Queen Elizabeth II: Kí ni ojúṣe ọba àti pé ta lọ̀rọ̀ ìdílé oyè kàn?

Ọba Charles nibi isin idupẹ aadọrin ọdun ti Ọbabinrin jọba eyi to waye nile ijọsin St Paul lọjọ Kẹta osu Kẹfa, ọdun 2022

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kabiyesi Charles kẹta n gba apere lọwọ iya rẹ lẹyin to papoda lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun.

Ṣaaju ni ibẹrẹ ọdun yii ni ọbabinrin ṣe ẹyẹ ọgọta ọdun to gun ori itẹ, eyi si mu ko jẹ ọba to pẹ julọ lori itẹ ninu itan ilẹ Gẹẹsi.

Ki ni yoo ṣẹlẹ bayii?

Ni kete ti Ọbabinrin Elizabeth dagbere fun aye ni itẹ ọba ilẹ Gẹẹsi ti di ti arẹmọ rẹ, Charles to jẹ Ọmọọba Wales.

Ireti wa pe lọjọ Satide ni wọn yoo ja ewe oye le arẹmọ Ọbabinrin Elizabeth, Charles lori ni aafin St. James's nilu London niwaju igbimọ alabẹ sekele kan ti wọn pe ni Accession Council.

Ki ni ojuṣe Ọba?

Alayeluwa Ọba ilẹ Gẹẹsi ni olori orilẹede ni UK. Amoṣa kii ṣe ipo apaṣeẹ waa ni ipo yii, ṣugbọn ipo to lapẹẹrẹ ni ti ko si gbọdọ rọgbọku si ọdọ igun oṣelu kankan.

L'ojojumọ ni yoo maa gba iroyin ifitonileti lati ọdọ awọn to wa ni igbọnnu iṣejọba ninu apoti ifiweranṣẹ kan ti wọn n pe ni red leather box. Lara awọn iroyin ti wọn maa n fi to o leti ni ikede nipa ipade pataki to n bọ lọna, tabi awọn iwe miran to nilo ibuwọlu re.

Lọpọ igba, ipade maa n waye laarin oun ati olotu ijọba ni Ọjọru ni aafin Buckingham Palace lati mu gbogbo eto iṣejọba to o leti.

Ipade idakọnkọ leyi maa n jẹ lọpọ igba kii sii si akọsilẹ ohunkohun to ba sọ nibẹ.

Oniruru ojuṣe ofin ṣiṣe tun wa fun Ọba ilẹ Gẹẹsi bii:

  • Yiyan ijọba - olori ẹgbẹ oṣelu to ba bori idibo ni wọn maa n pe si aafin Buckingham Palace nibi ti wọn yoo ti dari rẹ pe ko ko igbimọ iṣejọba tuntun jọ. Ọba ilẹ Gẹẹsi naa ni o gbọdọ tu ijoba kan ka ṣaaju idibo apapọ.
  • Ayẹyẹ iside odun ati ọrọ apilẹkọ Ọba - Ọba ilẹ Gẹẹsi a maa side ijoko ọdọọdún awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin orilẹede UK pẹlu ayẹyẹ iṣide ọdun. Yoo kede awọn eto ìjọba fun ọdun naa ninu ọrọ apilẹkọ to ba ba awọn aṣofin agba orilẹede naa sọ.
  • Ibuwọlu ori ade - Nigba ti wọn ba ṣe ofin kan nile igbimọ aṣofin orilẹede UK, Ọba ilẹ Gẹẹsi gbọdọ buwọlu abadofin naa ko to lee di ofin. Ọdun 1708 ni Ọba ilẹ Gẹẹsi fi ipa da abadofin ile aṣofin apapọ orilẹede naa nu keyin.
Ọbabinrin Elizabeth ati Ọmọọba Wales tẹlẹ nibi ayẹyẹ iside ile asofin lọjọ kẹrinla osu Kẹwa, ọdun 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọbabinrin Elizabeth ati Ọmọọba Wales tẹlẹ nibi ayẹyẹ iside ile asofin lọdun 2019

Ni afikun, Oba ilẹ Gẹẹsi a maa gba alejo awọn olori orilẹede, atawọn aṣoju ijọba orilẹede agbaye gbogbo to wa ni UK. Oun naa ni yoo lewaju ayẹyẹ iranti awọn akọni to ṣubu loju ija eyi to maa nnwaye loṣu kọkanla nidi ọwọn iranti to wa nilu London.

Ọba tuntun yii ni olori ajọ orilẹede Commonwealth eyi to jẹ ajọ orilẹede merindinlọgọta pẹlu eeyan biliọnu meji o le irinwo miliọnu wọn. Fun merinla ninu awọn orilẹede wọnyi, Ọba ilẹ Gẹẹsi ni olori orilẹede wọn.

Amọṣa o, lati igba ti orilẹede Barbados ti di ilu Olominira ro n da aṣẹ ara rẹ pa lọdun 2021, ni lara awọn orilẹede miran lati ẹkun Caribean to wa ninu awọn mẹrinla yii ni ajọ Commonwealth naa ti n sọ pe o ṣeeṣe ki awọn pẹlu tọ ipasẹ Barbados.

Aworan Kabiyesi Charles kẹta ni yoo rọpo ti iya rẹ bayii lori oolu ifiweranṣẹ ti ile ọba, Royal mail stamps pẹlu awọn owo ti banki apapọ ilẹ Gẹẹsi bann tẹ sita. Bakan naa ni wọn yoo ṣe atuntẹ iwe aṣẹ irinna silẹ okeerebti ilẹ Gẹẹsi sibti Kabiyesi alayeluwa tuntun.

Bakan naa ni orin adakọ orilẹede naa yoo yipada si, "Ki Ọlọrun da ọba okunrin si" "God Save the King".

Bawo ni ọrọ ọmọ oye to kan ṣe maa n yanju?

Ilana oye jíjẹ nilẹ Gẹẹsi ti yannana eyikeyi ninu awọn ọmọ idile oba ti yoo gba ipo gẹgẹ bi Ọba nigba ti ọba to wa nipo ba waja tabi fi ipo silẹ. Ẹni ti yoo kan naa ni akọbi ọmọ ọba naa.

Gẹgẹ bi akọbi Ọbabinrin Elizabeth ni Charles ṣe bọ sori apere Ọba ti iyawo rẹ, Camilla si di olori ọba.

Lọdun 2013 ni wọn ṣe atunṣe si iwe ofin oye jíjẹ lati rii daju pe oye naa jíjẹ kii fi sọdọ awon Ọmọọba okunrin to ni ẹgbọn to jẹ Ọmọọba obinrin dipo awọn ẹgbọn wọn to jẹ obinrin.

Ọmọọba William to jẹ akọbi Ọba Charles ni ipo naa yoo kan bayii, oun ni yoo si tẹwọ gba ipo Ọmọọba ọlọlajulọ ni Cornwall ti baba rẹ n fi silẹ bayii.O di igba ti baba rẹ ba to fi jẹ oye Ọmọọba Prince of Wales ko to lee jẹ iyẹn.

Lẹyin William, akọbi Ọmọọba William ti orukọ rẹ n jẹ Ọmọọba George ni yoo kan ki o to kan Ọmọọbabinrin Charlotte to jẹ akọbi ọmọ tirẹ naa yoo si jẹ tẹle e.

Aato bi ilana oye jijẹ se jẹ ninu idile ọba Gẹẹsi
Amin iyasọtọ kan

Ki ni yoo ṣẹlẹ nibi ayẹyẹ iwuye?

Ayẹyẹ iwuye ni ibi ti wọn ti n fi ọba jẹ. Eyi yoo waye lẹyìn ti akoko iṣọfọ fun Ọba to waja ba ti pari.

Ni ọjọ kẹfa oṣu keji ọdun 1952 ni Elizabeth keji di Ọbabinrin lẹyin iku baba rẹ, Alayeluwa Oba George kẹfa ṣugbọn ọjọ keji oṣu kẹfa ọdun 1953 ni wọn to de e lade.

Ayẹyẹ iwuye rẹ ni iwuye akọkọ ti yoo waye lori ẹrọ mohunmaworan kaakiri agbaye, ko si din ni ogun miliọnu eeyan to wo o.

Ayẹyẹ igbade ọba Elizabeth losu kẹfa ọdun1953

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Ọbabinrin lasiko ti wọn n gbe ade le lori gẹgẹ bii ọba Kọkandinlogoji eyi to waye ninu ijọ Westminster Abbey

Lati nnkan bii ẹẹdẹgbẹrun ọdun sẹyin, Gbongan Westminster Abbey ni eto iwuye ọba ilẹ Gẹẹsi ti maa n waye - Oba William the conqueror si ni ọba akọkọ to tẹri gba ade nibẹ, Charles ni yoo si di ọba ogoji ti yoo gba ade rẹ níbẹ.

Eto isin ijọ Anglican ni wọn maa fi n ṣe, Biṣọọbu agba Canterbury lo maa n ṣe atọkun ayẹyẹ yii.

Ororo mimọ ti wọn pe ni "holy oil" ni wọn yoo fi yan an, yoo si gba ọpa aṣẹ ati ohun ọṣọ oye 'orb' mejeeji yii jẹ ami oye ọba. Eyi to peleke julọ nibi ayẹyẹ naa ni asiko ti biṣọbu agba ba gbe ade St. Edwards ke Charles lori- kikida goolu Ojulowo ti ko ni abula ni wọn fi ṣe ade naa lati ọdun 1661.

Eyi ni apewaworan ade olokuta iṣura iyebiye ni ile iṣọ ti a mọ si "Tower of London ", igba ayẹyẹ iwuye yii nikan si ni awọn oba Gẹẹsi maa n de ade yii.

Yatọ si ayẹyẹ igbeyawo Ọmọọba, ìjọba lo n ṣe agbatẹru ayẹyẹ iwuye ọba ilẹ Gẹẹsi. Ijoba ni yoo mojuto gbogbo inawo ayẹyẹ naa, oun si ni yoo so awọn alejo to fẹ ko wa síbi ayẹyẹ naa

Awọn wo lo tun jẹ ọmọ idile ọba ilẹ Gẹẹsi?

Awọn mọlẹbi to wa ninu idile ọba nibi ayẹyẹ ọjọ ibi Ọbabinrin

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Awọn mọlẹbi to wa ninu idile ọba nibi ayẹyẹ ọjọ ibi Ọbabinrin ni aafin Buckingham lọdun 2019.
  • The Duke of Cornwall and Cambridge (Ọmọọba Williams) ni akọbi Ọba Charles ati akọfẹ iyawo rẹ, Diana, Ọmọọbabinrin Wales. O fẹ Catherine to jẹ oye Ọmọọbabinrin Cornwall ati Cambridge. Ọmọ meta ni wọn bi: Ọmọọba George, Ọmọọbabinrin Charlotte ati Ọmọọba Louis.
  • The Princess Royal Ọmọọbabinrin Anne) Oun ni Ọbabinrin Elizabeth bi tẹlẹ alayeluwa Charles. Oun nikan si ni ọmọ obinrin to bi. O fẹ ọgagun Timothy Lawrence. Ọmọ meji lo bi fun ọkọ rẹ akọkọ, ọgagun Mark Phillips: Peter Phillips ati Zara Tindall.
  • The Earl of Wessex (Ọmọọba Edward) Oun lo di ipo Earl of Wessex mu ni abigbẹyin Ọbabinrin Elizabeth. O fẹ Sophie Rhys-Jones, Countess of Wessex, wọn si bí ọmọ meji: Louis ati James Mounbatten-Windsor.
  • The Duke of York (Ọmọọba Andrew) Ẹni to di ipo Duke of York mu ni ọmọ ọkunrin keji ti Ọbabinrin Elizabeth bi. O bi ọmọ meji pẹlu iyawo to fẹ tẹlẹ Sarah Ferguson (Duchess of York) : Ọmọọbabinrin Beatrice ati Ọmọọbabinrin Eugenie.
  • The Duke of Sussex (Ọmọoba Harry) Oun ni aburo Ọmọọba William to di ipo Duke of Sussex mu. O fẹ arabinrin Meghan Markle to di ipo Duchess of Sussex. Ọmọ meji ni won bi: Archie ati Lilibet. Lọdun 2020 ni wọn kede pe awọn fẹ yẹba na kuro ninu ojuṣe gẹgẹ bi agba ọjẹ ni idile ọba, ti wọn si rinrinajo lọ sorilẹede Amẹrika.

Nibo ni awọn ọmọ idile ọba ilẹ Gẹẹsi ngbe?

Alayeluwa Ọba Charles ati olori rẹ yoo ko lọ si aafin Buckingham Palace. Clarence House nilu London at Highgrove ni Gloucestershire ni wọn n gbe ṣaaju akoko yii.

Ọmọọba William ati Catherine, to di ipo Duchess of Cornwall ati Cambridge mu naa ko kuro ni aafin Kesingron Palace ni West London lọ si Adelaide cottage ni ile nla Windsor Estate to jẹ ti Ọbabinrin Elizabeth.

Ọmọọba George, Duchess ti Cambridge, Ọmọọba Louis, Duke ti Cambridge ati Ọmọọbabinrin Charlotte fi ọwọkọwọ lati rin lọ sile ẹkọ Lambrook lọjọ akọkọ awọn akẹkọọ naa

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ọmọọba George, Ọmọọbabinrin Charlotte ati Ọmọọba Louis n lọ si ileẹkọ Lambrook School, nitosi Ascot ni Berkshire.

Ọmọọba Harry ati Meghan Markle n gbe ni ilu California.

Ṣe ọrọ idile ọba ṣi n gbajumọ laarin awọn ọmọ Gẹẹsi?

Eto idibo iwadii kan ti YouGov ṣe lasiko ayẹyẹ ọgọta ọdun Ọbabinrin Elizabeth lori oye woye pe ida mejilelọgọta awọn to kopa ninu ibo iwadi naa ni wọn n fẹ ki eto iṣejọba ọlọba, eyi ti oyinbo n pe ni 'monarchy' ṣi tẹsiwaju , ti ida mejilelogun miran ni awọn n fẹ ko jẹ pe olori orilẹede ti araalu dibo yan lawọn n fẹ.

Ibo iwadii meji ti Ipsos Mori ṣe lọdun 2021 naa gbe esi to fẹ fara pẹ eyi jade pẹlu.

Amọṣa, YouGov woye ninu iwadii tirẹ pe iye awọn to n fọwọsi iṣejọba ọlọba lorilẹede naa ti n dinku si lati nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin lati ida marundinlọgọrin ninu ọgọrun lọdun 2012 si mejilelọgọta lọdun 2022.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ lawọn to ṣi n ṣe atilẹyin fun eto iṣejọba ọlọba laarin awọn agbaagba, idibo iwadi naa fihan pe eyi ko fẹ ri bẹẹ laarin awọn ọdọ.

Lọdun 2011, nigba ti YouGov kọkọ bẹrẹ si ni ṣe ọfintoto ọrọ yii, ida mọkandinlọgọta ninu ọgọrun awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si mẹrinlelogun lo fọwọsi si eto iṣejọba ọlọba o tẹsiwaju, eyi to ti wa dinku si ida mẹtalelọgbọn ninu ọgọrun lọdun 2022.