Southern Governors forum: Ẹgbẹ́ Arewa àtàwọn àgbààgbà Àríwá tako pínpín ipò ààrẹ ní Nàìjíríà

Gomina

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ẹgbẹ Arewa Youth Consultative Forum ati ẹgbẹ awọn agbaagba Ariwa, Northern Elders Forum ti kede pe awọn ko faramọ ọrọ tawọn gomina ẹkun Guusu sọ pe aarẹ orilẹ-ede Naijiria gbọdọ wa lati ẹkun naa.

Aarẹ ẹgbẹ AYCF, Yerima Shettima ati agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn agbaagba, NEF Hakeem Baba Ahmed ko sọrọ ninu ohun tawọn gomina Guusu sọ.

Aarẹ AYCF Shettima ṣalaye pe lati ọdun 1999 ti Naijiria ti pada sí ijọba awaarawa lawọn ẹgbẹ oṣelu ti n pin ipo aarẹ laarin ẹkun Ariwa ati Guusu.

Amọ, Shettima ni eto pinpin ipo aarẹ laarin Ariwa ati Guusu daru lọdun 2011 nigba ti aarẹ ana, Goodluck Jonathan to gori aleefa leyin ti Aarẹ Umaru Musa Yar'adua ku tan.

Shettima ni dipo ki aarẹ sí wa lati ẹkun Ariwa lẹyin iku Yar'adua, niṣe ni Jonathan dije ninu ibo aarẹ lọdun 2011 nibi ti o sí ti jawe Olubori.

"A ko le jẹ ki ẹnikẹni dunkooko mọ wa ni Oke Oya tabi ki wọn ro pe awọn eeyan ẹkun Ariwa yoo jọwọ ipo aarẹ fún wọn nitori ariwo ti wọn n pa.

Ijọba awaarawa ni a wa, ki onikaluku dije ninu eto idibo gbogbogboo ọdun 2023," Shettima lo sọ bẹẹ.

Ninu ọrọ tirẹ, agbẹnusọ fún ẹgbẹ NEF, Baba Ahmed sọ pe awọn eeyan Ariwa ko ni ki aarẹ ma wa lati ẹkun Guusu ṣugbọn ohun tawọn ko fẹ ni pe ki awọn eeyan perete joko nibi kan ki wọn maa sọ pe aarẹ Naijiria gbọdọ wa lati ẹkun Guusu.

"Awa eeyan Ariwa ko ṣẹṣẹ maa dibo fun Aarẹ lati ẹkun Guusu.

Awa ni a dibo fun Abiola, a dibo fun Obasanjo, bakan naa ni a dibo fun Jonathan.

Nitori naa, ẹnikẹni ko le sọ fun wa pé a gbọdọ dibo ni tipa tipa fún oludije ipo aarẹ lati ẹkun Guusu tabi ki wọn ni ẹ ko gbọdọ dibo fun elomiran yatọ si oludije lati ẹkun Guusu.

Ẹtọ kan naa ni awon eayan Ariwa ni pẹlu awọn ara Guusu," Baba Ahmed lo ṣalaye bẹẹ.

Ẹkùn Gúúsù Nàìjíríà ni ààrẹ gbọdọ̀ ti wá lọ́dún 2023 - Àwọn Gómìnà Gúúsù yarí

Awọn gomina ẹkun guusu Naijiria

Awọn gomina apa Guusu orilẹ-ede Naijiria fẹnuko lori awọn koko kan lẹyin ti wọn ṣepade pọ tan niluu Eko lọjọ Aje, lori awọn ọrọ to n lọ ní Naijiria.

Ninu atẹjade ti alaga awọn gomina Guusu, Arakunrin Rotimi Akeredolu fi sita, awọn gomina ọhun ṣalaye pe oṣelu aiṣegbe fẹnikan lawọn fọwọ sí.

Eleyii lo jẹ ki wọn fẹnuko pe aarẹ orilẹ-ede Naijiria gbọdọ wa lati apa Guusu nitori o yẹ ki àwọn eeyan Ariwa ati Guusu máa pin ipo aarẹ laarin ẹkun mejeeji ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn gomina Guusu tun kede pe iṣọkan Naijiria, ododo, itẹsiwaju ati gbigbe pọ ni alaafia awọn ọmọ Naijiria lo jẹ awọn logun.

Àkọlé fídíò, 'Oko ni mo wà lọ́nà "Express" Ilesha tí àwọn agbébọn yìnbọn bá ẹnu mi tí mò fi dà báyìí'

Awọn koko miran tawọn gomina tun fẹnu ko le lori nibi ipade wọn:

  • Ẹgbẹ awọn gomina apa Guusu Naijiria tun ṣe agbeyẹwo eto abo to mẹhẹ ni Naijiria, wọn si lo akoko naa lati pe fún idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ.
  • Bakan naa ni won tun fẹnuko pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo gbọdọ maa fi to awọn leti ohunkohun ti wọn ba fẹ ṣe nipinlẹ awọn.
  • Awọn gomina naa mu ọjọ kinni oṣu kẹsan an ọdun 2021 yii gẹgẹ bi ọjọ ti wọn yoo ṣe agbekalẹ ofin ti yoo tako dida ẹran jeko ni gbangba lẹkun Guusu.
  • Wọn tún fẹnuko pe owo ti ijọba apapọ ya sọtọ ninu apo ijọba fún awọn ọlọpaa lori eto abo gbọdọ jẹ pínpín laarin ijọba apapọ at'awọn ijọba ipinlẹ, ki wọn sì jọ gbogun ti iṣoro eto abo to mẹhẹ.
  • Awọn gomina Guusu tun gboṣuba fún ile asofin agba niluu Abuja lori bi wọn ti ṣe agbekalẹ ofin iṣakoso ileeṣẹ epo rọbi ati ere ori epo.
  • Ṣùgbọn wọn tako ida mẹta ere ori epo ti ofin naa ni yoo maa lọ si awọn agbegbe ti Naijiria ti n wa epo.
  • Bakan naa lawọn gomina Guusu tun tako ilana ti ofin naa la kalẹ lori ẹni to ni ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPC .
  • Lori erongba rẹ lati ri pe ijọba awaarawa f'ẹsẹ ranlẹ ni Naijiria, awọn gomina Guusu tako bi wọn ṣe yọ ikede esi idibo lori kọmputa kuro ninu òfin idibo.
  • Awọn gomina ọhun tun fẹnuko yan ipinlẹ Eko gẹgẹ bí olú ileeṣẹ fawọn gomina apa Guusu Naijiria.