Lagos Assembly: Wo ìdí tí òfin ilé aṣòfin Eko kò fi le múlẹ̀ lórí ọ́lọ́pàá

Ile asofin ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, LASG

Lọjọ Aje, ọjọ karun un oṣu keje ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko kéde abadofin to wọgile ki awọn ọlọpaa maa ṣafihan awọn afurasi ọdaran lai ti gba idajọ.

Igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Wasiu Eshilokun-Sanni lo dari ijoko ile nigba ti ile ṣe ikede abadofin ọhun.

Lẹyin ti ile buwọlu abadofin naa ni igbakeji olori ile ni ki akọwe ile fi abadofin naa ranṣẹ si Gomina Babajide Sanwo-Olu lati buwọlu ki o le fi òfin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ti gomina ba le buwọluu tan, ofin naa ko ni faye gba awọn ọlọpaa lati ma ṣe afihan awọn afurasi ọdaran mọ niwaju awọn akọroyin.

Ọpọ awọn agbẹjọro lo ti pe fun idaduro asa bi awọn ọlọpaa ṣe maa n ṣafihan awọn afurasi lai ti jẹ pe ileẹjọ ti da wọn lẹbi.

Àkọlé fídíò, BBC Yoruba pada lọ ṣabẹwo si ọja Bode nibi ti ọkọ to kun fọọ fun afẹfẹ gaasi ti dede sina wọ inu ọja to si pa awọn kan.

Wọn ni ohun ti awọn ọlọpaa n ṣe yii tako ẹtọ ọmọniyan awọn ti wọn pe ni afurasi.

Ṣugbọn agbẹjọro Muktar Kolawole Suleiman ṣalaye pe abadofin ti ile igbimọ aṣofin ìpínlẹ̀ Eko ṣẹṣẹ ṣe, le maa mu opin dé ba bi awọn ọlọpaa ṣe maa n ṣafihan awọn afurasi.

Agbẹjọro Suleiman ni ofin ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ba ṣe ko le nipa lori ileeṣẹ ọlọpaa.

"Gomina ipinlẹ tabi ile aṣòfin ipinlẹ ko lagbara lori ileeṣẹ ọlọpaa.

Ti o ba wù awọn ọlọpaa ni wọn le tẹle aṣẹ gomina nipinlẹ ti wọn wa, ti o ba sì wu wọn, wọn le maa tẹle aṣẹ gomina tabi ofin ti ile asofin ipinlẹ ba ṣe.

Idi ni pe iwe ofin Naijiria ko fun awọn gomina laṣẹ lori ọlọpaa.

Aarẹ orileede Naijiria tabi aṣoju rẹ lo le pàṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa," amofin Suleiman lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òkú gbígbẹ́ tí wọ́n ṣì bá oyún nínú rẹ̀?

Agbẹjọro Suleiman ni ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja nikan lo le ṣofin ti yoo de awọn ọlọpaa lawọn ipinlẹ gbogbo.

O ni ileeṣẹ aarẹ ni ọga ọlọpaa nipinlẹ kọọkan n jiyin fun kii ṣe awọn gomina.

Ajafẹtọ agbẹjọro, Femi Falana tiẹ ti gbe ajọ EFCC ati agbẹjọro agba ni Naijiria lọ si ile ẹjọ lori fifi awọn afurasi han ṣáájú igbẹjọ wọn.

Falana ni eyi tapa sofin Naijiria, ati pe o tako ẹsẹ kẹrinlelọgbọn iwe ofin orile-ede Naijiria.