Ticket to Heaven: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ Pásítọ̀ tó ń ta tíkẹ́ẹ̀tì sí ìjọba ọ̀run ní $500 èèyàn kan

PAstor ati tikẹẹti goolu

Oríṣun àwòrán, Egypt today

Ara meeriri, mo rí ori olongbo lori atẹ ni iṣẹlẹ kan to waye lorilẹede Zimbabwe laipẹ yii.Pásítọ̀ kan àti aya rẹ ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ pe wọn n gba awọn eeyan lati wa ra tíkẹ́ẹ̀tì sijọba ọrun ni ẹẹdẹgbẹta dọla.Pásítọ̀ Tito Wats lo sọ fun ẹgbẹlẹgbẹ ọmọlẹyin rẹ pe Jesu lo fun oun ni awọn tíkẹ́ẹ̀tì naa, ti wọn yoo lo wọ ọrun rere.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ko kan mi ohun tawọn eeyan tabi ọlọpaa n sọ nipa mi, wọn n ṣe inunibini si mi ni tori pe mo n ṣiṣẹ Ọlọrun.Jesu funra rẹ lo yọju si mi, to si ko awọn tíkẹ́ẹ̀tì naa le oun lọwọ, ti wọn jẹ kikida wura.

Àkọlé fídíò, Ṣé o lè gbé orí rẹ lọ sọ́dọ̀ fárífárí alábẹ kó dán bí àwọn tó ní àwọn kò lè lo "clipper láéláé yìí?

O ni ki n ta wọn fun awọn eeyan to ba n fẹ igbala."Iroyin naa ni ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan lo n fi ẹhonu han tori bi wọn ṣe mu si ahamọ, wọn ni ki ọlọpaa fi silẹ ni.Pásítọ̀ naa ni wọn lo sọ pe goolu pọnbele ni wọn fi ṣe tíkẹ́ẹ̀tì naa, eyi ti yoo pese aaye nijoba ọrun fun ẹnikẹni to ba ni lọwọ." N ko fẹ mọ ohun ti awọn ọlọpaa n sọ. Goolu pọnbele ni awọn tikẹẹti naa, kii se eyi ti mo ge funra mi, ti mo si fi omi goolu pa lara.

Jesu funra rẹ lo fun mi lẹyin KFC, to si ni ki n lọ ta lati ri owo gba aaye to tobi si. Mo si ti pade ajeji kan to n jẹ Stevie.

O ti wa seleri pe ti mo ba le ko awọn owo naa pap, oun yoo fi baalu kekere rẹ gbe emi ati iyawo mi lọ si aye miran to jẹ kikida eroja Cocaine nikan lo wa nibẹ.

Àkọlé fídíò, BBC Yoruba pada lọ ṣabẹwo si ọja Bode nibi ti ọkọ to kun fọọ fun afẹfẹ gaasi ti dede sina wọ inu ọja to si pa awọn kan.

Ẹ le fin gbogbo Cocaine to wa nibẹ tẹba fẹ, ọfẹ ni. Ẹ wa ran alaisẹ ni ẹwọn, kẹ wa ri nnkan ti yoo sẹlẹ.

O yẹ kẹ lọ mu Jesu naa nitori oun lo fun mi ni awọn tikẹẹti onigoolu ọhun lati ta wọn. Mo si setan lati fa Jesu silẹ pẹlu."

Lara awọn nnkan ti awọn ọlọpaa ba ninu ile wọn ni ẹgbẹrun mẹwa dọla owo beba, awọn ọpa ati ọmọ Anta.