King Charles III: Camilla di Olorì tuntun

Camilla, Duchess ti Cornwall

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Camilla ni ifẹ aye Charles, olufọkantan rẹ lati igba ti wọn ti wa ni ewe, to si tun jẹ iyawo rẹ fun ọdun mẹtadinlogun. Ni bayii, O ti di Olori Ọba.

Ọpọ eeyan lo ti mọ lara lati ma ri Camilla ni ẹgbẹ ọkọ rẹ nibi ayẹyẹ ati ajọyọ orilẹede, sugbọn o ni awọn ti bẹrẹ, ọjọ tipẹ.

Awọn obinrin diẹ kan maa n sọrọ Camilla Parker Bowles ni buburu. Wọn fi ẹsun kan pe oun lo fa ipinya igbeyawo ayeraye, ti wọn si ma fi we Diana, ọmọbabinrin Wales.

Awọn Ọmọ iyawo ati awọn ẹgbọn ati aburo ọmọ ọdun mẹrin Camilla ati ọmọ ọdun mẹta Annabelle Shand nibi ayẹyẹ igbeyawo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Camilla Parker Bowles (L), pẹlu aburo rẹ obinrin, Annabel, nibi ayẹyẹ igbeyawo lọdun 1952

Idamu ba aye rẹ lẹyin to ni oun fẹ fẹ Charles. Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn akọroyin fi da laamu, ti wọn si tabuku rẹ fun ọpọ igba. Sugbọn o ni suuru, to si fi iwa pẹlẹ gba aye rẹ ninu aafin gẹgẹ bi obinrin to dagba ju.

Irin ajo nla lo jẹ fun obinrin naa to ni, Ọmọba Charles fẹran oun lẹsẹkẹsẹ ti awọn pade nigba ti wọn jẹ ọmọ ogun ọdun.

Itẹwọgba lati ọdọ Ọbabinrin Elizabeth gba asiko sugbọn ko ko iyan Camilla kere ni iwọnba ọdun diẹ sẹyin. Olori tuntun ni o sese ko ma ri itẹwọgba lati ọdọ araalu ni ibẹrẹ sugbọn gẹgẹ bi o ṣe sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ Vogue ni ibẹẹrẹ ọdun yii: "Mo maa n gbinyanju lati bori nnkan, ki n si tẹsiwaju, eeyan ni lati maa ba aye niso ni."

Fifẹ arẹmọ Ọba ni ko jẹ asọtẹlẹ fun Camilla Rosemary Shand, ẹni ti wọn bi lọjọ kẹtadinlogun osu Keje ọdun1947. Molẹbi rẹ jẹ ẹni nla, olowo, ọlọrọ, ti wọn si mọ eeyan nla sugbọn wn kii se idile ọba.

O dagba si agbegbe to ayika rẹwa, nibi to oun pẹlu ẹgbọn rẹ ọkunrin ati obinrin ti maa n ṣere ni ile mọlẹbi wọn to wa ni Sussex, Baba rẹ, Bruce Shand, ajagunfẹyinti, to maa n ka iwe itan fun, ko to sun pẹlu iya rẹ, Rosalind , to ma mu wọn lọ si ile ẹkọ, ibi ayẹyẹ ati eti okun. Iyatọ wa fun bi Charles ṣe dagba, ẹni to ọpọlọpọ ọdun lati duro lai ri awọn obi rẹ nitori wọn maa n rin irin ajo kaakiri agbaye .

Ile ẹkọ kan lorilẹede Switzerland ni Camilla ti bẹrẹ, ti wọn si kọ lori igbe aye awọn eeyan nla niluu London. Ilu mọọka ni ati pe nibi ọdun pupọ sẹyin, o wa ninu ibaṣepọ dakudaji pẹlu osisẹ ologun kan, Andrew Parker Bowles.

Andrew Parker Bowles ati Camilla lọjọ igbeyawo wọn

Oríṣun àwòrán, Frank Barratt / Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lẹyin ibaṣepọ dakudaji , Camilla fẹ Andrew Parker Bowles lọdun 1973.

Saaju ọdun 1970, o pade Ọmọọba Charles. Gẹgẹ bi Jonathan Dimbleby, ẹni to kọ iwe itan Ọmọọba naa ṣe sọ, "O ni ọyaya, ti ọmọọba si fẹran rẹ ni kete to fi oju kan-an".

Sugbọn asiko ko ti too, Charles si wa ni bii ọmọ ogun ọdun, to n sisẹ bii ologun oju omi. Lọdun 1971, o ri irin ajo kan sugbọn ko to de, Andrew ti kọnu ifẹ si Camilla, to si gba lati fẹ ẹ. Ki lo de ti ko duro de Charles? awọn ọrẹ ri gẹgẹ bi ẹni ti ko ri ara rẹ gẹgẹ bi Olori Ọba.

Sugbọn ni saa ounka ọdun 1970 siwaju, ni wọn fi Camilla mọ Ọmọọba Charles. Gẹgẹ bi Jonathan Dimbleby, to kọwe itan aye ọmọọba naa se wi, "O jẹ ẹni to ko ni mọra, le se oun gbogbo, to si nifẹ pupọ - ni kete to si ri Camilla, lo sọ ọkan rẹ nu sọwọ obinrin naa."

Awọn meejeji ni kadara ko fi wọn silẹ, aarin awọn alabarin kan naa ni wọn dijọ wa, koda Charles ati Andrew Parker Bowles jọ maa n ṣere idaraya 'Polo' papọ ni. Tọkọtaya naa ni ki Charles jẹ Baba isalẹ fun akọbi wọn, Tom. Aworan Charles ati Camilla nibi ipade ere idaraya Polo safihan pe wọn n jẹwọ.

Charles duro si ẹgbẹ Camilla , lẹgbẹ ibudo ọkọ nibi ere idaraya Polo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Charles, (L), ati Camilla ni igba ti wọn jọ kọkọ ya aworan papọ lọdun 1972.

Lasiko saa ọdun 1981 siwaju, Charles pade ọmọbinrin miran, to ki kọnu ifẹ si, Lady Diana Spencer. Sugbọn Camilla ko kuro ninu aye rẹ. Diana, ninu iwe itan ti Andrew Morton ṣe akọsilẹ rẹ, sọ pe bi Diana ṣe wọgile igbeyawo wọn to ku ọjọ meji nitori pe o ri ẹgba ọwọ ti Charles fẹ fun Camilla ti wọn kọ "F" ati "G" si lara, orukọ apejẹ ti awọn mejeeji fun ara wọn ni Fred ati Gladys.

Pe Diana n tiraka pẹlu ibasepọ Camilla ati ọkọ rẹ, kii se ariyanjiyan rara. Charles ni oun ati Camilla bẹrẹ ere ifẹ to wa laarin awọn pada lẹyin ti igbeyawo oun ti fori sanpọn. Sugbọn Diana sọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu iwe iroyin Panoram ọdun 1995 pe awọn mẹta ni awọn wa ninu igbeyawo oun.

Bi igbeyawo Charles ṣe n buru si, awọn akọle iroyin kan lo mu awuyewuye waye tabi ka ni o tan imọlẹ lori ipe kan to waye lasalẹ lọdun 1989 ti wọn ka silẹ sinu fọnran sugbọn to han sita lẹyin ọdun mẹrin. Charles ni o wu oun lati wa ọna abayọ si isoro ti wọn n fun oun nitori Camilla, to si salayan iru ibasepọ to wa laarin wọn.

Igbeyawo Camilla wa sopin lọdun 1995. Igbeyawo Charles ati Diana naa lulẹ lọdun 1996.

Ifẹ ti Camilla ni si Charles lo mu pinnu lati duro ti i, lai wo ọrọ kan to n ja kiri ati rogbodiyan awọn rẹ fa, papajulọ, awọn ọmọ rẹ mejeeji, Tom ati Laura.

Tom Parker Bowles salaye bi awọn ayaworan ṣe ma sapamọ sinu igbo ni ile wọn to wa ni Wiltshire , "Ko si nkan ti ẹnikẹni fẹ sọ nipa mọlẹbi wa to fẹ dun wa mọ," o sọ eleyi ninu iwe iroyin Times lọdun 2017. "Iya mi yoo fi ara di fun wa"

Nigba naa, Camilla ni: "Ko si ẹnikẹni to fẹran pe ki awọn eeyan ma wo oun ni gbogbo igba, Sugbọn o ni lati wa ọna lati gbe pẹlu rẹ nipa wiwa ọna lati koju orukọ buburu ti wọn pe wa nigboro lẹyin iku Diana lọdun 1997. Ni ita gbangba , Charles gbajumọ awọn ọmọ rẹ, Williams ati Harry, ti ko si dun mọ Camilla ninu sugbọn ibasepọ wọn tẹsiwaju.

Charles duro le pe Camilla gbọdọ wa ninu aye rẹ, to si bẹrẹ ọna lati ṣe atunse fun loju awọn eeyan. O bẹrẹ pẹlu bi awọn mejeeji se jọ kopa ninu ayẹyẹ ọjọ ibi adọta ẹgbọn Camilla ni ile itura Ritz lọdun 1999. Lẹyin ọdun mẹfa, wọn ṣe igbeyawo ranpẹ ni Windsor Guildhall.

Ọmọba Charles ati Camilla Parker Bowles kuro ni ile itura Ritz lọdun 1999

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Charles ati Camilla je apapọ gẹgẹ bi lọkọlaya lẹyin ti wọn kuro nibi ayẹyẹ kana lọdun 1999

Gbogbo nkan ti awọn tọkọtaya naa ro boya yoo lẹyin, ni ko ri bẹẹ, ti ogunlọgọ eeyan si ki wọn ku oriire igbeyawo naa.

Sugbọn fun ọpọlọpọ ọdun, awuyewuye si n lọ boya Camilla yoo di Olorì. Bi o til jẹ pe labẹ ofin, o lẹtọ lati di ipo naa mu, amọ ilana isejọba ni ki wọn maa pe e ni iyawo ọmọọba, gẹgẹ bi ọna lati pẹtu si ọkan awọn to n di ẹbi ru Camilla pe oun lo fa ipinya si igbeyawo Charles si Diana.

Ni ipari, Ọbabinrin yanju ọrọ naa, ẹni to ṣorọ lọdun 2022 pe o wu oun pe nigba ti asiko ba to, Camilla yoo di Olorì. Eyi fi safihan pe aye Camilla lẹgbẹ Charles wa ni digbi, ti ọrọ runrun si wa sopin.

Ti Ọbabinrin ko ba tiẹ fi ọwọ si Camilla ni ibẹẹrẹ, ọrọ ti awọn ọmọọba mejeeji, Williams ati Harry wa nilẹ. Awọn mejeeji lo n doju kọ isoro lori ipinya awọn Obi wọn ati iku iya wọn nigba ti awọn mejeeji jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun ati ọmọ ọdun mejila pere.

Charles ati Camilla lọjọ igbeyawo wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Tọkọtaya naa nibi ayẹyẹ igbeyawo ni Windsor Guildhall wọn lọjọ kẹsan ọdun 2005

Lọdun 2005, osu diẹ lẹyin igbeyawo wọn, Harry, ẹni ọdun mọkanlelogun sọ pe Camilla jẹ "Obinrin rere" to mu inu Baba awọn dun.

"Emi ati William nifẹ rẹ, ti a si ba lo pẹlu irọrun."

Nkan diẹ lo jade lati ẹnu Ẹgbọn rẹ lori Camilla sugbọn ibasepọ William, Iyawo rẹ Catherine ati Camilla nibi ayẹyẹ kan fihan pe ko si laburu laarin wọn.

Camilla pẹlu ọmọ rẹ ọkunrin Tom and ati ọmọbinrin Laura

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Camilla ati ọmọ rẹ ọkunrin Tom ati ọmọbinrin rẹ Laura lati igbayawo pẹlu Andrew Parker Bowles
Camilla pẹlu Ọbabinrin , Ọmọ Philip, Ọmọba Kate ati Ọmọba Williams nibi ayẹyẹ Ọmọba Charlotte

Oríṣun àwòrán, Chris Jackson / Getty images

Àkọlé àwòrán, Camilla di ọkan googi ninu aafin nibi ayẹyẹ kan lọdun 2015

Ni ẹni aadọrin ọdun bayi, igbesi aye Camilla da lori ọna lati gbaruku ti ọkọ rẹ ati awọn mọlẹbi. Awọn Molẹbi rẹ lati Windsor le bẹrẹ awuyewuye sugbọn yatọ si gbogbo ọrọ naa, Camilla ti di iya iya awọn marun un. O ko wọn si ile rẹ ni Wiltshire, Ray Mil, nibi to ti lọ maa n sinmi.

"O jẹ ẹni ti mọlẹbi sunmọ, to si maa n ran mọlẹbi ati awọn ọrẹ lọwọ" aburo rẹ Ben Elliott sọ fun Vanity Fair magazine. "O fẹran ọkọ rẹ, awọn ọmọ rẹ ati awọn ọmọ-ọmọ."

Camilla naa sọrọ lori awọn ohun to ni itara fun:

  • Sise ipolongo lati gbogun ti osteoporosis, eyi to ni ipa lara iya ati iya-iya rẹ
  • Nina ika si awọn to buru lawujọ lori ẹsun ifipanilopọ, lilu obinrin bii bara ati iwa abuku mii
  • Wiwa ọna lati fi iwe ifẹ to jogun lati ọwọ baba rẹ fun awón fun ẹgb onkawe kan lori ayelujara Instagram 

Boya nitori pe o p ko to dara p mọ idile ọba, oju maa n ti i nipa bawọn eeyan to yi i ka se n raga bo o.

Nigba to ṣe agbatẹru apejẹ ni Clarence House, akọroyin BBC ri Camilla to n yọju kaakiri lawọn ori faranda ati akasọ ninu ile, to n wo o boya gbogbo eeyan ti setan. Nigba to ri pe a ti setan, o sọkalẹ, to si n di mọ gbogbo wa amọ o fi ẹnu ko ọga agba ajọ alaanu naa lẹnu.

Lasiko igbele arun Coronavirus, Camilla sọrọ nipa bi bo se dun to pe oun ko le gbe ọmọ-ọmọ oun mọra daadaa. Nigba ti wọn dẹwọ lori ofin isede naa, o gbadun ara rẹ pe oun tun pada lati maa gbera nilẹ kiri.

Ọba Charles and Ayaba Camilla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Charles ati Camilla ani gbogbo eeyan n ri to maa n rẹrin papọ nita gbangba

Ti eeyan ba n wo ninu yara, o han gbangba pe o le mu ki ara eeyan walẹ. Kii si fi pamọ pe o nira fun oun lati sọrọ to nira maọ nitori iriri ọpọlọpọ ọdun, o ti ni igboya gidi.

Igbeyawo Charles ati Camilla lo ti pe ọdun mẹtadinlogun bayii. Ni ita gbangba, isopọ wn han kedere. Wọn maa n wo ara wọn loju, rẹrin papọ - ko si fẹẹ si ayẹyẹ ti kii ti foju han pe wn ba ara wọn se awada lasiko kan.

"Wọn nifẹ, ti wọn si n bọwọ fun ara wọn, ti wọn si maa n rẹrin si nnkan kannaa." Ọgbẹni Albert sọ fun Vanity Fair.

Wọn gbe igbe aye ọlọla amọ awọn mejeeji ni oju gbogbo n wo, ti iru eyi si le di ẹru si wọn lọkan.

"Yoo dara ki eeyan ni ẹnikan lgbẹ rẹ, ti yoo duro ti i," Ọmọọba Charles sọ fun ileesẹ iroyin CNN nigbaradi fun iranti ọdun kẹwa igbeyawo wọn. "Alatilẹyin to lagbara ni, to si maa n ri agbọn ibi ti aye ti pa ni lrin, a dup lọwọ Ọlọrun."

"Nigba miran, o dabi igba tawọn ọkọ oju omi ba n kọja ni alẹ" Camilla sọ nipa igbe aye wọn. "A maa n dijọ jokoo papọ lasiko ta ba n mu ife tii wa, ta si sọrọ lori bi ọjọ kan se lọ. A maa n ni akoko tiwa."

Ojuse ipo ọba jẹ adanikanse - Bi Charles si se n lọra lati fi Camilla silẹ lo fihan pe o seese ko ti mọ saaju pe obinrin naa nikan ni ẹnikan soso to le jẹ alabarin ti oun nilo ninu ojuse ipo ọba ti oun n gba.