Queen Elizabeth II: Àwọn ọlọ́pàá fí páńpẹ́ mu ọkùnrin to kùró lórí ìlà tí wọ́n tí n wo Ọbabìnrin Elizabeth II

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu arakunrin kan lẹyin to kuro ni ori ila to wa lọ si ibi ti oku Ọbabinrin Elizabeth wa.
Labẹ ofin alaafia ilu ni wọn ti gbe, ti wọn ti lọ fi si ahamọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa Metropolitan ni iṣẹlẹ naa waye ni Ile Aṣofin ni alẹ Ọjọ Ẹti
Ori ayelujara to n safihan bi ayẹyẹ isinku ọbabinrin naa ṣe n lọ ni wọn duro fun igba diẹ lasiko iṣẹlẹ naa
- Kíló kàn? Èrò tí wọ́n tò sórí ìlà láti bu ọ̀wọ̀ fún òkú Obabìnrin ti gún to èrò wákàtí 24
- Mọ̀ síi nípa ìlànà ìsìnkú àwọn Orí adé ni Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí àti bí o ṣe yàtọ̀
- Ta ni yóò lọ, ta ni kò ní lọ- Àwọn wo ló gba ìwé ìpè síbi ìsìnkú Ọbabìnrin Elizabeth-
- Wo ọ̀pọ́ àwòrán ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ti kópa nínú eré ìdárayá
- Ẹṣin gígùn jẹ́ ohun tí Ọbabìnrin Elizabeth fẹ́ràn jùlọ
Ninu atẹyade ti Scotland Yard fi lede ni wọn ti ni awọn ọlọpaa ile aṣofin fi panpẹ mu ọkunrin lẹyin to dabaru eto ti wọn n ṣe lọwọ .
Bakan naa ni agbẹnusọ ile aṣofin ni awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ti arakunrin naa kuro ni ori ila rẹ to si sunmọ ibi ti wọn gbe oku ọbasabinrin naa silẹ.
Wọn ti gbe kuro nibẹ, ti awọn eniyan si ti pada si ori ila lati maa ba ohun ti wọn n ṣe lọ.
Saaju ni Ọba Charles ati awọn aburo rẹ, Ọmọbabinrin Anne, Ọmọbakunrin Andrew ati Ọmọbakunrin Edward wa ni ibẹ lati ṣe aisun fun iya wọn.
Ọbabinrin Elizabeth naa yoo wa ni ibi ti awọn eniyan ti wa n wo oku rẹ ni Westminster Hall titi di ọjọ Isinku rẹ ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kẹsan, ọdun 2022.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Queen Elizabeth II: Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí dínà mọ́ ìkọ̀ China tó fẹ́ bu ọ̀wọ̀ ìkẹyìn fún òkú Ọbabìnrin Elizabeth
Ikọ kan lati China to fẹ ṣe ibọwọ ikẹyin foku Obabinrin Elizabeth nibi ti wọn tẹ oku si ni Gbongan Westminster ni wọn ko faaye gba lati ṣe bẹẹ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe wi Olori ile aṣofin Lindsay Hoyle ni o kọdi awọn ikọ yi nitori iwa ti China ti ṣaaju hu si awọn aṣofin ilẹ Gẹẹsi kan.
Lọdun to kọja ni China gbegi dina rinrin irinajo fawọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi mẹsan,meje ninu wọn jẹ aṣofin- nitori pe wọn fẹsun kan China lori bo ṣe n fiya jẹ awọn musulumi Uighur.
Igbesẹ yi mu ki wọn fofin de aṣoju China si ilẹ Gẹẹsi pe ko ma wọ ile aṣofin ilẹ naa.
- Kíló kàn? Wo ọ̀pọ̀ èrò tó ti ń wá wo Òkú Obabìnrin Elizabeth II ní Gbọ̀ngan Westminster
- Wo ìdí tí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí ṣé dínà mọ́ ìkọ China tó fẹ bọwọ ìkẹyìn fún òkú Ọbabìnrin Elizabeth
- Mọ̀ síi nípa ìlànà ìsìnkú àwọn Orí adé ni Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí àti bí o ṣe yàtọ̀
- Ọba Charles Kẹta yóò ṣe àìsùn lẹ́gbẹ́ẹ̀ òkú ìyá rẹ̀, Ọbabìnrin Elizabeth
- Ta ni yóò lọ, ta ni kò ní lọ- Àwọn wo ló gba ìwé ìpè síbi ìsìnkú Ọbabìnrin Elizabeth-
- Wo ọ̀pọ́ àwòrán ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ti kópa nínú eré ìdárayá
Ijiya yi kanna ni wọn nawọ rẹ de ori awọn ikọ China to fẹ wa ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Ọbabinrin Elizabeth ni ibi ti wọn tẹ oku rẹ si ni gbọngan Westminster.
Ibaṣepọ laarin China ati ilẹ Gẹẹsi ko gunrege daada tẹlẹ. Pẹlu ohun to waye yi, o ṣeeṣe ki o tunbọ ma lọ deedee si.
Amọ ṣa ireti wa pe igbakeji aarẹ China yoo kopa nibi ayẹyẹ isinku ti yoo waye ni isda titi ni Westminster Abbey.
Ṣaaju lawọn aṣofin kan ti parọwa si Minisita ọrọ ilẹ okere pe ko wọgile fifi iwe pe aarẹ China Xi Xiping wa sibi isinku Ọbabinrin.

Wo bí ìrìnàjò Pósí Obabìnrin Elizabeth II ṣe rin títí tó fi dé sí Gbongàn Westminster...
Posi Ọbabinrin Elizabeth ti kuro ni Buckingham Palace ni 14:22 BST, lọ si Westminster Hall.
Ọba Charles III, Ọmọọba William ati Ọmọọba Harry, ati awọn ọmo idile ọba miiran lo rin lẹyin posi Ọbabinrin Elizabeth naa.
Ayẹyẹ ibọn yinyin yoo waye ni Hyde Park ti ago nla ile geesi yoo dun (Big Ben)
- Kíló kàn? Lónìí ni òkú Obabìnrin Elizabeth yóò kúrò ní Buckingham ló sí Westminster Hall pẹ̀lú ikọ̀ ọmọ ogun
- Ta ni yóò lọ, ta ni kò ní lọ- Àwọn wo ló gba ìwé ìpè síbi ìsìnkú Ọbabìnrin Elizabeth-
- Queen Elizabeth: Àwọn ìgbà tí Ọbabìnrin ṣe àwàdà tó pa àwọn èèyàn lẹ́rìín rèé
- Ọ-̀pọ̀ èrò ya bo ààfin Buckingham láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Ọbabìnrin Elizabeth
- Àwọn ààrẹ Áfíríkà kí Ọbabìnrin Elizabeth pé ó dìgbóṣe
- Àwọn àwòràn ìgbé ayé Ọbabìnrin Elizabeth kejì
- Wo fídíò bí ayẹyẹ ìgbéyàwó Ọbabìrin Elizabeth ṣe wáyé lọ́dún 1947
Awọn to gbẹ posi na yoo gba awọn agbegbe wọnyi kọja,Queens Garden,The Mall,Horse Guards,whitehall,Parliament street,parliament Square ati new palace yard.
Posi naa de si Westminster Hall ni dedee ago 15:00
Ti wọn yoo gbe lori pepele tie to isin rampe yoo waye.
Awọn eniyan yoo ni anfani lati wọ posi Ọbabinrin Elizabeth ni Westminster Hall lati 17:00
- Wo ọ̀pọ́ àwòrán ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ti kópa nínú eré ìdárayá
- Ẹṣin gígùn jẹ́ ohun tí Ọbabìnrin Elizabeth fẹ́ràn jùlọ
- Àwọn ètò tó wà fún títẹ́ òkú Ọbabìnrin Elizabeth Kejì ní ìtẹ́ ẹ̀yẹ àti ìsìnkú rẹ̀
- Àwọn ààrẹ Áfíríkà kí Ọbabìnrin Elizabeth pé ó dìgbóṣe
- Èyí ni ìtàn ìgbé ayé Ọbabìnrin Elizabeth kejì
- Àwọn àwòràn ìgbé ayé Ọbabìnrin Elizabeth kejì
Òkú Ọbabìnrin Elizabeth ti balẹ̀ sí ìlú Edinburgh tí ń ṣe olú ìlú Scotland.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kọkànlá ni wọ́n gbé òkú Ọbabìnrin náà kúrò ní ààfin Balmoral tó kú sí lọ sí Edinburgh pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́.
Wàkátì mẹ́fà ni ìrìnàjò náà wọ́n kí wọ́n tó gbé òkú náà dé Edinburgh.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èrò ló dúró ní ẹ̀bá ọ̀nà láti ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Ọbabìnrin Elizabeth bí wọ́n ṣe ń gbé òk;u rẹ̀ kọjà lọ sí Edinburgh.
- Wó bí gbogbo ètò ìsìnkú náà yóò ṣe lọ ní Ọjọ́ Aje, Ọjọ́ Iṣẹ́gun, Ọjọ́ru àti Ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀...
- Àwòrán àwọn ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ṣe àbẹ̀wò sí ilẹ̀ Adúláwọ̀ fún ìbáṣepọ̀ tó dánmọ́rán
- Ìjọba Nàìjíríà bu ọlá fún Ọbabìnrin Elizabeth II, wọ́n yóò sọ àsía sílẹ̀ dé ìdajì
- Kíni ǹkan tí oyè Ọmọọba ilẹ̀ 'Wales' já sí fún William?
- Ta ni Ọba Charles Kẹta-
- Queen Elizabeth II: Níbo àti ìgbà tí ètò ìsìnkú Obabìnrin Elizabeth máa wáyé?
- Charles kọrin re ki saa isejọba Ọbabìnrin bí wọ́n ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bíi Ọba
- Wọn kéde ọba Charles Kẹta bii Ọba - Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìkéde náà tó wáyé lórí afẹ́fẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́?
Òkú Ọbabìnrin tó jẹ́ ọba tó pẹ́ lórí oyè jùló ní UK ti wà ní ààfi rẹ̀ ní Holyroodhouse ní Edinburgh, tí yóò sì wà níbẹ̀ títí di ọ̀sán ọ̀la tí wọ́n máa gbé òkú náà lọ sí London.
Àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, Ọmọọbabìnrin Anne, Ọmọọba Andrew àti Ọmọọba Edward ni wọ́n wà pẹ̀lú òkú náà ní Ediburgh báyìí.
Ní ọjọ́ Ajé, ọja kejìlá ni Ọba Charles yóò lọ darapọ̀ mọ́ wọn kí wọ́n tó gbé òkú náà lọ sí London.
Ṣaájú ni Ọba Charles ti ṣàpàdé pẹ̀lú akọ̀wé àpapọ̀ fún Commonwealth ní ààfin Buckingham.















