Gani Adams on Sunday Igboho: Aláìmọ̀ làwọn tó ní mo lọ Synagogue lọ dárò T.B Joshua dípo lílọ ìwọ́de Yoruba Nation

Oríṣun àwòrán, Iba Gani Adams/Facebook
"Aláìmọ̀ làwọn tó ní mo lọ Synagogue lọ dárò T.B Joshua dípo lílọ ìwọ́de Yoruba Nation".
Aarẹ Ọna Kakanfo Yoruba, Gani Adams ti tutọ soke foju gba lori bawọn kan ṣe ni o pataki isinku T.B Joshua ju kikopa ninu iwọde Yoruba Nation.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba lo ti tu kẹkẹ ọrọ yi silẹ.
Iba sọ pe iru ibeere yi ko yẹ ko tiẹ waye rara ati pe awọn to n sọ ọrọ naa jẹ alaimọkan ni.
O woye pe awọn eeyan ṣe le maa sọ pe ṣe oun ti pe tabi kan si Sunday Igboho lati igba ti ajọ DSS ti ṣe ikọlu si ile rẹ to fi wa di pe ibi akọkọ to lọ to han si gobogo araye ni ibi isinku Wolii T.B Joshua.

- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
- Àwọn alátìlẹyìn Sunday Igboho ṣe ìwọ́de ní Ibadan, wọ́n tọrọ nkan márùn-ún lọ́wọ́ Olubadan
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
- Àwòrán bí ó ṣe ńlọ rèé níbi ìsìnkú TB Joshua lónìí
O ni yatọ si pe oun lọ sibẹ lati lọ ṣe idaro eekan ọmọ ilẹ Yoruba to papoda, ọmọ ilu kanna ni oun ati T.B Joshua jẹ.
Lẹnu ọjọ mẹta yi ni ibeere ti nwaye wi pe ki lo de ti Gani Adams ko ṣe lewaju iwọde ati ipolongo Yoruba Nation ti Sunday Igboho ati awọn miran n ṣe agbatẹru rẹ.
Esi ti Gani Adams a si maa fọ si ibeere yi ni pe Aarẹ Ọna Kakanfo kii ṣadede lọ si ode tabi kopa ninu iwọde.
Adams ti sọ fun BBC ri wi pe ''Ki ni wọn fi ipo Aarẹ Ọna Kakanfo pe? ṣe ti mo ba lọ si iwọde ti awọn ọlọpaa ko mi mọ awọn oluwọde, kini ẹ fẹ maa sọ?''
Gani Adams ṣalaye pe bi oun ti ṣe lọ sibi eto isinku T.B Joshua, anfaani pupọ wa nibẹ tawọn eeyan ko mọ paapa nipa amuṣẹ Yoruba Nation ti wọn n ja fun.
O ni nibi isinku yi, awọn eeyan jankan jankan loun yoo pade nibẹ ti wọn si le ṣatilẹyin fun Yoruba Nation bo ba ya.
''Ṣe ẹ ri ibi isinku ti mo lọ, orisirisi aṣoju orileede ni wọn wa sibẹ. Ninu awọn wọnyi, bo ba di igba taa pade ni awọn ajọ agbaye bi UN, wọn yoo ranti pe a ti jọ sọrọ ri.''
''Nigba taa bi fi sọ fun wọn pe a fẹ idasilẹ Yoruba Republic ko ni jẹ tuntun si wọn nitori a ti jọ pade sọrọ lori rẹ tẹlẹ''
Gani Adams ni kii ṣe pe iwọde tabi ifẹhonuhan naa ko daa lati le polongo idasilẹ Yoruba Nation ṣugbọn ọrọ yi gba ọgbọn ati ooye ti eeyan fii to nkan daada.
O ni gbogbo igbesẹ ti Sunday Igboho n gbe loun mọ si ati pe o ṣe pataki ki awọn ọmọ Yoruba lo orisi ọna lati le ṣamuṣẹ idasilẹ Yoruba Nation ti wọn n ja fun.

















