Sunday Igboho: Ààrẹ̀ Buhari ní iṣẹ́ akínkanjú ní àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe nípa Sunday Igboho, Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti gboriyin fun awọn ẹṣọ alaabo lori aṣeyọri mimu adari ikọ Biafra, Nnamdi Kanu ati ikọlu ti wọn ṣe si ile Sunday Igboho.
Ninu atẹjade ti aarẹ fi lede gba ọwọ agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu lo ti sọ bẹẹ.
Aarẹ Buhari ni awọn ẹṣọ alaabo naa ṣiṣẹ akọni lai si ibẹru, ti wọn si ṣe gbogbo rẹ ni idakọnkọ lai jẹ ki ẹnikẹni mọ nipa rẹ.
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
- Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch
- Mo Bimpe tú àṣírí bí Yomi ṣe ń nàá síí fún ìbalòpọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà
- Ìkọlù DSS sílé Sunday Igboho tàpá sófin, ìwà ìjọba ológun ni - Falana
- Wo ohun tó le gbégi dínà àbádòfin tó wógilé ṣíṣàfihàn afurasí ọ̀daràn l'Eko
- Ìgbeyàwó òṣèrébìnrin mìràn tún forí ṣánpọ́n
- Àwọn olólùfẹ́ Baba Ìjèsà gbé ìgbà Gofund Me láti ràn án lọ́wọ́ sàn owó tí yóò fí ṣé ẹjọ́
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
''A gbọdọ tẹra mọ iru awọn ilana yii lati yọ gbogbo awọn agbebọn to n ji awọn akẹkọọ gbe ni Naijiria, paapaa awọn to n gbe ni ariwa orilẹede Naijiria.''
''Orilẹede Naijiria gbe oriyin fun awọn akọni naa, ti wọn si gboriyin fun iṣẹ ti wọn ṣe''.
Ijọba orilẹede Naijiria ti n woye awọn iwa ọdaran ti ẹgbẹ IPOB ti n ṣe lati ọjọ to ti pe, ti iwadii si fihan wi pe iwa ọdaran ni wọn n hu, ti wọn fi n ri owo ti wọn fi n gbe ikọ IPOB larugẹ.
Bakan naa ni aarẹ Buhari ni iṣe akọni ni bi wọn ṣe yabo ile Sunday Igboho nitori oun pe fun iyapa kuro lorilẹede Naijiria, to si da omi alaafia orilẹede Naijiria ru pẹlu awọn ohun ija oloro ti wọn ba ni ile rẹ.
''Lori irọ ni pe ohun ṣiṣẹ lati da abo bo awọn eniyan rẹ, wahala lo fi n da silẹ ni Naijiria''
- Wo àwọn gbajúmọ̀, òṣèré tó lọ sí ibi ètò ìsìnkú Temitope Joshua
- Odíndi mọ̀lẹ́bí kan jẹ́ oníbalòpọ̀ abo sí abo, wo irú ìpólówó ọjà wọn tó dá wàhálà sílẹ̀
- Kò jọọ́, adájọ wọ́gilé gbígba onídùró Dibu Ojerinde lórí ẹ̀sùn àjẹbánu ₦5.2 bílíọ̀nù ní JAMB
- Yomi Fabiyi, ìtíjú ńlá gbáà lo jẹ́ lórí fíímú ''Oko Iyabo'' tóo gbé jáde - Mercy Aigbe
- Ikú dóró! Lẹ́yìn ogún ọdún lórí ilẹ̀ alààyè, ẹṣin tó ga jùlọ Big Jake jáde láyé
''Awọn ọrọ ẹnu rẹ lati ẹyin wa ti fihan pe ko fẹ rere fun orilẹede Naijiria, eleyii ti o fẹ ba ajọṣepọ Naijiria''.
Aarẹ Buhari wa fikun pe awọn ẹṣọ alaabo gbọdọ ṣe ju ti tẹlẹ lọ lati ri pe awọn to n ji awọn ọmọ ileewe gbe ni ileẹkọ wọn foju wina ofin.















