Queen Elizabeth II: Àwọn aṣaájú orílẹ̀èdè lágbàyéé ń ṣèrántí ‘Ọbabìnrin ẹlẹ́yinjú àánú’

Oríṣun àwòrán, 10 Downing Street
Awọn asaaju orilẹede lagbaye atawọn eeyan jankan jankan lagbaye lo ti n sedaro Ọbabinrin Elizabeth keji to ku lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun.
Wọn bu ọla fun iwa akikanju ati isisẹ sin rẹ, to fi mọ abuda awada sise ati ẹyinju aanu to ni.
Aarẹ Emmanuel Macron ti orilẹede Faranse lo lewaju ọrọ ibanikdun naa, to si n ranti ‘Ọbabinrin ẹlẹyinju aanu’ to tun jẹ ‘ọrẹ orilẹede Faranse‘.
Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden lo foju ganni Ọbabinrin naa ni ogoji ọdun sẹyin, to si se apejuwe rẹ bii ‘ẹni to ju ọba lọ - obinrin to duro fun saa kan.’
Nigba to n se iranti abẹwo rẹ silẹ UK lọdun 2021 gẹgẹ bii aarẹ, Ọgbẹni Biden ni ‘O fi iwa akikanju rẹ fa wa mọra, sun mọ wa plu oju aanu rẹ, to si tun salabapin ọgbọn rẹ fun wa."
"Ọbabinrin Elizabeth keji jẹ asaaju awujọ ti ko si ẹni to ni ọwọ to, to si tun jẹ igi lẹyin ọgba ibasepọ to wa laarin ilẹ United Kingdom ati orilẹede Amẹrika. O seranwọ lati jẹ ki ibasepọ wa se pataki." Ọgbẹni Biden lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni aarẹ il China, Xi Jinping naa ti fi isẹ ‘ ibanidaro tootọ sọwọ sijọba ilẹ Gẹẹsi atawọn eeyan rẹ’ lori iku ọbabinrin, o fikun pe ‘ipapoda rẹ jẹ adanu nla fawọn eeyan ilẹ Gẹẹsi.’
Canada - nibi ti Ọbabinrin Elizabeth ti jẹ Olori orilẹede naa - lo ti ri Olootu Ijọba mejila lasiko to wa lori itẹ.
Justin Trudeau - to ti mọ Ọbabinrin fun aimọye ọdun, o ba pade nigba to kọkọ wa ni ọmọde nigba ti baba tiẹ gan j Olootu Ijọba - ni Ọbabinrin ni ifẹ to jinlẹ titi lai fun awọn eeyan orilẹede Canada’.
"Ni aye to ti soro yii, oore ọfẹ to duro ati ipinu rẹ lo mu itunu ba gbogbo wa," Olootu ijba lo sọ bẹẹ pẹlu afikun pe oun yoo saaro ‘itakurọsọ’ awọn, nibi to ti maa n ronu jinlẹ, safihan ọgbọn, seranwọ, lakaka lati se iwadi ati awada pẹlu awọn nnkan miran."
"O jẹ ọkan lara awọn eeyan ti mo fẹran julọ ni agbaye, maa si saaro rẹ pupọ." Justin Trudeau wa n pa ẹkun mọra.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
'Ẹda to yatọ pupọ’
Wọn ti n fa awọn asia wa silẹ de idaji yika agbaye - to fi mọ ajọ isọkan ilẹ Yuroopu (EU) to wa ni Brussels, Belgium.
Aarẹ fun ajọ EU, Ursula von der Leyen, ni ifarada Ọbabinrin ati abuda lati so pọ mọ iran kọọkan to n rekọja lọ, lai yẹsẹ kuro ninu asa to se koko si, jẹ apẹẹrẹ abuda asaaju rere."
Ọbabinrin Margrethe Keji ti Denmark, to tun ku ni obinrin kan soso to jba yika agbaye kọwe ibanikẹdun si Ọba Charles Kẹta.
"Ọbabinrin jẹ eeyan to laagbara laarin awọn ori ade nilẹ Yuroopu ati koriya fun gbogbo wa pata."
O wa se apejuwe akoko aadọrin ọdun isejọba Ọbabinrin bii eyi to le amọ to dara pẹlu ọpọ aseyọri."
Ọba Willem-Alexander ti Netherlands - to tun jẹ ibatan karun si Ọbabinrin Elizabeth - ni oun ati Olori Maxima seranti ‘iduro sinsin ati iwa ọgbọn’ ọba alaye naa pẹlu ‘ọwọ to jinlẹ ati ifẹ nla’.
Ọba Carl XVI Gustaf ti Sweden, to tun jẹ ibatan to jinna si Ọlọlajulọ ni "O jẹ eeyan to se iyebiye si idile mi ati isopọ to sọwọn ninu itan ẹbi ta dijọ wa."
Ọba Philippe ti Belgium ati ayaba Mathilde ni "eeyan pataki to se ara ọtọ...ẹni to jẹ pe ni gbogbo saa isejọba rẹ, safihan ọwọ, igboya ati ifiraẹnijin."
Asaaju orilẹede Germany, Olaf Scholz naa kọrin re ki Ọbabinrin, to si sọrọ imọyi nipa rẹ pe o jẹ ‘Alawada to lagbara‘, to si sọ ninu atẹjade kan pe ‘ifọkansin rẹ si ibadọrẹpọ laarin orilẹede Germany ati Gẹẹsi lẹyin ogun abẹle keji yoo wa ni akọsilẹ titi lae".
Olootu Ijọba ilẹ India, Narendra Modi naa mu wa si iranti nipa awọn "ipade manigbagbe" to waye laarin rẹ ati Ọbabinrin ni igba mejeeji to se abẹwo wa silẹ UK.
"N ko ni gbagbe iwa ikonimọra ati aanu rẹ" O kede bẹẹ loju opo Twitter rẹ. "Lasiko ọkan lara ipade naa, o fi asọ inuju ti Mahatma Ghandi fun gẹgẹ bi ẹbun lọjọ igbeyawo rẹ. Titi aye ni maa maa mọ riri ọwọ ifẹ naa."
Ọba Saudi Arabia, Salman ati Ọmọọba Mohammed bin Salman naa fi isẹ ibanikẹdun wọn ransẹ, ti ba Salman si sapejuwe Ọbabinrin gẹgẹ bii "awokọse rere fawọn asaaju to fẹ fi orukọ rere silẹ ninu iwe itan".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
'Ìwà láyé rẹ fún wá ní ìgboyà'
Gẹgẹ bi Ọlọlajulọ fun ọpọlọpọ ọdun, ọbabinrin Elizabeth gbe igbesi aye to ri iyipada to si farahan ninu orisirisi lẹta ibanikẹdun ti ọpọ fi ransẹ.
Arakunrin Macron sakiyesi pe "Ọnabinrin gbajumọ ilọsiwaju ati ibaṣe alafia fun aadọrin ọdun".
Aaré ana lorilẹede Amẹrika, Barck Obama ni "Ọbabinrin lo aye laarin idagbasoke ati ilọsiwaju- lati ibi ti oṣupa ti bale titi di igba ti Brelin wole".
Olotu agba fun orilẹede Japan, Fumio Kishida fi ẹdun ọkan rẹ ran. "Iku Ọbabinrin, ẹni to saaju ile UK nigba isoro, ko ki n ṣe ile UK ni kan lo padanu, gbogbo orilẹede lagbaye ni.
Aarẹ orilẹede Ireland, Michael d Huggins ni oun gbo osuba Ọbabinrin fun bi ṣe isẹ wọn ni isẹ, tiitan ko si ni gbagbe rẹ.
"Igba Ọbabinrin fun aadọrin ọdun ni o waye pẹlu ọpọilọpa ayipada sugbọn o duro gẹgẹ bi ẹ ni to fi ọkan awọn eeyan orilẹede Britain balẹ.
Micheal Martins ti orilẹede Ireland ni saa Ọbabinrin jẹ ọkan lara saa mọnigbagbe, o ni opin saa kan ni ".
"Bi Ọbabinrin ṣe jara mọ isẹ ati bi o se sin ilu ni ko legbẹ pẹlu ọgbọn ati oye ti ko lẹgbẹ," Arakunrin Martin sọ eleyi ninu atẹjade kan. O ni oun ṣe iranti igba ti Ọbabinrin ṣe abẹwo si orilẹede Ireland lọdun 2011.
Akọwe fun ajọ United Nations, António Guterres ni bi Ọbabinrin 'se wa ni fun ọpọlọpọ ọdun lo mu ọpọlọpọ ayipada wa, papa julọ bi bi awọn orilẹede ni ile Africa ati Asia ṣe gba ominira , ti wọn si tun darpọ ajọ Common Wealth.
Ninu atẹjadae kan, o gbo osuba fun Ọbabinrin bi o ṣ fi gbogbo igbesi aye rẹ sin awọn eeyan. O ni agbaye yoo mu ṣe iranti rẹ fun ipa to ko pẹlu iṣejọba rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọbabinrin ṣe abẹwo si orilẹeede Australia, orilẹede to wa lara awọn orilẹede CommonWealth nibi to jẹ adari- igba mẹrindilogun- Ọlọlajulọ to ṣ adari fun wọn.
Olotu agba Anthony Albanese ni ọpọ ni ko ba ilu mọka ti ko ba ṣe ti Ọbabinrin naa.
"Pẹlu b o ni ri idaduro fun ọpọ ọdun, ko dẹkun lati kuro lẹnu isẹ to n ṣe ati pe o ṣe pẹlu suru."
"O ba wa ṣe ayẹyẹ ọjọ ayọ wa, o duro ti wa nigba isoro. O ni inu dundun ati ọyaya."
Olotu agba fun orilẹedee New Zealand , Jacinda Ardern ni oun ji gbọ iroyin iku Ọbabinrin nigba ti ina ọlọpaa tan ninu iya oun ni dede ago mẹrin lati ji oun.
"Eeyan gidi ni Ọbabinrin jẹ. Ọjọ kẹyin to lo safihan pe o gbinyanju lati se ọpọlọpọ isẹ lori awọn to nifẹ si to fi ku ni."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
'O gbe igbe aye to kun fun itan, o ṣe ohun manigbagbe'
Ọbabinrin Elizabeth II ṣe alabapade awọn aarẹ ilẹ Amẹrika mẹtala - bẹrẹ lati orii Dwight D Eisenhower - nigba aye rẹ.
Aarẹ ilẹ Amẹrika tẹlẹri, Barack Obama ṣe alaye wi pe Ọbabinrin naa "ko gbogbo aye ni papa mọra nipasẹ iṣejọba to kun fun oore ọfẹ, irinisi ti o kun fun ọla ati iṣẹ ṣiṣe lai gbojẹgẹ".
Obama ti o ti ṣe alabapade Ọbabinrin naa ni ọpọ igba ṣe alaye wi pe, "Ni ọpọlọpọ igba ni iwa tutu rẹ, ọwọ irọrun ti o fi mu awọn eeyan ati bi o ṣe n panilẹrin pẹlu awọn ohun amuyẹ ti o jẹ arimaleelọ lawujọ maa n jẹ nnkan iyalẹnu".
Bakan naa ni aarẹ ana lorilẹede Amẹrika, Donald Trump ṣe alaye wi pe "oun ko ni gbagbe ibanidọrẹ to ni oore ninu, ogidi ọgbọn ati awọn awada Ọbabinrin naa".
Aarẹ tẹlẹri mii, George W Bush ṣe iranti igba ti oun ati Ọbabinrin naa jọ joko lati mu 'tea' pẹlu awọn aja ti o n sin gẹgẹ bi o ṣe n ṣe apejuwe adari ilẹ Gẹẹsi naa gẹgẹ bii ọlọgbọn ti o jẹ arimaleelọ, ti o si tun jafafa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ ilẹ Israẹli, Isaac Herzog naa mọ riri awọn ayipada ti Ọbabinrin naa ṣe lasiko ijọba rẹ, ṣugbọn o fi kun ọrọ rẹ wi pe ninu gbogbo rẹ, o duro gẹgẹ bii apẹrẹ adari to duro deede, ti o n ṣe ojuṣe rẹ, ti o si tun duro gẹgẹ bii ami itọkasi fun igbe aye ire ati ṣiṣe olotitọ si ilẹ ẹni".
Botilẹ jẹ wi pe Ọbabinrin ko ṣe abẹwo si ilẹ Israẹli nigba aye rẹ, awọn ọmọọba, Charles, Edward, William ati Oloogbe Prince Philip - ti wọn sin iya rẹ si Jerusalẹmu - ṣe abẹwo si ibẹ.
Aarẹ Herzog ni, "Ọbabinrin Elizabeth jẹ ẹẹyan ti ko ṣee gbagbe ninu itan: o gbe igbe aye itan, o ṣe ohun manigbagbe, bakan naa si ni ipapoda rẹ ti fi apẹrẹ rere lelẹ".
Ọba Abdullah II ti ilu Jordan ṣe alaye wi pe orilẹede rẹ "se idaro ipapoda adari rere".
O ni Ọbabinrin naa ti o ṣe abẹwo si Jordan ni ọdun 1984 lo jẹ apẹrẹ adari ti o kun fun ọgbọn ati ilana antẹle... ojulumọ fun Jordan ati ọrẹ ti o sun mọ ẹbi pẹkipẹki".
Aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymyr Zelensky fi ọrọ lede lori ikanni Twitter wi pe "pẹlu ibanujẹ ọkan" ni oun fi gbọ nipa "adanu ti ko ni atunṣe yii".
Bakan naa ni aarẹ Russia, Vladimir Putin ti o ti ṣe alabapade Ọbabinrin naa ni ọpọlọpọ igba ti iroyin si tun sọ pe o ti daa duro fun iṣẹju mẹrinla ri, fi "ibanikẹdun rẹ" ṣọwọ si Ọba King Charles III.
Ninu atẹjade ti o fi lede, Putin ni, "Pupọ ninu awọn iṣẹlẹ manigbagbe ti o ti waye lorilẹede 'United Kingdom' ni ko ṣẹyin orukọ Ọbabinrin naa".
Awọn adari ilẹ Afrika naa kẹdun lori ipapoda Ọbabinrin Elizabeth - ti o mọ pupọ ninu wọn daadaa gẹgẹ bii adari apapọ awọn orilẹede to n bẹ labẹ iṣakọso rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ tuntun lorilẹede Kenya, William Ruto gbe oriyin fun awọn "ipa ribiribi ti o ko", pẹlu alaye wi pe awọn ọmọ orilẹede Kenya yoo maa "ṣe afẹri ibaṣepọ ti o jẹ anfani rẹ" pẹlu orilẹede naa.
Orilẹede Kenya ti o wa labẹ iṣakoso ilẹ Gẹẹsi tẹlẹri ki wọn to gba ominira lọdun 1963 jẹ ibi kan ti o ṣe pataki si Ọbabinrin naa.
Ni akọkọ, orilẹede naa ni o ti di Ọbabinrin.
O rin irinajo igbafẹ lọ si Kenya lasiko ti o jẹ ọmọọba lẹni ọdun mẹẹdọgbọn. Nibẹ sini o ti gbọ iroyin wi pe baba rẹ, Ọba George VI wọ aja lati oju orun lọdun 1952.
Aarẹ Bongo Ondimba ti orilẹede Gabon ti o jẹ ọkan lara awọn orilẹede ti o tuntun ju ninu awọn orilẹede to ni ilepa ati ifojusun kan naa ṣe alaye wi pe, "Ọbabinrin naa jẹ ọrẹ Afrika, bẹẹ sini o ṣe afihan ifẹ rẹ".
Bakan naa ni aarẹ Nana Akufo-Addo ti orilẹede Ghana fi ọrọ lede lori ikanni Twitter wi pe orilẹede naa ni iranti abẹwo meji ọtọọtọ ti Ọbabinrin naa ṣe, gẹgẹ bi o ṣe mẹnuba "bi o ṣe n ba ni dọrẹ, irinisi rẹ ati ayọ ti o fi n ṣe awọn ojuṣe rẹ".
Abẹwo akọkọ ti o ṣe si orilẹede Ghana ti o wa labẹ akoso ilẹ Gẹẹsi tẹlẹri lo mu awuyewuye lọwọ nitori ifoya ti o niṣẹ pẹlu aabo Ọbabinrin naa.
Ọjọ marun sun saaju abẹwo rẹ ni ado oloro bu gbamu ni olu ilu orilẹede naa, Accra, ṣugbọn eyii ko di Ọbabinrin naa lọwọ nitori o ti wọgile abẹwo to yẹ ki o ṣe tẹlẹri lasiko ti o loyun Ọmọọba Andrew.

Oríṣun àwòrán, Getty Images












