Sunday Igboho: Falana ní ìkọlù DSS sílé Igboho dàbí ìdìtẹ̀ gbàjọba lóru

Femi Falana ati Sunday Igboho

Agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana (SAN) ti bu ẹnu atẹ lu bi ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe kọlu ile ajijagbara, Oloye Sunday Igboho to wa lagbegbe Soka niluu Ibadan.

Nigba to n sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan ileeṣẹ Channels TV, Falana ni igbesẹ ajọ DSS da bí iditẹ-gbajọba to waye lọganjọ oru.

Agbẹjọro agba naa ni ko si ofin Naijiria to faye gba mimu ẹnikẹni ni oru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ikọlu ajọ DSS laago oru sile Igboho jẹ iwa ijọba ologun tawọn ajọ naa jogun ba.

Lai jẹ wí pe eeyan huwa ọdaran loru, kò si ofin to faye gba a, DSS ko l'aṣẹ lati lọ mu ẹnikẹni ni oru.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òkú gbígbẹ́ tí wọ́n ṣì bá oyún nínú rẹ̀?

Ohun to tọ ni ki ajọ ọtẹlẹmuyẹ mu iwe aṣẹ to fún wọn lagbara lati ṣe ayẹwo ile Igboho dani, ki wọn to le wọ ile rẹ.

Amọ, kò si ohun to jọ bẹẹ, DSS ko mu iru iwe bẹẹ jade.

Nisin yii, Igboho ni oun ko ni ibọn nile, ṣugbọn DSS ṣe afihan awọn ibọn AK-47 pe awon ri nile rẹ.

Gbogbo nkan bayii ni ko ba ti lojutuu ti DSS ba ti huwa bi ajọ ọtẹlẹmuyẹ to laju ni," Falana lo ṣalaye bẹẹ.

Agbẹjọro Falana tun sọrọ lori ikede awọn gomina Guusu ọjọ Aje ninu eyi ti wọn ti sọ pe awọn oṣiṣẹ eleto abo gbọdọ maa fi to awọn leti ki wọn to le ṣe ohun kan nipinlẹ awọn.

Àkọlé fídíò, BBC Yoruba pada lọ ṣabẹwo si ọja Bode nibi ti ọkọ to kun fọọ fun afẹfẹ gaasi ti dede sina wọ inu ọja to si pa awọn kan.

Amọ, Falani ni o ti pẹ ju fun wọn lati sọrọ sita ati pe ṣe igba yii laarọ ti arugbo wọn n sunkun oge.

O ni o buru jai pe ọganjọ oru ni wọn ṣe ikọlu sile Igboho, ti wọn si payan níbẹ, ṣugbọn gomina ipinlẹ Oyo ko mọ.

Falana ni "lẹyin bii wakati mejila ni ajọ DSS ṣẹṣẹ sọ pe awọn lawọn wa nidi iṣẹlẹ naa.

Ẹ lọ ṣe ikọlu sile eeyan, ẹ tun pa eayan meji, gomina ipinlẹ naa ko sí mọ nipa rẹ."

Falana ni ọrọ naa ko dun gbọ leti.