Death of Queen Elizabeth II: Ìdí igi ìdílé ọba nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn tó le jọba
Lẹ́yìn ìpapòdà Ọbabìnrin Elizabeth II, àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, Charles ti di Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì báyìí.
Orúkọ tí wọ́n yóò máa pe Ọba tuntun náà ni Ọba Charles Kẹta, láti 1685 tí ọba Charles Keji ti kúrò lórí ìtẹ́ ọba.
Ọbabìnrin Elizabeth tó kú ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹsàn-án ni Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó pẹ́ lórí oyè náà jùlọ pẹ̀lú bó ṣe lo àádọ́rin ọdún lórí ìtẹ́ ọba.
Àwòrán bí ìdí igi ìdílé Ọba náà ṣe lọ rèé

Ọbabìnrin Elizabeth àti ọkọ rẹ̀, ọmọọba Philip, Duke ti Edinburgh
Ọbabìnrin Elizabeth tó dágbére fáyé ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2022 lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ̀rún ni Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó pẹ́ jùlọ lórí ìtẹ́ ọba bó ṣe lo àádọ́rin ọdún lórí àpèrè àwọn baba rẹ̀.
Ní ọdún 1926 ní wọ́n bí Ọbabìnrin Elizabeth tó sì gorí ìtẹ́ ọba lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, Ọba George Kẹfà, lọ́dún 1952.
Ní ọdún 1947 ní Ọbabìnrin Elizabeth ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ọmọọba Philip, Duke ti Edinburgh tí Ọlọ́run sì fi ọmọ mẹ́rin tawọ́n lọ́rẹ: Charles, Anne, Andrew àti Edward.
Duke ni àná oyè tó pẹ́ jùlọ lórí oyè kó tó fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dún 2017. Ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Kẹrin, ọdún 2021 ló jáde láyé.

Oríṣun àwòrán, Alamy
Ọba Charles III
Ní ọdún 1948 ni wọ́n bí Ọba Charles Kẹta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní kété tí Ọbabìnrin Elizabeth papòdà ni Charles ti di ọba gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí.
Ọba Charles tó jẹ́ ọmọọba Wales tẹ́lẹ̀ gbé Diana Spencer níyàwó ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 1981 tí wọ́n sì bí ọmọ méjì, William àti Harry.
Ní ọdún 1996 ni ìgbéyàwó wọn túká, tí Diana sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ síní ìjàmbá ọkọ̀ ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ, ọdún 1997 ní Paris.
Ọba Charles fẹ́ Camilla Parker Bowles ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹrin, ọdún 2005. Ọbabìnrin Elizabeth ṣaájú ikú rẹ̀ ní Camilla, tó jẹ́ Duchess ti Cornwall ni òun fẹ́ kó joyè olorì láàfin tí Charles bá jọba.
Àwọn tó le jẹ́ ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
1. Ọmọọba William, Duke Cornwall àti Cambridge
Ní ọdún 1982 ni wọ́n bi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọọba William ni àkọ́bí ọmọ tí Ọba Charles III àti Diana, Ọmọọbabìnrin Wales bí papọ̀. Òun ni ẹni tí oyè ọba kàn lẹ́yìn bàbá rẹ̀.
Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ló wà nígbà tí ìyá rẹ̀ jáde láyé.
Ilé ẹ̀kọ́ gíga fásità St Adrews ló ti kẹ́kọ̀ọ́, níbẹ̀ ló sì ti pàdé ìyàwó rẹ̀, Kate Middleton, tí wọ́n sì ṣe ìgbéyàwó lọ́dún 2011.
Nígbà tó pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ni wọ́n yàn-án bí aṣojú ìlú tó sì máa ń ṣojú Ọbabìnrin níbi àwọn isẹ́ ìlú.
Ní ọdún 2013 ni òun àti ìyàwó rẹ̀ bí àkọ́bí ọmọ wọn, George. Ọdún 2015 ni wan bí Charlotte tí wọ́n sì bí Louis ní ọdún 2018.
William ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun ilẹ̀, ọmọ ogun orí omi àti ti òfurufú kó tó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa wíwa ọkọ̀ òfurufú tí wọ́n fi ń dóòlà ẹ̀mí fún ọdún mẹ́ta pẹ̀lú RAF Valley ní Anglesey, àríwá Wales.
Ó ṣiṣẹ́ bí ìgbákejì awakọ̀ òfurufú tó ń dóòlà ẹ̀mí ti East Anglican fún ọdún méjì kó tó kúrò lọ́dún 2017 láti gbájúmọ́ iṣẹ́ ìlú lórúkọ Ọbabìnrin àti Duke Edinburgh.
Ọmọọba William kò ní di Ọmọọba Wales lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àmọ́ ó ti gba ipò bàbá rẹ̀, Duke ti Cornwall. William àti ìyàwó rẹ̀ Kate ti di Duke àti Duchess Cornwall àti Cambridge báyìí.
Gẹ́gẹ́ bí àrẹ̀mọ, iṣẹ́ rẹ̀ ni láti ṣàtìlẹyìn fún Ọba lórí iṣẹ́ ìlú tó gbé dání.
2. Ọmọọba George ti Cornwall àti Cambridge
Ọdún 2013 ni wọ́n bí George

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Keje, ọdún 2013 ni wọ́n bí Ọmọọba George ti Cornwall àti Cambridge sí ilé ìwòsàn St Mary ìlú London níbi tí bàbá rẹ̀ ti wà ní ìkàlẹ̀.
Òun ni ẹnìkejì tí oyè Ọba Gẹ̀ẹ́sì kàn lẹ́yìn bàbá rẹ̀.
3. Ọmọọbabìnrin Charlotte ti Cornwall àti Cambridge
Ní ọdún 2015 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́ kejì oṣù Karùn-ún, ọdún 2015 ni Duchess Cornwall àti Cambridge bímọ kejì tó jẹ́ obìnrin sílé ìwòsàn St Mary bákan náà tí wọ́n sì sọ ọmọ náà ní Charlotte Elizabeth Diana.
Lẹ́yìn bàbá àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Charlotte ọmọbabìnrin Cornwall àti Cambridge ló tún lẹ́tọ̀ọ́ sí oyè ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
4. Ọmọọba Louis ti Cornwall àti Cambridge
Ọdún 2018 ló dé ayé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kẹrin ni wọ́n bí Louis Arthur Charles sí ilé ìwòsàn St Mary ìlú London bákan náà.
Louis ni ọmọọba kẹrin tó le jẹ Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
5. Ọmọọba Harry, Duke Sussex
Ní ọdún 1984 ni wọ́n bí Harry

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọọba Harry kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé iṣẹ́ ọmọ ogun tí ilé oyè ní Sandhurst tó sì di ọ̀gá tó ń wa ọkọ̀ òfurufú helicopter.
Fún ọdún mẹ́wàá tó lò nínú iṣẹ́ ológun, Capt Wales gẹ́gẹ́ bí orúkọ ìnagijẹ tí wọ́n máa ń pè é kópa ní Afghanistan ni ẹ̀ẹmèjì lọ́dún 2012 àti 2013 gẹ́gẹ́ bí ìgbákejì awakọ̀ helicopter.
Ní ọdún 2015 ló fi iṣẹ́ ogun kalẹ̀ láti gbájúmọ́ iṣẹ́ ìtọrẹ àánú ni ṣíṣe tó fi mọ́ àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti ṣíṣètò eré ìdárayá fún àwọn ológun tó bá farapá lójú ogun.
Láti ìgbà tó ti wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ló ti jẹ Counsellor of State tó sì ń ṣojú Ọbabìnrin ní àwọn iṣẹ́ ìlú.
Ní ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2018 ló ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú òṣèré tíátà ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Meghan Markle ní Windsor Castle. Ní oṣù kìíní ọdún 2020 ni wọ́n kéde wí pé àwọn fẹ́ yọwọ́ nínú ṣíṣe ìlú.
Wọ́n ní àwọn fẹ́ máa gbé láàárín UK sí apá àríwá Amẹ́ríkà àti pé àwọn fẹ́ ṣiṣẹ́ láti ní owó fúnra àwọn.
Lẹ́yìn ọdún kan sígbà náà ni ààfin Buckingham kéde pé àwọn tọkọtaya náà kò ní kópa nínú iṣẹ́ ìlú kankan mọ́ àti pé gbogbo iṣẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n ń ṣe ni wọn yóò fi kalẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àǹfàní rẹ̀.
6. Archie Harrison Mountbatten-Windsor
Ọdún 2019 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àkọ́bí Harry àti Meghan ni Archie Harrison Mountbatten-Windsor, ọjọ́ Kẹfà oṣù Karùn-ún, ọdún 2019 ni wọ́n bi. Pẹ̀lú orúkọ tí àwọn òbí rẹ̀ fún-un, ó hàn gbangba pé àwọn òbí rẹ̀ kò fẹ́ lo orúkọ kankan fún ọmọ náà.
Nígbà tí wọ́n kéde orúkọ ọmọ ọ̀hún akọ̀ròyìn BBC ní ààfin, Jonny Dymond ní ìpinnu àwọn òbí rẹ̀ hàn wí pé wọn kò fẹ́ tọ ní ìlànà ọmọ ọba.
7. Lilibet Diana Mountbatten-Windsor
Ní ọdún 2021 ni wọ́n bi
Ní Santa Barbara ní California ni Duchess Sussex bí ọmọ rẹ̀ kejì sí lọ́jọ́ Kẹrin oṣù Kẹfà, ọdún 2021. Lilibet Diana Mountbatten-Windsor tí wọ́n ń pè ní Lili, tó jẹ́ orúkọ oyè tí wọ́n máa ń pe Ọbabìnrin Elizabeth.
Wọ́n fun ní orúkọ àbísọ Diana ní ìrántí ìyá Ọmọọba Harry tó pàdánù lmí rẹ̀ sínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́dún 1997 nígbà tí Harry wà ní ọmọ ọdún méjìlá.
8. Duke ti York
Ọdún 1960 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọọba Andrew ni ẹni tó wà ní ipò kẹjọ sí ẹni tó le jẹ ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, òun sì ni ọmọ Kẹta tí Ọbabìnrin Elizabeth àti Duke Edinburgh bí.
Òun ni ọmọ àkọ́kọ́ tí Ọba yóò lórí oyè lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlélọ́gọ̀rún tí irú rẹ̀ ti wáyé kẹ́yìn.
Lẹ́yìn tó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Sarah Ferguson ló di Duke ti York lọ́dún 1986. Ọmọbìnrin méjì ni wọ́n bi Beatrice àti Eugenie lọ́dún 1988 àti 1990.
Ní oṣù kẹta ọdún 1992 ni wọ́n kọ́kọ́ kéde wí pé tọkọtaya náà yóò pínyà kí wọ́n tó pínyà lọ́dún 1996.
Ọdún méjìlélógún ni Duke lò nínú iṣẹ́ oógun orí omi tó sì kópa nínú ogun Falklands lọ́dún 1982. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìlú tó ń ṣe, ó ṣe aṣojú ìjọba lórí okoòwò títí di ọdún 2011.
Ọmọọba Andrew yẹ̀bá nínú iṣẹ́ oyè lọ́dún 2019 lkyìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú BBC lórí ìbáṣepọ̀ tó ní pẹ̀lú ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan, Jeffrey Epstein, ẹni tó pa ara rẹ̀ lásíkò tó ń dúró de ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn wí pé ó ń fi àwọn ènìyàn ṣe aṣẹ́wó àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn.
Ní oṣù Kejì, Andrew gbà láti san owó kan tí wọn kò fi iye rẹ̀ léde fún obìnrin ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Epstein ṣe jàmbá fún fẹ̀sùn wí pé ó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ àmọ́ Andrew jìyàn ẹ̀sùn náà.
9. Ọmọọbabìnrin Beatrice
Ọdún 1988 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọọbabìnrin Beatrice ni àkọ́bí ọmọ tí Andrew àti Sarah bí, tí wọ́n sì ń pè é ní ọlọ́lájùlọ ọmọbabìnrin Beatrice ti York. Kò ní orúkọ bàbá kan tó ń jẹ́ ní pató àmọ́ York ló ń lò.
Ní oṣù Keje, ọdún 2020 ló fẹ́ Edorado Mapeli Mozzi ní Royal Chapel ti All Saint of Royal Lodge, Windsor. Nínú oṣù karùn-ún ọdún ni wọ́n kọ́kọ́ fi ìgbéyàwó náà kí coronavirus tó ṣe okùnfà ìdí tí wọ́n fi sun síwájú.
10. Sienna Elizabeth Mapelli Mozzi
Ní ọdún 2021 ni wọ́n bi
Nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2021 ni Ọmọọbabìnrin Beatrice bí Sienna Elizabeth, ẹni tó wà ní ipò kẹwàá sí ẹni tó le jẹ ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Òun sì ni ọmọọmọọmọ kejìlá tí Ọbabìnrin Elizabeth ní. Ọmọọbabìnrin Beatrice tún ìyá fún ọmọ ọkọ rẹ̀, Christopher Woolf tí Dara Haung bí fun.
11. Ọmọọbabìnrin Eugenie
Ní ọdún 1990 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọọbabìnrin Eugenie ni ọmọ Ọmọọba Andrew àti Sarah tó kéré, òun sì ni ẹni tó wà ní ipò kọkànlá sí ẹni tó le jẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́wọ́lọ́wọ́.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun náà kò ní orúkọ bàbá tóún jẹ́ ní pàtó, York ni òun náà ń lò. Ní ọdún 2018 ló fẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, Jack Brooksbank ní ààfin Windsor.
12. August Philip Hawke Brooksbank
Ní ọdún 2021 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ ọmọọbabìnrin Eugenie àti Jack Brooksbank, August, tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹsàn-án, oṣù kejì ọdún 2021 ni ọmọọmọọmọ Ọbabìnrin kẹsàn-án.
13. Earl ti Wessex
Ní ọdún 1964 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọọba Edward gba oyè Earl Wessex àti Viscount Severn lẹ́yìn ìgbéyàwó rẹ̀ sí Sophie Rhys-Jones lọ́dún 1999. Ọmọ méjì ni wọ́n bí: Lady Louise àti James Viscount Severn tí wọ́n lọ́dún 2003 àti 2007.
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ìdílé wọn, ọmọọba Edward da ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ti ara rẹ̀ kalẹ̀, tó sì tún ń ṣe àtìlẹyìn fún Ọbabìnrin lórí àwọn iṣẹ́ ìlú. Òun ni ẹni tó wà ní ipò kẹtàlá sí àwọn tó le jẹ oyè ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
14. James, Viscount Severn
Ọdún 2007 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, PA
Viscount Severn ni àbúrò nínú ọmọ méjì Edward àti ìyàwó rẹ̀ Countess ti Wessex bí. Ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Earl ni wọ́n ń pe àwọn ọmọ wọn dípò ọmọọba tí wọ́n máa ń fún àwọn ọmọ ní ìdílé wọn. Ìgbàgbọ́ ni wí pé nítorí à ti má fẹ̀ẹ́ kí àwọn ọmọ náà dá sí ọ̀rọ̀ oyè tó bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún wọn ní àwọn orúkọ náà.
15. Lady Louise
Ọdún 2003 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, PA Media
Lady Louise Windsor ni àkọ́bí ọmọ tí Earl àti Countess Wessex bí àmọ́ nítorí wí pé wọ́n ti bi kí wọ́n tó m;u àyípadà bá òfin tó ní ọmọkùnrin tó bá jẹ́ àbúrò lé jẹ ọba ṣíwájú ẹ̀gbọ́n ni àbúrò fi wà níwájú rẹ̀ nínú ààtò àwọn tó le jẹ ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
16. Ọmọọbabìnrin Anne
Ní ọdún 1950 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọọbabìnrin Anne ti ọmọ kejì àti obìnrin kan ṣoṣo tí Ọbabìnrin Elizabeth bí. Nígbà tí wọ́n bi, òun ló wà ní ipò kẹta ààtò àwọn tó le jọba ṣùgbọ́n tó ti wà ní ipò kẹrìndínlógún báyìí. Ní oṣù kẹfà ọdún 1987 ni wọ́n fun ní oyè Ọmọọbabìnrin orí adé.
Ẹ̀ẹmèjì ní Ọmọọbabìnrin Anne ti ṣe ìgbéyàwó: ọkọ àkọ́kọ́ rẹ̀ ni Ọ̀gágun Mark Phillips, ẹni tó bí ọmọ méjì fún, Peter àti Zara. Ọkọ kejì ni Vice-Admiral Timothy Lawrence.
Ọmọọbabìnrin Anne ló kọ́kọ́ lo orúkọ Mountbatten-Windsor lẹ́yìn ìgbéyàwó pẹ̀lú Capt Phillips. Ó kópa nínú ìdíje eré ìdárayá equestrian fún Great Britain níbi ìdíje Montreal Olympics lọ́dún 1976, tó sì tún ti kópa lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú bíi "Save the Children", èyí tó jẹ́ ààrẹ láti ọdún 1970.
17. Peter Phillips
Ní ọdún 1977 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Peter Phillips ni àkọ́bí ọmọọmọ tí Ọbabìnrin Elizabeth ní. Ọmọ orílẹ̀ èdè Canada, Autumn Kelly ló fẹ́ ní ọdún 2008 tí wọ́n sì bí ọmọ méjì: Savannah àti Isla tí wọ́n bí ní ọdún 2010 àti 2012.
Àwọn ọmọ Anne kò ní orúkọ oyè nítorí wí pé ọmọ obìnrin ni wọ́n. Mark Phillips kọ̀ láti gba oyè Earldom nígbà tó fẹ́ Anne nítorí náà àwọn ọmọ wọn kò ní orúkọ oyè.
Ní ọdún 2020 ni Peter Phillips àti ìyàwó rẹ̀ kéde wí pé àwọn fẹ́ kọ ara àwọn sílẹ̀.
18. Savannah Phillips
Ní ọdún 2010 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, PA Media
Savannah Phillips tí wọ́n bí ní ọdún 2010 ni àkọ́bí ọmọ Peter àti Autumn Phillips, òun náà sì ni àkọ́bí ọmọọmọọmọ Ọbabìnrin Elizabeth.
19. Isla Phillips
Ní ọdún 2012 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, PA Media
Isla Phillips tí wọ́n bí ní ọdún 2012 ni ọmọ kejì tí Peter àti Autumn Phillips bí.
20. Zara Tindall
Ní ọdún 1981 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Zara Tindall mú ọwọ́ àwọn òbí rẹ̀ nínú ìdíje eré sísá tó sì gbé ipò kejì níbi ìdíje Olympics ìlú London lọ́dún 2012. Ó fẹ́ Mike Tindall tó ń gbá rugby lọ́dún 2011 tí wọ́n sì bí àkọ́bí ọmọ lọ́dún 2014.
Àwọn ọmọ Anne kò ní orúkọ oyè nítorí wí pé ọmọ obìnrin ni wọ́n ṣùgbọ́n òun ló wà ní ipò ogún àwọn tó le jẹ ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Mark Phillips kọ̀ láti gba oyè Earldom nígbà tó fẹ́ Anne nítorí náà àwọn ọmọ wọn kò ní orúkọ oyè.
21. Mia Grace Tindall
Ní ọdún 2014 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní oṣù Kìíní, ọdún 2014 ni Zara Tindall bí ọmọ rẹ̀ àkọ́kọ́, Mia Grace.
22. Lena Elizabeth Tindall
Ní ọdún 2018 ni wọ́n bi

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹfà ọdún 2018 ni Zara àti Mike Tindall bí ọmọ wọn kejì ní Stroud Maternity, Gloucestershir.
Lena Elizabeth ni wọ́n sọ ni orúkọ olóògbé Ọbabìnrin.
Bíi ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Lena Elizabeth náà kò ní orúkọ oyè ti wọ́n yóò sì máa pè ní ọmọbìnrin Tindall.
23. Lucas Philip Tindall
Ní ọdún 2021 ni wọ́n bi
Zara àti Mike bí ọmọ wọn kẹta ní ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹta ọdún 2021.












