Queen Elizabeth II: Kíní àwọn ńkan tí yóò wáyé lọsẹ yìí?

Aworan Ọbabinrin Elizabeth keji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Saaju irinajo posi Ọbabinrin Elizabeth keji lati Balmoral, awọn nkan to ṣeeṣe ko waye ni wọn ọjọ to n bọ re.

Oni: Posi Ọbabinrin yoo gbera kuro ni Balmoral, yoo si rin irin ajo oni kilomita marundinlọgọsan an, ti yoo si gba awọn ilu bi Aberdeen ati Dundee ati Perth kọja, ko to balẹ si Aafin Holyroodhouse.

Ọjọ Aje: Lọsan ọjọ Aje, posi Ọbabinrin yoo rin irinajo lọ si ile jọsin, St Giles pẹlu Ọba ati mọlẹbi idile ori ade.

Irinajo posi Obabinrin Elizabeth keji
Àkọlé àwòrán, Irinajo posi Obabinrin Elizabeth keji

Ọjọ Isẹgun: Ọmọọbabinrin Anne yoo tẹle posi Ọbabinrin lati rin irinajo wa si ilu London.

Lati ibẹ, ni yoo ti morile Aafin Buckingham, ti Ọba Charles ati Olori Camillia yoo si ki i kaabọ.

Ọjọru: Posi Ọbabinrin yoo rin irinajo kiri agbegbe aarin gbogbo ilu London, ki wọn to tẹ posi naa si Westminster, nibi ti yoo wa fun ọjọ mẹrin.

Ọjọ Aje, Ọjọ kọkandinlogun, Ọsu yii: PosI Ọbabinrin yoo gbera kuro ni Westminster lọ si Westminster Abbey, nibi ti ayẹyẹ oku yoo ti waye.

Ọba Charles kẹta

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọba Charles Kẹta

Queen Elizabeth II: Kíní àwọn nkan ti yóò wáyé lónìí nípa ètò ìsìnkú Obabìnrin Elizabeth?

Bi ile UK ṣe n tẹsiwaju lati ma a ṣe idaro lori iku Ọbabinrin kẹji, awọn nkan ti yoo waye loni re e.

  • Posi Ọbabinrin yoo gbera ni Balmoral ni deede aago mẹwaa, ti yoo si rin kẹlẹkẹlẹ lọ si Edinburgh

Yoo balẹ si Aafin Holyroodhouse- ile ìgbé awọn ori ade ni olu ilu Scotland - ti won yoo si tẹ posi naa silẹ ni ninu Iyara Ìtẹ́ ti wọn n pe ni Throne Room.

  • Niluu London, Ọba yoo ṣe ipade pẹlu akọwe agba ajọ iṣọkan Commonwealth ni Aafin Buckingham.

Bakan naa ni yoo ma a gba alejo awọn olori orilẹ̀-ede to jẹ Ọba le lori ni ìyara igbalejo Bow's Room ni aafin rẹ̀.

Wó àwọn nǹkan tó wáyé lánàáọjọ́ Abameta lẹyìn ikú Ọbabìnrin Elizabeth...

Saaju bi igbaradi yoo ṣe waye loni, wo awọn nkan to waye lana ọjọ Satide.

Ayẹyẹ Ikede Ọba Charles gẹgẹ bii Ọba tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wn fi ariwo ayọ ki Ọba tuntun
  • Ni Balmoral, awọn ọmọ Ọbabinrin Elizabeth mẹtẹẹta- Ọmọobabinrin Anne, Ọmoọba Andrew ati Ọmọoba Edward kopa ninu eto adura to waye ni ile jọsin pẹlu awọn mọlẹbi ori ade miiran, ti wọn si tun fẹsẹ kan duro lati fi ki awọn eeyan to wa nita Balmoral.

Eto isinku yoo waye lọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii ni deede aago mọkanla owurọ ni Westminster Abbey.

Molebi ori ade n wo iwe ibanikedun ni ita Balmoral

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Molebi ori ade n wo iwe ibanikedun ni ita Balmoral
  • Ọmọoba Williams, Ọmọoba tuntun fun Wales kan saara si Ọbabinrin Elizabeth, o ni iya baba oun duro ti oun nigba iṣoro ati nigab ti inu oun dun.
  • Ọba Charles ṣe ipade pẹlu awọn minisita, awọn oloṣelu lati inu ẹgbẹ oselu alatako ni Aafin Buckingham.
  • Ọmoọba Harry ati William, pẹlu awọn iyawo wọn mu inu awọn eeyan dun lati ara bi wọn ṣe rin jade ni Windsor, lati ki awọn eeyan to wa kan saara si Ọbabinrin to doloogbe.