Motilola Adekunle: Èmi àti ọkọ́ mi ti gbà láti yàgò fún ara wa

Motilola ati Oko rẹ

Oríṣun àwòrán, @motilola/instagram

O tun ti n sẹlẹ bayii o lagbo osere tiata Yoruba, ẹni ti ọrọ yii si sẹlẹ si kii se ẹni ti ẹnu maa n kun lọpọ igba, nitori eeyan jẹjẹ ni.

Idi si ree ti o se n ya ọpọ eeyan lẹnu ohun to le fa a, ti iru gbajumọ osere tiata naa yoo se bọ si agbami ori alejujara fun idajọ araalu lori igbeyawo rẹ.

Ẹni ta n sọrọ rẹ ni Motilola Adekunle, ti ọpọ eeyan mọ si ara awọn oju to gbajumọ ninu awọn fiimu Yoruba.

Lọjọ Aje ni Motilola bọ soju opo Instagram rẹ pẹlu aworan oun ati ọkọ rẹ, ti wọn n ti ẹnu bọ ara wọn lẹnu.

Amọ kii se ọrọ ifẹ lọkọlaya lo mu ki osere binrin naa fi aworan oun ati ọkọ rẹ yii han, ohun to fẹ kede fun araye ni pe opin ti de ba igbeyawo awọn.

Àkọlé fídíò, Gbajugbaja oṣere tiata, Motilọla Adekunle ló fi aya gbangba rẹ han lori èto ṣé o láyà.

Gẹgẹ bi alaye ti Motilola se, o ni lootọ ni kii saba wọpọ pe ki oun pin iru oiroyin bayii fun awọn eeyan nitori oun wa lara awọn eeyan to gbagbọ ninu igbeyawo.

Amọ o ni igbagbọ ti oun ni pe o yẹ kii eeyan maa na tan, ko si ko akoyawọ lai fi aaye gba ahesọ ọrọ tabi gbọyi-sọyi lo mu ki oun se bẹẹ.

Motilola ati Oko rẹ

Oríṣun àwòrán, @motilola/instagram

"Lẹyin ọpọ ọdun ta ti se igbeyawo, a ti wa fẹnu ọrọ jona, to si ti ye wa bayii pe o dara ki awa mejeeji wa lọtọọtọ.

Mo fẹ sẹ lori awọn ahesọ ọrọ to le jẹ jade nipa iyapa wa. Igbeyawo wa ko kan saseyege ni. Ko si irunu tabi ibinu sira ẹni ninu rẹ.Pe o nira? Bẹẹni amọ ipinnu to dara lati se ni akoko yii ree."

Motilola tun wa tẹnu mọ pe obi kọkọ ni awọn, ti Ọba oke si fi ọmọ meji ta awọn lọrẹ, ti awọn si n bẹbẹ pe ki araye bo awọn ni asiri nipa bibọwọ fun kọlọfin awọn lakoko yii.

O ni bonkẹlẹ ni awọn n se ọrọ igbeyawo awọn saaju akoko yii, ti ireti si wa pe bi awọn se n pinya yii, awọn yoo tẹsiwaju lati se bẹẹ."Mo dupẹ fun agbọye yin , mo si tun n bẹbẹ fun adura yin ni akoko yii.

Maa mọ riri yin ti ẹ ko ba pe mi lori aago amọ maa dahun si awọn atẹjisẹ tẹ ba fi ransẹ bi agbara mi ba se ka.

Ẹ jọwọ, ẹ ni oye nipa bi isẹlẹ yii ti gba ẹlẹgẹ to...Ọlọrun yoo bu kun yin."