Baba Ijesha €50,000 GoFundMe: Àwọn olólùfẹ́ Baba Ìjèsà gbé ìgbà Gofund Me láti fí sàn owó tí yóò fí ṣé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha/Twitter
Awọn ololufẹ oṣere tiata Yoruba nii Baba Ijesha ti bẹrẹ si ni da owo jọ lati le fi san owo ti wọn yoo fi ṣẹjọ rẹ.
Ẹsun aṣemaṣe pẹlu ọmọde ni ẹjọ ti wọn fi kan labẹ ofin ipinlẹ Eko.
Lọwọlọwọ bayi, Baba Ijesha ti gba beeli niwaju adajọ ṣugbọn yoo nilo owo ti yoo fi sẹjọ.
Loju opo Go Fund Me, akọle ipe owo dida fun Baba Ijesha ni wọn pe ni 'Help Olanrewaju Omiyinka with Legal Costs'
Ẹni to si ṣe agbatẹru ipolongo yi ni arakunrin Oladele Matti ti a gbọ pe orileede Ireland lo n gbe.
Matti jẹ oludari ere tiata ti a si ri loju opo r ni Instagram pe o jẹ wọlewọde pẹlu Yomi Fabiyi.

Oríṣun àwòrán, Instagram/OladeleMatti
Ninu ipolongo yi, wọn lawọn nilo €50,000,ṣugbọn iye ti awọn eeyan da ko ti kọja €20 ti wọn ti ri gba.
Nigba ti Baba Ijesha wa sile ẹjọ lori ọrọ beeli rẹ,awọn agbẹjọro agba meji lo tẹle wa ti awọn agbẹjọro mẹtadinlogun mii si kọwọrin pẹlu wọn.














