Queen Elizabeth II: Níbo àti ìgbà tí ètò ìsìnkú Obabìnrin Elizabeth máa wáyé?

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ọbabinrin yoo wa ni itẹ oku fun ọjọ mẹrin ki eto isinku to waye ni Westminster Abbey lọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, ọsu kẹsan an.
Awọn araalu yoo ni anfani lati ri posi Ọbabinrin nigba naa.
Ko to di igba naa, Ọbabinrin yoo maa sinmi ni ijọ Aguda St Giles ni Edinburgh fun wakati mẹrinlelogun lati ọjọ aje ọjọ kokanla , ti awọn yoo si ni anfani ṣe ibọwọ kẹyin fun.
Mọlẹbi, oloṣelu ati awọn olori lagbaye ni yoo wa ni bi eto isinku naa ni dede ago mọkanla lọjọ, to jẹ ọjọ isimi.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lati Balmoral, Aberdeenshire, nibi to ku si, Posi Ọbabinrin yo gbera lọjọ aiku lọ si Edinburgh, ti yoo si ma rin jẹjẹ lọ si aafin Holyroodhouse ni dede ago mẹrin.
Lọsan ọjọ aiku, yoo gbera lọ si ijọ ajuda St Giles ni Edinburgh pẹlu awọn mọlẹbi ori ade. Eto adura yoo waye, ti posi naa yoo si wa ni itẹ oku fun wakati mẹrinlelogun lati fun awọn eeyan ni anfani lati ṣe ibọwọ ikẹyin.
Lọjọ keji, Ọmọba Binrin Anne yoo tẹle oku Iya rẹ to ba ti balẹ si ilu London. Posi Ọbabinrin ni yoo gbera lati papa ọkọ ofurufu Edinburgh lọ si aafin Buckingham
Lọsan ọjọru, wọn yoo gbe oku naa lọ si Westminster ni dede ajo mẹta. Ọjọ mẹrin ni itẹ oku naa yoo fi waye lati ọjọru, ki eto isinku to waye.
Eto isinku ijọba yoo waye ni dede ago mọkanla ni ọjọ kọkandilogun, ti wọn yoo gbera lọ is aafin Windsor, pẹlu irin gungun. Ọbabinrin naa yoo wọ ka ile ni itẹ oku King George ni Windsor.
Ọba yóò bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò lọ sí àwọn orílẹèdè
Saaju eto isinku, Ọba tuntun yoo irin irinajo lọ si orilẹede Scotland, Northern Ireland ati Wales.
Di daro lọrilẹede UK yoo tẹsiwaju titi eti isinku ijọba yoo waye, ijọba ti kede. Mọlẹbi ori ade yoo ṣe idaro fun ọjọ meje lẹyin naa
Ile jọsin Westmister Abbey jẹ ile jọsin nibi awọn Ọba ile UK ti ma de ade sugbọn ko si eto ifini jọba fun ọjọ pipẹ. Eto isinku baba Ọbabinrin, Baba to bi baba rẹ ati Iya nla rẹ, Ọbabinrin VIctoria waye ni ijọ aguda St Geroge ni Windsor.

Awọn adari lagbaye yoo darapo mọ awọn mọlẹbi ori ade lati ṣe iranti igbesi ati isẹ Ọbabinrin.
Awọn agba oselu ati awọn olotu ijọba tẹlẹri at lọwọlọwọ yoo wa nibi ayẹyẹ naa
Wọn ko da ẹnikẹni to ba nbi nkan ṣe lọjọ naa duro sugbọn ijọba gba awọn ajọ ere idaraya ni imọran pe ki wọn sun awọn ifẹsẹwọnsẹ wọn siwaju lati ma le ṣe idaduro eto isinku naa.
Awọn ayẹyẹ to yẹ ko waye ni wọn ti sun siwaju kete ti Ọbabinrin papoda.

Ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu ni ligi Premier League. ligi ile gẹẹsi lorilẹede Scotland tabi ni Northern Ireland ni wọn ti sun siwaju di ọjọ iṣegun, ti awọn ligi obinrin ti wa ni idaduri. Ọpọlọpọ awọn ere ẹrin gungun, ẹsẹ kikan ni wọn da duro.
Ọpọlọpọ ayẹyẹ to yẹ ko waye ni ọsẹ to n bọ ni wọn ti daro, ti ajọ Trade Union Congress ti da ayẹyẹ wọn to ma waye lọdọdun ni Brighton duro.
Ọba sọ si lọjọ Satide pe eto isinku naa yo waye lọjọ isimi nigba ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi Ọba ni aafin St James niluu London.
Ninu ọrọ rẹ, o gbo osuna fun Ọbabinrin, to si ni igba rẹ ko lẹgbẹ.

Oríṣun àwòrán, Jonathan Brady/PA
Ọba di olori ni kete ti iya rẹ papoda sugbọn ipade awọn ajọ awọn oloselu, alufaa ati osisẹ lo kede rẹ.
Ipada naa ni awọn olotu agba ile UK pẹlu awọn miiran lo wa nibẹ. Ikede naa ni wọn ka ni ita aafin St James lọjọ Eti.
Akọwe ajọ igbinmọ Privy, Richard Tilbrook kede Charlse gẹgẹ bi "Ọba,m adari ajọ Commonwealth, Oludabo bo igbagbọ", ko to wa ni ki "Ọlọrun dabo bo Ọba".














