King Charles III: Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìkéde náà tó wáyé lórí afẹ́fẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́?

Ọba Charles Kẹta ati Camilla, olori tuntun lasiko ayẹyẹ ifidimulẹ Ọba tuntun ti igbimọ awọn Ọlọla se lọjọ Satide ni aafin St James

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Ọba Charles Kẹta ati Camilla, olori tuntun lasiko ayẹyẹ ifidimulẹ Ọba tuntun ti igbimọ awọn Ọlọla se lọjọ Satide

Ọba Charles kẹta ni wọn ti kede bayii gẹgẹ bii ọba nibi ayẹyẹ manigbagbe kan to waye ni aafin St James nilu London.

Lasiko asa tito lọwọọwọ to waye ni aarọ ọjọ Satide - eyi ti wọn gbe sori afẹfẹ fun igba akọkọ -, awọn asia ti wọn fa silẹ fun ọbabinrin to waja, ni wọn fa wa soke lati se ayẹ ba tuntun.

Afẹfẹ ariwo ayọ mii ni yoo maa waye jakejado ilẹ UK titi di ọjọ Aiku, ti wọn yoo si fa asia walẹ pada de idaji lasiko ibanikẹdun eyi to tẹle iku Ọbabinrin Elizabeth Keji eyi to waye lọjọ Kẹjọ Osu Kẹsan.

Igbimọ awọn Ọlọla lo kede Ọba tuntun naa, to si sebura nibi ayẹyẹ alarinrin naa to kun fun asa isẹnbaye - eyi ti ko tii waye ti lati aimọye ọdun sẹyin.

Ayẹyẹ Ikede Ọba Charles gẹgẹ bii Ọba tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wn fi ariwo ayọ ki Ọba tuntun

Ki ni itumọ gangan ti ikede Ọba tuntun jẹ?

Charles ti di Ọba bayii - labẹ ilana ofin ti wọn n pe ni Act of Settlement 1701, Ni ti asa, o ti di Ọba ni kete ti iya rẹ ku. Nitori naa, pataki ijoko Igbimọ Ọlọla kan jẹ ayẹyẹ lasan lati kede fun araye pe Ọba tuntun ti jẹ.

Eyi maa n waye laarin wakati mẹrinlelogun ti ọba ba waja. Amọ akoko diẹ kọja laarin igba ti Ọbabinrin Elizabeth keji papoda si igba ti ayẹy waye ni aafin St James, to wa ni aarin gbungbun ilu London, to si sun mọ aafin Buckingham. Iyapa kuro ninu asa miran to tun waye, ni pe ọba Charles Kẹta pinnu fun igba akọk pe ki wọn gbe ijoko Ọlọla naa sori afẹfẹ.

Àwọn wó ló wà?

O igba eniyan lati igbinmọ Privy, awọn oludaramọran si Ọba, awọn oloṣelu tẹlẹri ati ti isin yii ni wọn pejọ si gbọngan St James , pẹlu awọn alufaa ijọ

Igbinmọ naa lo ti wa lati aye awọn ọba Norman. Wọn to eeyan ẹẹdẹgbẹrin ni ye lo wa ninu igbinmọ sugbọn awọn igba ni wọin ransẹ pe.

Awọn Olotu ijọba nigba kan ri, Gordon Brown, David Cameron, Boris Johnson ati Theresa May ti wọn si salabapade Ọbabinrin ni ọpọ igba ni wọn wa ni ikalẹ ati oludari ilu London, agbẹjọro agba ati osisẹ ijọba miiran.

Asaaju ẹgbẹ osisẹ, Sir Keir Starmer ati awọn Olootu Ijọba tẹlẹ Tony Blair, Gordon Brown, Boris Johnson, David Cameron, Theresa May ati John Major naa wa nikalẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Asaaju ẹgbẹ osisẹ, Sir Keir Starmer ati awọn Olootu Ijọba tẹlẹ Tony Blair, Gordon Brown, Boris Johnson, David Cameron, Theresa May ati John Major naa wa nikalẹ

Camilla Parker Bowles, Iyawo Charles fun ọdun mẹtadinlogun,(ẹni to di Olori bayi) ati Ọmọ Ọba, WIlliams, Ọmọ Ọba tuntun fun ile Scotland naa wa ni kalẹ.

Apá kìíní: Wọ́n kéde orukọ Ọba

Ọ̀nà méjì ni wọ́n pín ètò kíkéde fífi Charles jọba sí, tó sì jẹ́ wí pé ibi apá kejì ni Ọba Charles ti kópa.

Ní àkọ́kọ́, Ààrẹ ẹ̀ka ìdájọ́, Mínísítà ẹgbẹ́ Conservative, Penny Mordaunt ẹni tí Olóòtú ìjọba Liz Truss yàn sípò lọ́jọ́ Kẹfà, oṣù kẹsàn-án kéde ikú Ọbabìnrin Elizabeth.

Lẹ́yìn náà ló darí akọ̀wé ìgbìmọ̀ láti ka ìkede ìfìjoyè náà pẹ̀lú wí pé Charles fẹ́ kí wọ́n máa pe òun ní Ọba Charles Kẹta.

Àwọn ènìyàn tó tó igba tó wà nínú gbọ̀ngán náà panupọ̀ láti sọ wí pé "Kí Ọlọ́run dá ààbò bo Ọba" kí wọ́n tó buwọ́lu àwọn ìwé ẹ̀rí tó yẹ.

Awọn ologun naa kopa ninu ayẹyẹ yinyin ibọn lati ki Ọba tuntun, Charles Kẹta kaabọ

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Awọn ologun naa kopa ninu ayẹyẹ yinyin ibọn lati ki Ọba tuntun, Charles Kẹta kaabọ
Awọn ologun naa kopa ninu ayẹyẹ yinyin ibọn lati ki Ọba tuntun, Charles Kẹta kaabọ

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Ibọn yinyin lati se ikinni nilu London

Ọmọọba William, Olóòtú ìjọba Liz Truss àti Archbishop Justin Welby sì wà níbẹ̀ láti wo bí ètò náà ṣe ń wáyé.

Lẹ́yìn ìbuwọ́lu ìwé náà ni Mordaunt pè fún ìdákẹ́jẹ́jẹ́ láti tún ka àwọn ìgbésẹ̀ tó kàn bíi yíyin ìbọn ní Hyde Park ní ààrin gbùgùn London àti ní Tower ìlú London.

Bákan náà ni wọ́n tún kéde àwọn Ọba Charles gẹ́gẹ́ bí Ọba ní Belfast, Cardiff, Edinburgh àti àwọn ibòmíràn ní orílẹ̀ èdè náà.

Apá kejì: Ọba Charles sọ̀rọ̀

Apá kejì ètò fífi Ọba Charles jẹ ni ibi tí ìgbìmọ̀ Privy ti kí Ọba tuntun nínú yàrá oyè ní ààfin St James.

Ohun ni ìpàdé àkọ́kọ́ tí ìgbìmọ̀ Privy yóò ṣe èyí tí Ọba tuntun náà darí. Àwọn káhúnsílọ̀ tó lọ́wọ́ọ̀ọ̀wọ́ láti kí Ọba tuntun náà káàbọ̀ ní orí ìdúró gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn wí pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ní ìgbìmọ̀ Privy.

Ọba Charles Kẹta nibi ayẹyẹ ibura

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Charles ti di ọba lẹyin iku iya rẹ, ijoko awọn Ọlọla lati kede kan jẹ ayẹyẹ lasan ni

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àkọ́kọ́ rẹ̀ sí ìgbìmọ̀ Privy, Ó ní gbogbo iṣẹ́ ìsìn tí ìyá òun ṣe ni òun jẹ́jẹ̀ẹ́ láti gùnlé gẹ́gẹ́ bí Ọba.

"Gbogbo àgbáyé ló ń bámi kẹ́dùn lórí àdánù ńlá tó kọlu gbogbo wa."

"Àkókò ìyá mi gẹ́gẹ́ bí Ọba kò ní ẹgbẹ́ nípa iṣẹ́ àti àwọn ètò ìlú. Kódà bí a ṣe ń ṣọ̀fọ̀, adúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìgbé ayé rere tí Ọbabìnrin gbé."

Ọba tuntun náà tún sọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ tó wà níwájú rẹ̀.

"Gbogbo àwọn iṣẹ́ àti àwọn nǹkan ti mo jogún ló yé mi dada mo sì ti ṣetán láti ṣé tọkàntọkàn."

Bákan náà ló kan sáárá sí Camilla, ẹni tó jẹ́ olorì tuntun, tó sì dúpẹ́ fún àtìlẹyìn rẹ̀.

"Àtìlẹyìn tí ìyàwó Camilla ń ṣe fún mi wà lára ohun tó n fúnmi ní ìwúrí láti máa tẹ̀síwájú."

Ki ni itumọ ibura ti ba Charles se?

Labẹ ilana Act of Union, awọn olori tuntun gbọdọ ṣe ileri pe awọn yoo dabobo ile jọsin ti ile Scotland

Idi ni pe lorilẹede Scotland, pinpin agbara wa larin ilu ati ile jọsin

Charles buwọlu ẹda meji iwe ileri naa niwaju igbinmọ Privy. Awọn oṣoojumikoro, Ọmọba William - Ọmọba Wales - ti Camilla si tẹle - Olori tuntun.

Prince William ati aya rẹ, Catherine ni wọn kede bii Ọmọọba ati Ọbabinrin ti Wales, nigba ti Camilla di Ayaba laafin

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Prince William ati aya rẹ, Catherine ni wọn kede bii Ọmọọba ati Ọbabinrin ti Wales, nigba ti Camilla di Ayaba laafin

Kete ti wọn buwọlu awọn iwe naa, awọn olorin bẹrẹ orin.

Charles ni anfani lati ma ṣe buwọlu iwe ti wọn ni ko buwọlu, Ọba tuntun to ṣe bẹ gbẹyin ni Ọba George V lọdun 1910, nigab to kọ lati buwọlu iwe si awọn ọrọ to lodi si ijọ aguda.

Ki lo sẹlẹ ni faranda?

Lẹyin eyi ni wọn gbe eto yii lọ si ita aafin.

Wọn gba awọn araalu laaye lati inu gbọngan lọ si gbagede igbẹjọ Friary lati boju wo ikede Ọba Charles keta.

Ikede Ọba Charles Kẹta ni wọn ka ni gbagede igbẹjọ Friary

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ikede Ọba Charles Kẹta ni wọn ka ni gbagede igbẹjọ Friary

"Wọn wa pẹlu awọn ohun ọsin, ododo, ọmọ kekere pẹlu asọ alawọ Spiderman, ti wọn si lori ọkada ati kuku jia." BBC James Bryant sọ eleyi lati ileẹjọ."

Ọgagun Garter lo si ẹyinkunle lori agbala Friary lati ka ikede naa, ti awọn onifere si fọn fere fun ni ikinni laafin ọba.

Won wa kọ orin orilẹede pẹlu afikun awọn ọrọ wọnyi, "Ki Ọlọrun dabobo Ọba" fun igba akọkọ ni ọpọlọpọ ọdun

Lẹyin naa ni ajọyọ bẹrẹ: Ọga gun awọn ọmọ ologun: "Fun Ọlọlajulọ, Ọba, Hip Hip.....", ti awọn ẹsọ Ọba si dalohun pe "Hooray" ni igba mẹta, ti wọn si na fila wọn si oke lati kọja ori wọn

Awọn afọ fere Ọba ati awọn osisẹ yo ku wa si bi ọkọ. Wọn gbera lo si Royal Exchange niluu Londom nibi wọn ti ikede naa

Awọn afọnfere

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn afọnfere Ọba wa nikalẹ ni faranda to wa loke igbẹjọ Friary
Ayẹyẹ ikede Ọba tuntun ni London
Àkọlé àwòrán, Ayẹyẹ ikede Ọba tuntun

Kí ló kàn?

Ayẹyẹ naa wa sopin nigba ti agbẹnusọ ile igbinmọ Privy kede Charles gẹgẹ bi "Ọba", adari ajọ CommonWealth, oludabobo igbagbọ", ko to sọ pe "Ọlọrun yoo dabobo Ọba".

Penny Mordaunt pari ayẹyẹ lẹyin to ka awọn ilana ti wọn ki kọ sile sita , ti Ọba Charles kẹta si bẹrẹ si ni ma buwọlu wọn ẹyo kọkan.

Aarẹ igbimọ Privy Council (lo dari ayẹyẹ naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ igbimọ Privy Council (lo dari ayẹyẹ naa
Ayẹyẹ Ikede Ọba Charles gẹgẹ bii Ọba tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọba buwọlu awọn ofin naa ni ẹyọ kọọkan

Lara awọn ni ọjọ ti eto isinku yoo waye pẹlu ọjọ isinmi lẹnu isẹ.

O le ṣe diẹ ki ayẹyẹ ifinijoye Charles to waye . Ọsu mẹrindinlogun lo wa larin ọjọ ti baba Ọbabinrin Elizabeth, Ọba George VI, ọsu keji ọdun 1952 ati 'ọjọ to jẹ oye Ọba ni osu kẹfa ọdun 1953.