Sex: Àwọn onímọ̀ ìjínlẹ́ ṣàlàyé ohun tó lè fa ikú òjijì lásìkò ìbálòpọ̀

Oríṣun àwòrán, malayalamemagazine.com
Ibalopọ ladun pupọ, o si jẹ ohun ti ọkunrin ati obinrin maa n gbadun lọpọ igba.
Ṣugbọn lọpọ igba naa ni awọn to n ni ibalopọ ọhun le ko sinu ewu iku ojiji, tabi ki awọn mejeji lẹpọ, tabi se aisan.
Ọkunrin le ku sori obinrin, bẹẹ si ni o ṣeeṣe ki obinrin ku sabẹ okunrin lasiko ti wọn n gbadun ara wọn pẹlu ibalopọ, eyi to maa n ya ọpọ eeyan lẹnu.
- Ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram 6,000 ti jọ́wọ̀ ara wọn fún ìjọba Naijiria
- Wo obìnrin tó ní ojú ara méjì, ilé ọmọ méjì àti ẹsẹ̀ mẹ́rin
- Wo àṣírí márùn-ún tí obìnrin kò gbọdọ̀ sọ fún ọkọ rẹ̀
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
- Gbanjo! $500 ni tíkẹ́ẹ̀tì ìjọba ọ̀run, ẹ bò ó wìtìwìtì - Pásítọ̀
- Àlùfáà tó wọ gàù nítorí pé ó fẹnuko akẹ́kọ̀ọ́bìnrin mẹ́ta lẹ́nu tọrọ àforíjì
- ''Pásítọ̀ ní kí n gbé ọwọ́ lé ǹkan ọkùnrin ọ̀un, ní ejò dúdú bá jádé...''
- Wo àwọn nǹkan tí o kò mọ̀ nípa 'Church of Satan'
Oniruru iroyin lo ti jade pe awọn eeyan kan ku lori ibalopọ, eyii to jẹ kayeefi ati ara meeriri fun ọpọ eeyan.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe iṣẹ aye ni, ni awọn mii maa n di ẹbi irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ru eyikeyi ninu takọ-tabo naa, paapaa awọn to n ni ibalopọ lẹyin ọkọ tabi iyawo wọn.
Ọpọ eeyan miran si lo maa n fi oju asasi wo iru iru isẹlẹ yii lasiko to ba waye, ti kii si jẹ ootọ nigba miran.
Amọ awọn onimọ ijinlẹ isegun oyinbo ti ṣalaye ohun to le mu ki eeyan gbẹmi mi lasiko ibalopọ, yala ọkunrin tabi obinrin.
Awọn ohun mẹ́rin wọnyi le mu ki eeyan ku lasiko ibalopọ si ree:
1. Aṣilo oogun:
Ọpọ igba ni awọn ọkunrin maa n lo agbo ibilẹ ki wọn le ni okun daadaa lasiko ibalopọ.
Awọn mii ẹwẹ a maa da agbo ibilẹ mọ ọti oyinbo pẹlu igbagbọ pe yoo le ṣiṣẹ daada ninu agọ ara wọn alti fi pa itu meje sara obinrin.
Nigba mii ẹwẹ, awọn ọkunrin kan maa n mu siga, igbo, to fi mọ oniruru oogun ti wọn n ta, lati le ṣe afikun okun wọn lori obinrin.
Ṣugbọn ohun ti ko ye wọn ni pe, pupọ ninu awọn oogun naa lo ni eroja ti wọn n pe ni "Nitrate" ninu, eyi to le fa ẹjẹ riru, to si le yọri si iku ojiji.
Gbogbo ẹ gbogbo ẹ, igbesẹ naa ko sẹyin iyi ti wọn fẹ gba lọdọ obinrin ti wọn n ba ni ibalopọ ọhun.
2. Aisan ọkan:
Gbogbo aisan to jẹ mọ ọkan lo lewu ninu, kii si ṣe ohun to yẹ ki eeyan fi ọwọ yẹpẹrẹ mu.
Ẹni to ba ni aisan ọkan tẹlẹ le dakẹ lasiko ibalopọ nitori ọkan naa yoo maa ṣiṣẹ ju be ṣe yẹ lasiko ibalopọ ọhun.
Lara awọn ohun to maa n fa aisan ọkan, paapaa fun awọn obinrin ti ọjọ ori wọn ti le ni marundinlọgọta atawọn okunrin ti ọjọ ori wọn ti le ni marundinlaadọta ni ẹjẹ riru, siga mimu, aisan itọ ṣuga, ara sisan ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ohun kan gboogi to tun maa n fa aisan ọkan ni wahala aṣeju ti wọn n pe ni "Stress" lede Gẹẹsi.
3. Magun:
Gẹgẹ bii igbagbọ Yoruba, magun jẹ oogun kan ti wọn maa n fi sara obinrin ti oju rẹ ko ba gbe ibikan, lati kọ irufẹ obinrin bẹẹ lọgbọn.
Wọn tun maa n lo magun lati fiya jẹ okunrin to ba n ni ibalopọ pẹlu iyawo oniyawo.
Oriṣiri magun lo wa, lara rẹ ni magun mamuomi, magun matakiti, magun ma fotiti, magun majẹla ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Fun irufẹ awọn magun bayii, ti ọkunrin to lu magun ọhun ba ti jẹ eewọ rẹ, yoo jade laye dandan ni.
Igbagbọ Yoruba ni pe ọrun lala ni okunrin to ba lu magun, yoo si lọ ṣalaye ara rẹ fun Eledumare.
- Wo oríṣiríṣi ìgbádun ibálòpọ̀ láwọn orílẹ̀èdè mìíràn
- Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìbálọ̀pọ̀ pẹ̀lú aya tàbí ọkọ rẹ lè jẹ́ kí o dàbí ọmọdé?
- Bó o bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tó o lè kó lójú ara rẹ
- Ẹ̀mi arákùnrin yìí kò gbé e, ó bá aláṣẹ́wò lò dórí ìgbà ìkéje ló bá ré sálákeji
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
4. Ifipabanilopọ:
Oniruru iroyin lo ti wa lode nipa awọn obinrin to n dakẹ sabẹ okunrin lasiko ti wọn ba fi tipa ba wọn lopọ, eyi ti ko ti ọkan obinrin naa wa.
Iru iku bayii wọpọ laarin awọn obinrin ti wọn ba fi agidi ba lopọ.
Irufẹ iku bẹẹ tun wọpọ laarin awọn ti ọjọ ori wọn ko tii nnkan, ṣugbọn ti wọn fi ipa ba lopọ bakan naa, paapaa awọn ọmọdebinrin.
Nigba miran ẹwẹ, ti ọkan irufẹ obinrin naa ko ba si nibi ibalopọ ọhun, o ṣeeṣe ko dakẹ sabẹ okunrin to n fi ipa balopọ.





















