Prince Charles III: Ọ̀rọ̀ Ọba tuntun rèé sí àwọn ará Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Àjọ Commonwealth

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọba Charles kẹ́ta sọ àwọn wọ̀nyí fún ilé UK àti àjọ Commonwealth:
"Mo ba yin sọrọ pẹlu ibanujẹ ọkan loni. Ni gbogbo Igbesi aye, Ọbabinrin- Iyami to tọ lo wu ni lori, to si jẹ apẹẹrẹ rere fun ẹmi ati mọlẹbi mi, ati a jẹ ni gbese ti ọmọ le jẹ iya rẹ fun ifẹ ati bi o ṣe tọ wa pẹlu apẹẹrẹ rere.
"Ọbabinrin Elizabeth ge igbesi aye gidi:, ileri to wa si imusẹ, to si kẹdun to lọ nigba aye rẹ.
"Ileri ayereye to ṣẹ fun yin lati si yin, ma tẹsiwaju ilẹri naa fun yii loni
"Yatọ si ifoya mi ati ti awọn mọlẹbi mi, a ba yin eeyan ile UK kẹdun, gbogbo orilẹeede ti Ọbabinrin ti jẹ adari, ni ajọ commonwealth ati kaakiri agbaye, mo dupe fun aadọrin ọdun eyi ti iya mi lo lati fi sin awọn eeyan lati orilẹede kaakiri agbaye.
"Lọdun 1947, lọjọ ti iya mi pe ọmọ ọdun mọkanlelogun, o ṣe ibura lati ilu Cape Town lati fi igbesi aye rẹ, kukuro tabi gungun si nawọn eeyan.
"Eyi ju ileri lọ, o gbe aye silẹ ni, to si duro ti ileri naa.
"O si isẹ rẹ pẹlu otitọ ọkanati fifi ara ẹni jin pẹlu bi igba sẹ n iyipada, ọjọ ayo ati idunu, ọjọ ikioro ati ọfọ.
"Nigba igbesi aye rẹ, a ri pe ifẹ wa fun isẹse, ajọsepọ lati ni ilọsiwaju eyi to mu di orilẹede nla.
"Ifẹ, ọwọ to ni jẹ ami nla fun ayeraye. Gbogbo ọmọ ẹbi le jẹ ri, O wu awọn wọnyi pẹlu suru, ẹfẹ lati ohun gidi jade lara awọn eeyan.
''Mo ṣe idaro iya mi ati iranti rẹ fun iṣẹ takuntakun to ṣe fun ara ilu. Mo mọ wi pe iku rẹ jẹ ibanujẹ fun ọpọ eniyan to si bami ninu jẹ ju bi mo ṣe le ṣalaye lọ.''
''Nigba ti Ọbabinrin gun ori itẹ, Ilẹ Gẹẹsi ṣi n koju ipa ti Ọgun agbaye Keji ni lara wọn, ti wọn si n gbe igbe aye ogun nigba naa.''
''Lati bi aadọrin ọdun, a ri ti awujọ wa gba atunṣe ni ọra asa ati iṣe miran to fi mọ ọrọ ẹsin.''
''Bakan naa ni iṣejọba ile ọba naa ti yipada, amọ ninu ohun gbogbo atunṣe ayọ lo de ba asa ati iṣe ilẹ Gẹẹsi ti ohun ti a gbagbọ ninu rẹ si duro laelae''
''Bakan naa ni iṣe ati iṣe ọba duro lai wẹyin, paapaa ojuṣe rẹ si ijọ Church Of England- nibi ti igbagbọ mi rọ mọ.''
''Ninu igbagbọ yii ni mo ti mọ bi a ṣe n bọwọ fun ojuṣe ẹni, ki a si bọwọ fun aṣa ati iṣe, to fi mọ itan ati iṣejọba awarawa.''
''Gẹgẹ bi Ọbabinrin ṣe ṣe lai wẹyin, emi naa yoo ṣe titi gbogbo ọjọ aye mi ti Ọlọrun yoo fun mi ni oke erupẹ.''
''Mo mọ pe aye mi yoo yipada bi iṣe mi yoo ṣe pọsi, ti ko si ni si akoko lati fi ṣe awọn nkan miran ti mo ma n ṣe.''
''Asiko yii yoo yipada fun ẹbimi bakan naa, amọ mo jẹjẹ lati fẹran iyawo ti a ṣegbeyawo ni ọdun mẹtadinlogun ṣẹyin, to si ti di ayaba bayii. Mo mọ wi pe yoo ṣe iṣẹ rẹ pẹlu gbogbo agbara rẹ.''
''Gẹgẹ bi arole mi, Willam ti gba ami ẹyẹ ỌBAKUNRIN Wales, ipo ti mo dimu fun ọpọlọpọ ọdun ati igba aye mi.''
''Pẹlu Catherine lẹgbẹ rẹ, yoo ṣiṣẹ takuntakun lati mu idagbasoke ba Ilẹ Gẹẹsi.''
''Bakan naa ni mo fi ifẹ mi han si Meghan ati Harry ti wọn yoo ma gbe ni oke okun lati gbe igbe aye ti wọn.''
''Lai pẹ si isnyii, ni gbogbo agbaye yoo parapọ lati sin oku mama bi. Pẹlu ibanujẹ ọkan, amọ a fi agbara fun iru igbe aye ti wọn gbe . Ti a si dupẹ lọwọ gbogbo eniyan fun aduroti wọn.''
''Ọrọ mi si Mama mi olufẹ mi pataki ni pe bi o ṣe n lọ ba abba mi to ti lọ naa, ohun ti mo fẹ sọ ni pe , ẹ ṣeun fun aduroti yin ati fun gbogbo awọn ẹbi ni agbaye.''
''Mo fi orin iyin sin lọ si ọrun aremabọ''












