Sunday Igboho: Oluwo tí Iwo ní èébú ni wọ́n bú àwọn lọ́balọ́ba nígbá tí Igboho bẹ̀rẹ̀ ìjìjàgbara.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oluwo of iwo land
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba AbdulRasheed Akanbi ti ni o ni idi ti awọn lọbalọba fi dakẹ lẹyin ikọlu si ile ajijagbara ẹya Yoruba, Sunday Igboho.
Ọba Akanbi ni kii ṣe wi pe awọn kẹyin si Sunday Igboho nitori ọmọ Yoruba ni, amọ ko gbọ ọrọ si awọn lọbalọlọba lẹnu.
Oluwo ni nigba ti ijijagbara fun Yoruba Nation naa bẹrẹ ni oun ti bẹrẹ si ni lọgun rẹ pe, kii ṣe ọna to yẹ ki wọn gbe e gba ni wọn n gba beere fun idaduro ilẹ Yoruba.
- Àmúṣẹ Yoruba Nation wà lára ǹkan tó gbé mi lọ síbi ìsìnkú T.B Joshua
- Àwọn olólùfẹ́ Baba Ìjèsà gbé ìgbà Gofund Me láti ràn án lọ́wọ́ sàn owó tí yóò fí ṣé ẹjọ́
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
- Ìkọlù DSS sílé Sunday Igboho tàpá sófin, ìwà ìjọba ológun ni - Falana
- Ẹ̀yin àgbà Yorùbá, ẹ lọ gba Sunday Igboho lọ́wọ́ ẹ̀sùn tíjọba fi kàn-án - YWG
- Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
Ninu ọrọ tirẹ, Oluwo ni o yẹ ki awọn ajijagbara naa kọkọ wa ba awọn lọbalọba sọrọ lori nkan ti wọn fẹ, ki awọn lọbalọba gbee yẹwo boya nkan to ṣeeṣe ni, ati ọna ti wọn yoo gbee gba.
Amọ, o ni awọn ajijagbara ti Sunday Igboho ṣe adari fun yii n bẹrẹ si ni bu awọn ni, ti awọn araalu naa si n ti wọn lẹyin.
''Wọn gbagbe pe ọba ba lori ohun gbogbo ni, ijọba si laṣẹ lati da abo bo awọn eniyan''.
''Ijọba ko le maa woran ki nkan to ṣẹlẹ lasiko ifẹhọnuhan tako ijiya awọn araalu lọwọ ọlọpaa, ENDSARS tun ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria mọ''.
O ni nitori naa iṣẹ ijọba ni wọn n ṣe lati rii pe ko si wahala ni agbegbe kankan.'
''Okun kii ho ruru, ka waa ruru ni ọrọ yii jẹ, a kii ba ijọba ja, a ma n dunadura pẹlu ijọba ni.''

Oríṣun àwòrán, Instagram/oluwo of iwo land
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba AbdulRasheed Akanbi fi kun un wipe aanu awọn ti iṣẹlẹ naa mu ẹmi wọn lọ ṣe oun. nitori ara o rọ okun, ara o rọ adiyẹ ni ọrọ Sunday Igboho.
Ọba Akanbi ni ọmọ awọn naa ni Sunday Igboho nitori ọmọ ko lee buru ka fi fun ẹkun pa jẹ nitori baba ni oun jẹ fun Baba Igboho.
Oluwo wa gbadura fun un pe ki Ọlọrun yọ ọ kuro ninu wahala to ko ara rẹ si.
















