King Charles III: Irú Ọba wo ní Charles yóò jẹ́?

Oríṣun àwòrán, PA Media

Charles, tii se arole to pẹ lori ipo naa julọ ninu itan ilẹ Gẹẹsi, ti di ba.
Aadọrin ọdun gbako lo fi kọ isẹ naa bii arole Ọba, ti eyi si ti jẹ ko gbaradi pupọ ati Ọba tuntun to tii dagba julọti yoo gori itẹ.
ọba naa, tii se ẹni ọdun mẹtalelaadọrin wa pẹlu mama rẹ ni gbogbo igba to fi wa lori itẹ, to si ti foju ri bi aimọye iran awọn olori to ti jẹ ni agbaye se n wa, ti wọn si n lọ, to fi mọ Olootu ijọba mẹẹdogun to jẹ nilẹ UK ati aarẹ mẹrinla to ti dari orilẹede Amẹrika sẹyin.
Lẹyin saa Ọbabinrin Elizabeth to kun fun aseyọri, iru Ọba wo ni ka wa maa reti? Ati pe, bawo ni Ọmọọba tẹlẹ, to ti mọ lara lati maa n sọrọ soke lori awọn ọrọ to ba ta a lara, yoo se bẹrẹ si duro si ipo aisegbe sibi kan, to yẹ ki Ọba se?
Gẹgẹ bii Ọba, Charles ko ni lanfaani mọ si iwe irina silẹ okeere tabi iwe iwakọ rẹ to n lo tẹlẹ - tabi ko sọ ero rẹ nipa ohunkohun nita gbangba nitori pe o jẹ Ọba. Ipo Ọba bori ero ẹnikẹni.
Ọrọ naa wa dabi ojuse to yatọ, ofin to se ọtọ, eyi ni ero asaaju onimọ nipa ofin kan, Ọjọgbọn Vernon Bogdanor.
"O ti mọ lati ibẹrẹ aye rẹ pe ilana igbe aye rẹ naa yoo yatọ. Awọn araalu ko ni fẹ Ọba ti yoo maa se ipolongo kiri," Ọjọgbọn Bogdanor lo sọ bẹẹ.
Ọba Charles mọ idi to fi yẹ ki oun mase maa sọrọ lọpọ igba nita gbangba. "Emi kii se omugọ. Mo mọ pe ojuse ọtọọtọ ni ipo ọba ati ọmọọba jẹ", " O sọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC lọdun 2018. "Iwa aini laakaye ni pe ki ẹnikan ro pe maa si maa se bi mo se n se lọ."
Nigba ti ba tuntun naa ba gori itẹ, ayipada yoo ba aworan ọba to wa lara owo sile si odi keji. Akoko isejọba Charles yoo tun ni afojusun ọtọ
Orilẹede ti Ọba Charles yoo maa jọba le lori gan yapa pupọ ju eyi ti iya rẹ jogun lọ lasiko to gun ori itẹ, ti Ọjọgbọn Bogdanor si nireti pe Ọba tuntun naa yoo maa kan si ilẹ Gẹẹsi to kun fun oniruuru asa ati iyapa.
O wa nireti pe Ọba tuntun yoo duro bii opo kan to wa fun irẹpọ, ti yoo si tiraka lati so awọn ẹya to kere julọ atawọn igun ti ko ni anfaani to yẹ.


Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọgbọn Bogdanor tun nireti pe idile ọba yoo kọ iha to wu ni lori bayii si isẹ ọna, orin ati asa - wọn yoo maa ka iwe Shakespeare dipo kikopa ninu idije fifi ẹsin sare
Amọ Ọlọla Lloyd Dorfman, to n ba ọba Charles sisẹ fun ọpọlọpọ ọdun gẹgẹ bii alakoso ajọ alaanu Ọmọọba naa, ko gba pe idaduro yoo ba ibasepọ rẹ lori awọn ọrọ to nii se pẹlu oju ọjọ ati isẹ ọgbin lai lo oogun igbalode.
"O jẹ ọkunrin to loye, o maa n sisẹ kara, o si nira lati lero pe yoo takete lọjọ to ba gori itẹ." Ọlọla Lloyd lo sọ bẹẹ.


Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ nipa itan Anyhony Seldon gbagbọ pe wọn ti ro Ọba Charles lagbara pẹlu bi wọn se gba pe ootọ ọrọ lo sọ nipa awọn ọrọ kan, fun apẹẹrẹ bii ikilọ nipa ayipada oju ọjọ. Gẹgẹ bii ẹni ti wọn ti fi se ẹlẹya ri, o ti ni ọkan akin. Ọlọla Anthony lo sọ bẹẹ
Nibi ipade ayipada oju ọjọ to waye ni Glasgow lọdun 2021, fun apẹrẹ, awọn eekanlu bii aarẹ Joe Biden, gẹgẹ ni Ọgbẹni Hardman, to ni ipo ti Charles di mu lawujọ agbaye yoo seranwọ fun lati saseyọri ninu ojuse ipo ọba to di mu.
"Oun ati Biden dijọ joko si igun kan, ti Biden si ni 'O si o ni gbogbo eleyi to ti se' O sọ bẹẹ
Iru iwa wo la ri ninu ọba titun?
Awọn to ti mọ salaye pe ninu rẹ, oju maa n ti i, to si maa n joko jẹjẹ. O tun jẹ́ 'eeyan to maa n tara jẹ apejuwe kan.


Oríṣun àwòrán, PA Media

Apẹrẹ wa pe o jẹ ọmọkunrin to maa n saroye pe wọn maa n ya oun sọtọ, tabi yaju si oun
"Wọn maa n ju salubata mọ ni alẹ di afẹmọjumọ tabi ju irọri mọ tabi sare si laarin yara lati lu u tagbara-tagbara," O kọ sinu lẹta kan to fi ransẹ sile pe wn n fiya jẹ oun nilegbe ile igbe.
Aya rẹ Camilla, to di ayaba bayii sapejuwe rẹ bii "Ẹni ti ko ni suuru. O maa n fẹ ki wọn se ohun gbogbo ko to falẹ. Bo se maa n fẹ ki wọn se nnkan niyẹn"
Camilla sọ ninu ifọrọwerọ ori mohunmaworan to se lasiko ọjọ ibi aadọrin ọdun Ọba Charles pe dipo abuda eeyan kan to maa n leju koko ti awọn eeyan n ri, o tun ni abuda awada sise.
"Wọn maa n fi oju eeyan kan to le wo o, eyi to jẹ lootọ. Amọ maa fẹ ki awọn eeyan ri abuda rẹ to dara. O maa n kunlẹ lati bawọn ọmọde sere, o maa n ka iwe Harry Potter fun wọn, ti yoo si maa sọrọ bii awọn eeyan to kopa nibẹ." - Cammila lo sọ bẹẹ.


Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Asiko ti Charles ba n bawọn araalu pade ni ara rẹ maa n balẹ julọ, to si maa n bawọn eeyan se awada lati fa wọn mọra. Boya, o seese ki eyi yipada nigba to di ọba bayii amọ gẹgẹ bii Ọmọọba Wales, o ni iwa agbalagba lai takete.
Fun ẹni to ti le ni aadọrin ọdun, ọba ko ju ara silẹ rara.
Chris Pope, to ti sisẹ ni ibudo idanilẹkọ ti Ọmọọba da silẹ, se apejuwe Ọba tuntun bii ẹni ti ọwọ rẹ di, to si kun fun okun pupọ, to n ru ẹru wuwo.
"Ọrọ awọn iran to n bọ maa n ka lara. Eleyi fi oju han ninu awọn ọpọ isẹ to dawọ le." Ọgbẹni Pope.
Lara awọn isẹ aanu ti Ọmọọba n se ni didaabo bo awọn ohun to jogun ba ati lati daabo bo awọn isẹ ọna isẹnbaye - bakan naa lo n se iwuri fun agbekalẹ awọn ohun ọtun ati iyipada.
"Ohun to maa n jẹ logun ni bi awọn asa ko se ni parun, amọ ko papọ mọ ero to ni ka da ọwọ aago pada sẹyin." Ọgbẹni Pope.
Ọba tuntun naa ko ọpọ nnkan pọ ni oniruuru ẹka to nii se pẹlu wiwa iyipada, to si tun fẹ daabo bo wọn. O si jẹ eeyan kan to n polongo iyipada.


Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba miiran o dabi onila-ẹrẹkẹ pupa kan ti o ti sọkalẹ lati inu aworan ti 18th-Century. Ni awọn igba miiran, o dabi ẹni ti o ni ibanujẹ, ti o binu si bi a ṣe pa awọn agbegbe kọkan ti, opolopo iwa lo jogun lati ọdọ iya rẹ, Ọba Charles tun jogun igbagbọ ẹsin rẹ ati imọlara ti o lagbara.
Hitan Mehta ti ṣiṣẹ pẹlu rẹ lati igba ti o ṣe iranlọwọ lati ṣe idasile British Asia Trust ni ọdun 2007
O jẹ eniti o lawo . Mo ro pe awọn eniyan ko mo gbedeke bi o ṣe nifesi ṣi. Nigbagbogbo o ma n sọrọ nipa iru aiye ti yoo fi sile fun awọn ọmọ ọmọ rẹ.
Eyi le tumọ si awọn ipe si iṣẹ. "Opo igba ni oo ma n pe mi, ole jẹ aago mẹsan ni alẹ,ọjọ Jimọh kan mo gba ipe kan lati ọdọ rẹ pe: 'Mo ṣẹṣẹ gbọ nipa awọn isele omiyale ni Pakistan. Kini a nṣe sii?'
Omo Oba Harry so wi pe baba ohun " jẹ ọkunrin ti o mu ise ni okunkundun leyin ti o ba jeun ale tan, yoo lọ si yara ise re,lati se ise ti yoo si sun loo lori tabili rẹ.


Oríṣun àwòrán, PA Media

Charles Philip Arthur George ni wọn bi ni aafin Buckingham lọjọ Kẹrinla osu Kọkanla ọdun 1948. Nigba tillesẹ agbohunsafẹfẹ BBC kede ibi rẹ, kii se pe tori pe Ọbabinrin bi ọmọkunrin kan ni amọ tori pe iya rẹ 'bi Ọmọọba layọ'. Lẹyin ọdun mẹrin lẹyin eyi, o di arole ọba.
"Mo ba ara mi ti wọn ti bi mi sinu iru ipo yii. Mo si ti se ipinnu lati se amulo rẹ bo se yẹ. Ki n si se ohunkohun to ba yẹ lati seranwọ." Charles lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan to se lọdun 2005.
Oun ni Baba isalẹ tabi aarẹ fawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ to le ni irinwo, lọdun 1976 lo se idasilẹ ẹgbẹ alaanu tara tiẹ, the Prince's Trust, to si n lo awọn owo ifẹyinti rẹ lẹnu isẹ ologun oju omi lati gbọ bukata rẹ.
Ajọ alaanu yi ti seranwọ fun awọn ọdọ bii ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun to wa lati idile talaka ni orilede naa, eyi to fun ni oye nipa ọpọ isoro to wa ni awujọ
Awọn afojusun rẹ fun ajọ alaanu Prince's Trust lati nawọ de awọn ẹka to pe ni " eyi to le julọ lati nawọ de lawujọ" ni ko saseyọri
"Ileesẹ asoju ni oun ko ro pe ero to dara ni. O si nira lati jẹ ko dide nilẹ." O sọ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC lọdun 2018.
Isẹ rẹ lo ti mu ariwisi wa pe o n da si ọrọ oselu, to si tun n toju bọ isejọba lati ipasẹ kikọ awọn iwe asiri ti wọn pe ni "black spider memos". Wọn mu orukọ naa jade lati ara ọna ti Charles n gba kọwe to da bi ti alantakun. Eyi si jẹ awọn lẹta asiri lati ọdọ Charles si awọn minisita ijọba lati ọdun 2004 siwaju.
Awọn lẹta asiri yii lo n beere ilana ijọba lori awọn ọrọ to se koko bii eto ọgbin, aato ilu nlanla, aworan ile kikọ,eto ẹkọ ati ọna lati daabo bo ẹja Patagonian toothfish.


Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita tẹlẹri kan to ri iriri bi Charles se maa n dirẹbẹ ni oun ko fi bẹẹ ri pe Charles kii saba durp le eeyan lori lati gba ohunkohun sugbọn Ọba tuntun naa jẹ ẹnikan ti o durp lori awọn ohun to ba gbagbọ ninu ara rẹ.
O ri i bi eniti o de pẹlu awọn iwoye ti a ti ṣeto silẹ ti o fẹ lati lepa, ju ki o wa ṣe ariyanjiyan lori ọrọ kankan lọ .
Ti a ba ranti ifọrọwanilẹnuwo kan ni ọdun 2006, Charles sọ wi pe ti ohun ba da si awọn ọrọ ti o se pataki, inu ohun maa n dun si, Charles sọ pe: "nigba yen ohun ko lero wi pe oro ohun le bori ninu idojukọ yẹn.
"Ti o ba ṣe ohunkohun rara, wọn yoo sọrọ, Ti o ba gbiyanju lati ṣe nkan iranlọwọ, wọn yoo tun ri wii.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan, o sọ pe ohun yago fun eto oṣelu, ṣugbọn o nira fun oun lati mase sọrọ lori "awọn ipo ti awon eniyan n gbe".
Minisita tẹlẹ fun ọrọ osisẹ, Chris Mullin ṣapejuwe ninu awọn iwe akosile rẹ, ipade ohun ati Charles lori igbaradi re lati gbena woju awon oloselu ati ona lati lana funa won odo ti won fi owo ola gba loju.
Chris ni Charles je okunrin kan ti o setan lati duro ti ohun ti o gbagbo tokan tokan.


Oríṣun àwòrán, Chris Jackson / Clarence House

Iru atilẹyin wo ni Ọba Charles yoo ri latọdọ araalu bi ijọba rẹ se bẹrẹ?
"Ohun kan ti o yio je iyalenu ju ni bi ijọba oba yoo se ayafi ti o ba ṣe akiyesi iwuwasi awon eniyan. Tori wi pe,ti awọn eniyan ko ba fẹ, wọn ko ni ni, gege bi oro Charles.
Gẹgẹbi iwadii ti YouGov ṣe ni Oṣu Kejila ọdun 2021, o ti n ni okiki,nitori fẹrẹ to ida meji ninu ida mẹta eniyan n fi oju ti o dara woo.
Ṣugbọn awọn akojopo ero aralu ti fihan nigbagbogbo pe ko ni okiki to iya rẹ Queen Elizabeth II ati ọmọ rẹ Omooba William, nitorinaa ipin awon aralu ti o ni lati faa mora po,ni pataki julo laarin awon odo.
Victoria Murphy sọ pe eyi ni se pelu awọn ifihan aibanujẹ ti Charles ninu awọn fiimu nipa ibasepo rẹ pẹlu iyawo re akọkọ, Diana, Ọmọ-binrin ọba ti Wales, ti o ku ninu jamba ọkọ ayọkẹlẹ kan ni Oṣu Kẹjọ ọdun 1997.
Arabirin Murphy sọ pe "Ohun ti o jẹ iyanilenu gaan ni bi Diana ṣe n tẹsiwaju lati tan yika idile ori Ade.
Bi Charles ti sunmọ itẹ naa, igbiyanju ti wa lati yi oju-iwoye ti gbogbo eniyan pada, Ọjọgbọn Pauline Maclaran ti Ile-iṣẹ fun Ikẹkọ ti Ijọba ni Royal Holloway, University ti ilu London sọ wi pe.
Lati se safihan rẹ lori awọn mohunmaworan alawada bii Spitting image ,won ti gbe si ipo ti o lola,pelu ogbon nipa ayika gege bi ojogbon Maclaran ti so.
Awon ife awon ara ilule ma n je okan ti o ga julo nigbagbogbo,ati pe gege bi olori idile Oba yoo ni lati koju awon iroyin nipa Omooba Harry ati meghan,Omooba birin ni Sussex,ati awon ibasepo won pelu idile Oba.


Oríṣun àwòrán, PA Media

Nibiti awọn itan idile ọba ti bẹrẹ si yipo mo ti awon gbaju gbaja ilu maaka olokiki eyiti ki se ipo re.
Ọba Charles dojukọ awọn ipinnu ẹbi ti o lagbara , gẹgẹbi ipo Omooba Andrew, lẹhin adehun ipinnu ti o tẹle awọn esun ibalopo ti Virginia Giuffre.
Ni ita UK, ipenija pataki kan yoo jẹ lati tun ṣe alaye ibasepo igbalode diẹ sii pẹlu orilede ti o wa ninu ajo commonwealth. Gẹgẹbi ori tuntun rẹ, bawo ni awọn abẹwo rẹ si awọn orilẹ-ede ti o wa ninu ajo common wealth ṣe lebori awon oro ti o jomo owo eru ati imunisi.
Oba Charles ti di olori orilede merinla ,pelu UK naa. Diẹ ninu awọn wọnyi le fẹ lati di ilu olominira, lakoko ti o wa labe orilede ti o wa ninu ajo common wealth, ati pe Ọba Charles ti jẹ ki o han gbangba pe o ti ṣetan fun awọn ibaraẹnisọrọ ti o lorin nipa iyipada titun.
Awọn ipinnu ti a ti ṣe tẹlẹ ti o ti mu ki ijọba titun rẹ dara. Inu re gbodo dun nigbati iya rẹ gba lati sọ peki Camilla ki o lo akọle olori, dipo Ọmọ-obabinrin.
Camilla yoo se atilẹyin pataki fun bi o ṣe bẹrẹ ọkan ninu awọn ise ti o ga julọ ni agbaye ni ọjọ-ori ti ọpọlọpọ eniyan yoo ti fẹyìntì.
Ni akoko yii, ti gbogbo ayẹyẹ ifobaje, ti nduro niwaju.
Fun Ọba Charles, akoko re ti bere.
















