹ ọjọ ayẹyẹ eyi ti ko tii waye mọ lati igba ti wọn ti se ayẹyẹ isinkua alarinrin kẹyin fun Winston Churchill ni bii ọgọta ọdun sẹyin. Koda, Ọbabinrin funra gan se afikun si awọn ilana isinku naa, gẹgẹ bii aafin Buckingham ti sọ.
Wo bí àwọn ìlànà ìsìnkú Ọbabìnrin yóò ṣe wáyé lónìí ọjọ Aje, ọjọ Kọkandinloguun osu Kẹsan.

Aago mẹfa abọ aarọ ni wọn yoo tẹ oku Ọbabinrin nitẹ ẹyẹ, ti awọn eeyan to kẹyin yoo si to lọwọọwọ kọja lara posi rẹ.

Wọn yoo silẹkun Westminster Abbey fun isinku naa ni aago mẹjọ aarọ.
Nigba to ba di aago mọkanla kọja isẹju mẹrindinlogun, wọn yoo gbe posi Ọbabinrin pẹlu ọkọ ẹlẹsin.
Awọn eeyan yoo si to ni ọwọọwọ lati aafin lọ si Westminster Abbey, tawọn ọmọ ogun oju omi yoo si maa yin ibọn.
Ọdun 1979 ni wọn lo ọkọ ẹlẹsin naa kẹyin lasiko isinku aburo baba Ọmọọba Phillip, eyiun Ọlọla Mountbatten, ti awọn awakọ oju omi mejilelogoje latinu ikọ ologun oju omi yoo maa wa.
Ọmọọba Charles Kẹta yoo maa rin bọ lẹyin ọkọ ẹlẹsin naa pẹlu ọmọọba obinrin, Duke ti York ati Earl ti Wessex.
Lẹyin naa ni awọn ọmọọmọ Ọbabinrin yoo to tẹle wọn, eyiun Ọmọọba Wales, Duke ti Sussex ati Peter Phillips.

Isin ikẹyin ti yoo waye ni Westminster Abbey fun Ọbabinrin.
Awọn ologun ilẹ Scotland ati Ireland, ọ̀wọ́ ologun Gurkhas ati ologun ofurufu , ti apapọ wọn to igba niye, ni yoo fi ilu ati orin gbe.
Aago mọkanla ku isẹju mẹjọ ni wọn yoo gbe posi Ọbabinrin de Abbey, ti isin idagbere yoo si bẹrẹ ni aago mọkanla aarọ.
Ni aago mejila ku isẹju marun, ni wọn yoo fọn ipe ikẹyin, ti idakẹ rọrọ isẹju meji yoo si waye ni Abbey ati ni jake jado ilẹ UK.
Orin ibilẹ ilẹ UK ti afọnfere ọba yoo kọ, ni wọn yoo fi kasẹ isin idagbere naa nilẹ ni deede aago mejila ọsan.
Lara awọn alejo ẹgbẹrun meji ti yoo peju sibi isinku naa ni awọn idile ọba, awọn eekan oselu nilẹ UK atawọn olori orilẹede jakejado agbaye, atawọn ẹgbẹ alaanu ti bvabinrin n se atilẹyin fun.
Lẹyin isin idagbere naa, wọn yoo to lọwọọwọ tẹle posi naa lati Westminster Abbey lọ si Wellington Arch.
Ọba ati awọn mọlẹbi ninu idile ọba ni yoo maa rin tẹle posi naa.

Aago mẹrin irọlẹ ni wọn yoo se isin fifi eeru fun eeru.
Ẹtahoro ero ti wọn jẹ kikida awọn eeyan to sunmọ Ọbabinrin nigba aye rẹ, ti wọn ko ju ẹgbẹrin lọ, ni yoo peju sibi isin naa.
Olori ile Windsor, David Conner ni yoo dari isin naa, ti Bisọọbu agba ti Canterbury, Justin Welby yoo si sure fun wọn.

Lẹyin eyi ni wọn yoo gbe iyoku ara Ọbabinrin si itẹ oku awọn idile ọba.
Ni ọwọ irọlẹ lẹyin isin idakọnkọ ti yoo waye ninu ile ijọsin niranti King George VI to wa ninu ile ijọsin St George, ni wọn yoo sin Ọbabinrin sẹgbẹ ọkọ rẹ, Duke ti Edinburgh.


Queen Elizabeth II: Bí ìgbésẹ̀ ìsìnkú yóò ṣé lọ lójoojúmọ́ rèé

Oni ọjọ Aje, tii se ọjọ isinmi Bank Holiday nilẹ UK, ni isinku Ọbabinrin Elizabeth Keji to waja.
Aago mẹfa abọ aarọ ni wọn yoo tẹ oku Ọbabinrin nitẹ ẹyẹ, ti awọn eeyan to kẹyin yoo si to lọwọọwọ kọja lara posi rẹ.
Wọn yoo silẹkun Westminster Abbey fun isinku naa ni aago mẹjọ aarọ.
Nigba to ba di aago mọkanla kọja isẹju mẹrindinlogun, wọn yoo gbe posi Ọbabinrin pẹlu ọkọ ẹlẹsin.
Awọn eeyan yoo si to ni ọwọọwọ lati aafin lọ si Westminster Abbey, tawọn ọmọ ogun oju omi yoo si maa yin ibọn.
Ọdun 1979 ni wọn lo ọkọ ẹlẹsin naa kẹyin lasiko isinku aburo baba Ọmọọba Phillip, eyiun Ọlọla Mountbatten, ti awọn awakọ oju omi mejilelogoje latinu ikọ ologun oju omi yoo maa wa.
Ọmọọba Charles Kẹta yoo maa rin bọ lẹyin ọkọ ẹlẹsin naa pẹlu ọmọọba obinrin, Duke ti York ati Earl ti Wessex.
Lẹyin naa ni awọn ọmọọmọ Ọbabinrin yoo to tẹle wọn, eyiun Ọmọọba Wales, Duke ti Sussex ati Peter Phillips.
Isin ikẹyin ti yoo waye ni Westminster Abbey fun Ọbabinrin:
Awọn ologun ilẹ Scotland ati Ireland, ọ̀wọ́ ologun Gurkhas ati ologun ofurufu , ti apapọ wọn to igba niye, ni yoo fi ilu ati orin gbe.
Aago mọkanla ku isẹju mẹjọ ni wọn yoo gbe posi Ọbabinrin de Abbey, ti isin idagbere yoo si bẹrẹ ni aago mọkanla aarọ.
Ni aago mejila ku isẹju marun, ni wọn yoo fọn ipe ikẹyin, ti idakẹ rọrọ isẹju meji yoo si waye ni Abbey ati ni jake jado ilẹ UK.
Orin ibilẹ ilẹ UK ti afọnfere ọba yoo kọ, ni wọn yoo fi kasẹ isin idagbere naa nilẹ ni deede aago mejila ọsan.
Lara awọn alejo ẹgbẹrun meji ti yoo peju sibi isinku naa ni awọn idile ọba, awọn eekan oselu nilẹ UK atawọn olori orilẹede jakejado agbaye, atawọn ẹgbẹ alaanu ti bvabinrin n se atilẹyin fun.
Lẹyin isin idagbere naa, wọn yoo to lọwọọwọ tẹle posi naa lati Westminster Abbey lọ si Wellington Arch.
Ọba ati awọn mọlẹbi ninu idile ọba ni yoo maa rin tẹle posi naa.
Aago mẹrin irọlẹ ni wọn yoo se isin fifi eeru fun eeru.
Ẹtahoro ero ti wọn jẹ kikida awọn eeyan to sunmọ Ọbabinrin nigba aye rẹ, ti wọn ko ju ẹgbẹrin lọ, ni yoo peju sibi isin naa.
Olori ile Windsor, David Conner ni yoo dari isin naa, ti Bisọọbu agba ti Canterbury, Justin Welby yoo si sure fun wọn.
Lẹyin eyi ni wọn yoo gbe iyoku ara Ọbabinrin si itẹ oku awọn idile ọba.
Ni ọwọ irọlẹ lẹyin isin idakọnkọ ti yoo waye ninu ile ijọsin niranti King George VI to wa ninu ile ijọsin St George, ni wọn yoo sin Ọbabinrin sẹgbẹ ọkọ rẹ, Duke ti Edinburgh.
Posi Ọbabinrin yoo wa ni itẹ oku ni gbọngan Westminster fun odidi ọjọ kẹrin, eyi si ni ọjọ to kẹyin ti isinku yoo fi waye.
Ojoojumọ ni wọn fi si gbọngan naa silẹ lai ti ilẹkun rẹ fawọn araalu lati maa to kọja lẹba posi naa, ti wọn si n bu ọ̀wọ̀ ikẹyin oku Ọbabinrin, eyi ti yoo waye di aago mẹfa aarọ ọjọ Aje.
Awọn to ba si nifẹ lati bu ọwọ ikẹyin yii naa le maa wo bo se n lọ loju opo BBC lagbaye.
Amọ awọn ilana igbesẹ yii ni yoo maa waye ni ojoojumọ.
Oni yii ni ọjọ kẹrin ti wọn ti tẹ posi Ọbabinrin ni itẹ ẹyẹ ni gbọngan Westminster, oni yii naa si ni asekagba igbesẹ titẹ posi naa ni itẹ ẹyẹ.
Awọn araalu ni wọn n to lọwọọwọ kọja lara posi Ọbabinrin ti wọn ko si silẹ, eyi ti wọn gbe ka ori pepele kan.
Ẹgbẹlẹgbẹ awọn olubanikẹdun lo ti bu ọ̀wọ̀ ikẹyin fun Ọbabinrin naa ti ile nla ti wọn pe ni 11th Century, eyi to jẹ abala to tii pẹ julọ ninu aafin Westminster.
Obitibiti ero si lo to sori ila gbọọrọ, koda, o ti gun de South Bank, kọja National Theather, lọ si Tate Modern ati HMS Belfast titi de Southwark Park.
Ijọba ilẹ UK ti wa tẹ iwe atọnisọna kan sita fun awọn eeyan lati maa tẹle loju opo ayelujara YouTube.
To ba si ni ibeere lori awọn nnkan to le mu dani ati eyi ti o ko le mu wọle sibẹ, lọ ka iwe atọnisọna naa.

Ni deede aago mẹjọ alẹ, wọn yoo se idakẹjẹẹ isẹju kan jakejado ilẹ UK, ti wọn si gba awọn eeyan niyanju lati se eto idakẹjẹẹ naa ninu ile wọn, loju popo pẹlu awọn aladugbo tabi nibi ipejọpọ awujọ tabi isọ oru.
Saaju idakẹjẹẹ naa, akanse isin adura yoo waye ni Kelpies, nibi ti ère ẹsin to ga to iwọn ẹsẹ bata mejidinlọgọrun wa, to si wa lẹba Falkirk.
Atupa mẹrindinlọgọrun - atupa ọkọọkan fun iye ọdun kọọkan ti Ọbabinrin lo - ni wọn yoo tan lori omi to yi ere ẹsin naa ka.
Awọn Olori orilẹede nireti wa pe wọn yoo bẹrẹ si ni de silu London fun ayẹyẹ isinku Ọbabinrin.
Diẹ lara wọn nireti wa pe wọn yoo fi ọwọ si iwe ibanikẹdun ni ile Lancaster.
Ọba Charles Kẹta yoo ba Olootu ijọba UK, Liz Truss fikunlukun ni aafin Buckingham. Ọba ati olori rẹ, Camilla yoo tun gbalejo awọn olori orilẹede pẹlu awọn alejo pataki lati ilẹ okeere nibi akanse alarinrin naa.
Nigba to ba di ọsan gangan, Olootu Ijọba yoo pade pọ pẹlu awọn olori orilẹede lati ilẹ okeere, to fi mọ Micheal Martin ti Taoiseach, Justin Trudeau to jẹ olootu ijọba ni Canada, aarẹ Andrzej Duda ti Poland ati aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden.

Oni Ojo Abameta, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kesan an yii ni ọjọ keta ninu ọjọ mẹrin ti oku Obabinrin Elizabeth yoo lo ni ibẹ.
Gbongan yii si ni ara Obabinrin elizabeth yoo wa titi ti wọn yoo fi lọ sin in sile ikẹyin rẹ.
Koda, won ti gba awọn ero niyanju pe ki awọn mii ma rinrinajo mọ lati wa wo oku Obabinrin nitoripe ila naa ti gun ju lasiko yii nitori pe ero ti pọ ju ti wọn fẹ bu ọla fun un.
Opo ero lo ti n wa bu ọla ikẹyin fun Obabinrin nigba ti wọn ṣi tun n reti ọpọlọpọ ero lati wa ba wọn kẹdun nibẹ.
Ni ile nla 11th - Century to jẹ ile apa ibi ti wọn ti kọ tipẹ lati ọdun gbọgbọrọ sẹyin ni posi naa yoo wa.
Iya Obabinrin Elizabeth ni wọn tẹ oku rẹ sinu ile nla yii kẹyin lọdun 2002 nigba to salaisi.
O le ni ẹgbẹrun lọna igba eeyan to wa wo oku Iya Obabinrin Elizabeth nigba naa.

Bayii ni yoo ṣe waye lọjoojumọ.
Wọ́n yoo gbe Posi Obabinrin Elizabeth kuro ni aafin Buckingham lọ si gbongan nla Westminster loni.
To ba ti di ọsan ni awọn ọmọ ogun yoo maa yan bi ologun lati bu ẹyẹ fun oloogbe naa.
Ni Westminster ni won yoo tẹ oku Obabinrin Elizabeth si fún ọjọ mẹrin ṣaaju eto isinku rẹ ti yoo waye lọjọ aje to m bọ.
Awọn eeyna yoo ni anfani lati wa maa wo oku Obabinrin naa.

Oríṣun àwòrán, BBC News
- Kíló kàn? Lónìí ni òkú Obabìnrin Elizabeth yóò kúrò ní Buckingham ló sí Westminster Hall pẹ̀lú ikọ̀ ọmọ ogun
- Mọ̀ síi nípa ìlànà ìsìnkú àwọn Orí adé ni Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí àti bí o ṣe yàtọ̀
- Ọba Charles Kẹta yóò ṣe àìsùn lẹ́gbẹ́ẹ̀ òkú ìyá rẹ̀, Ọbabìnrin Elizabeth
- Queen Elizabeth: Àwọn ìgbà tí Ọbabìnrin ṣe àwàdà tó pa àwọn èèyàn lẹ́rìín rèé
- Ta ni yóò lọ, ta ni kò ní lọ- Àwọn wo ló gba ìwé ìpè síbi ìsìnkú Ọbabìnrin Elizabeth-

Lónìí ni òkú Obabìnrin Elizabeth yóò kúrò ní Buckingham ló sí Westminster Hall pẹ̀lú ikọ̀ ọmọ ogun

Oríṣun àwòrán, BBC News
Posi Ọbabinrin ti gbera kuro ni Balmoral, lọ si Edinburgh saaju eto isinku Ọbabinrin Elizabeth keji lọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, osu kẹsan an.
Awọn eeyan yoo ni anfani lati bu ọla ikẹyin fun Ọbabinrin Elizabeth keji, bi wọn ba ṣe gbe oku rẹ de Aafin Holyroodhopuse ati gbọngan Westminster fun awọn eeyan lati wo posi naa- eto ilana to jẹ isẹnbaye.
Ọba Charles kẹta yoo bẹrẹ irinajo lọ si awọn orilẹ-ede mẹrin to parapọ to di ilẹ̀ United Kingdom (UK).

Posi Ọbabinrin Elizabeth keji, eyi to joko ni gbọngan Balmoral, ni awọn osisẹ ti gbe si ọkọ a gbe ọku.
Oku rẹ kuro ni Balmoral ni deede agogo mẹwaa, ti o si rọra rin fun wakati mẹfa lọ si Edinburgh to to kilomita marundinlọgọsan an.
Maapu ṣe afihan ni irinajo naa ṣe bẹrẹ ati bi irinajo naa ṣe gba Aberdeen, Dundee ati Perth.
Posi naa si balẹ si Aafin Holyroodhouse- ilegbe awọn Ori ade ilẹ Gẹẹsi ni olu ilu Scotland, ti wọn si tẹ ẹ silẹ ninu Iyara Itẹ ti wọn n pe ni Throne Room.

Niluu London, Ọba Charles kẹta yoo ṣe ipade pẹlu awọn akọwe agba fun ajọ isọkan Commonwealth ni Aafin Buckingham.
Bakan naa ni yoo ma a gbalejo awọn olori orilẹ-ede to jẹ le lori ni iyara igbalejo Bow's Room ni Aafin rẹ.
Bí ètò ìsìnkú yóò ṣe lọ lójoojúmọ́ rèé títí Obabìnrin yóò fi wọ káà ilẹ̀

Ọba Charles kẹta yoo bẹrẹ ọjọ naa pẹlu irinajo lọ si gbọngan Westminister nibi ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin mejeeji yoo ti ma a daro Ọbabinrin.
Pẹlu iyawo rẹ Camilla, Olori Ọba, Ọba Charles yoo gbera lọ si Edinburgh.
Eyi wa lara irinajo 'Operation Spring Tide' to jẹ irinajo akọkọ kaakiri awọn orilẹ-ede to wa labẹ ile UK to jẹ Ọba.

Lọsan, posi Ọbabinrin yoo gbera lọ si ile jọsin St Giles pẹlu Ọba ati awọn mọlẹbi Ori Ade.
Ọba Charles yoo pada si Aafin Holyroodhouse, nibi ti yoo ti lọ ba olootu ijọba Scotland, Nicola Sturgeon.
Oun pẹlu Olori Camilla, Obabinrin Consort yoo wa gbera lọ ile aṣofin orilẹ-ede Scotland ni bi ti wọn ti ma a ki i ku ọrọ eeyan.
Ni asalẹ, Ọba Charles yoo ṣe isin pẹlu awọn mọlẹbi ori ade ni ile jọsin St Giles nibi ti won yoo tẹ e si.

Ọmọbabinrin Ori Ade, Ọmọbinrin Anne, to jẹ ọmọbinrin kan soso fun Ọbabinrin Elizabeth yoo tẹle posi Ọbabinrin lati ile ijọsin St Giles lọ si papa ofurufu Edinburgh, ki wọn to tẹ ọkọ baalu ileeṣẹ ọmọ ologun leti.
Irinajo ofurufu ikẹyin ree fun Ọbabinrin Elizabeth keji lati ilu Scotland lọ si London ni deede ago meje alẹ.
Lati ibẹ, wọn yoo gbe oku Ọbabinrin lọ si Aafin Buckingham. Ọba ati Olori Camilla yoo si ri posi naa ki wọn to gbe e lọ si iyara lati sinmi.
- Queen Elizabeth II: Níbo àti ìgbà tí ètò ìsìnkú Obabìnrin Elizabeth máa wáyé?
- Wọn kéde ọba Charles Kẹta bii Ọba - Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìkéde náà tó wáyé lórí afẹ́fẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́?
- Charles kọrin re ki saa isejọba Ọbabìnrin bí wọ́n ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bíi Ọba
- Kí ni Ọba Charles sọ nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tó bá ìlú sọ?
- Bí ètò Ọba jíjẹ àtàwọn tó le jọba ṣe yípadà rèé
Ki o to di igba naa, Ọba ati Camilla yoo ṣe abẹwo si Belfast lorilẹ-ede Northern Ireland.
Wọn yoo tun rinrin ajo lọ Aafin Hillsborough lati mu ibasepo ọlọjọ pipẹ ti Ọbabinrin ni pẹlu wọn dan mọran si i.

Ọba Charles yoo ṣe ipade pẹlu akọwe agba fun orilẹ-ede Northern Ireland, Chris Heaton-Harria pẹlu awọn oloṣelu miiran.
Yoo tun tẹwọ gba iwe ikẹdun lọwọ Abẹnugan ile igbimọ asofin Northern Ireland, Alex Maskey MLA.
Lẹyin ipade pẹlu awọn adari ẹsin, Ọba Charles ati Camilla yoo darapọ mọ ile ijọsin St Anne fun adura ki wọn to pada si London

Oku Ọbabinrin yoo rin irinajo lati Aafin Buckingham lọ si gbọgan Westminster ni aago mẹrin kọja iṣeju diẹ.
Posi naa ni wọn gbe si ọkọ onibọn ti Ori Ade, ti wọn ọmọ ologun pẹlu awọn mọlẹbi yoo si tẹle.

Ọba Charles so siwaju ọkọ naa, eyi ti wọn yoo fi asọ ori ade yipọ.
Awọn ero yoo ni anfani lati wo bo ṣe lọ si ọgba Ọbabinrin ati ibo miiran ninu Aafin.
- Àwọn aṣaájú orílẹ̀èdè lágbàyéé ń ṣèrántí ‘Ọbabìnrin ẹlẹ́yinjú àánú’
- B-í ìgbésí ayé Ọbabìnrin Elizabeth ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn owó, òǹtẹ̀ àti ìwé ìrìnnà tí àwòrán Ọbabìnrin wà?
- Ẹṣin gígùn jẹ́ ohun tí Ọbabìnrin Elizabeth fẹ́ràn jùlọ
- Wo ọ̀pọ́ àwòrán ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ti kópa nínú eré ìdárayá
- Fídíò nípa Ìtàn ayé Ọbabìnrin Elizabeth Kejì tó jáde láyé
Irinajo naa ni yoo waye fun ogoji iṣeju.
Ero imowamoworan yoo wa nile nigba ile gbe ọkọ ni Aafin.
Kete ti wọn ba ti de Westminister, wọn yoo gbe posi naa sori pẹpẹle, nibi ti wọn pe ni 'Catafalque' pẹlu Ade ati Ọpasẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo ayika ibẹ ni awọn ọmọ ologun lati ninu awọn to sọ Aafin yoo ma sọ.
Bisọọbu agba fun ijọ aguda Canterbury, Justin Welby yoo ṣe ijọsin ranpẹ ti Ọba Charles kẹta ati awọn ekan ninu mọlọbi Ori Ade ki wọn to si gbagede fun awọn eniyan.

Ọjọ naa jẹ ọjọ akọkọ ninu awọn ọjọ mẹrin ti oku Ọbabirin yoo wa ni gbagan Westminster, nibiti yoo wa titi di owurọ nigba ti eto isinku ijọba yoo bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, BBC News
Wọn yoo gbe posi naa sori pẹpẹle ti o ga soke, ti gbogbo eniyan yoo ni anfani lati wọ, ti wọn si ṣe ẹyẹ ikẹyin fun.

Wọn yoo fi awọn laye sita lori bi awọn ẹniyan yoo ṣe le kopa, ṣugbọn ireti wa pe ọpọlọpọ awọn olubanikẹdun yoo ni anfani lati bu ẹyẹ ikẹyin ni gbọngan eyi to je ile to pe julọ ni Aafin Westminister, ati ọkan ìjọba ile Gẹẹsi.
Tite oku si gbagede jẹ ilana aṣa ti a fi fun Ọba-alaṣẹ, awọn Olori to waye tabi ti atẹyinwa, igbamiran awọn agba oloṣelu - botilẹjẹpe, ko ti si Olootu ijọba ile Gẹẹsi ti won gbe oku rẹ sibẹ lẹyin isinku Winston Churchil lọdun 1965

Posi Ọbabinrin Elizabeth yoo wa ni inu gbọngan Westminister fun ọjọ keji nibiti awọn araalu yoo ti ni anfani lati se ẹyẹ ekehin fun.
Ọba Charles kẹta ati Camilla yoo rin irinajo lọ si Wales, eyi ti yoo samisi ipari awọn abẹwo rẹ si gbogbo awọn orilẹede mẹrin to wa labe ijọba ile Geesi gẹgẹ bi ọba.

Oku Ọbabirin yoo wa ni gbọgan Westministe, fun ọjọ kẹta gbọngan Westminister
Oku Ọbabirin yoo wa ni gbọgan Westministe, fun ọjọ kẹrin gbọngan Westminister

Ni owurọ, Ọjọ Aje ti te oku Ọbairin Elizabeth si gbagede yoo dopin, ti wọn yoo si gbe oku na lọ si Westminister Abbey fun isinku ijọba, Ọjọ Aje je ọjọ isinmi Banki ni ilé Gẹẹsi.
Lara awọn alejo ti yoo darapọ mọ awọn idile rẹ ni awọn oloṣelu ilẹ Geesi ati awọn olori ilu lati gbogbo agbaye.

Lẹhin isinku naa, posi naa yoo rin irin-ajo lati Westminster Abbey si Wellington Arch, latibẹ, yoo gbera lọ si Windsor.
Ọkọ igboku yoo si gbe posi lo si ijọ St George ni Winsdor nibi ti ayẹyẹ igbeyin yoo ti waye
















