Sunday Igboho: Alhaji Fatai ń kírun lọ́wọ́ ni wọ́n ta ní ìbọn, tó sì kú

Alhaji Fatai ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Ọjọbọ ọjọ kinni osu Keje ọdun 2021 ni awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS se ikọlu sile ajijagbara to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Sunday Igboho.

Nibẹ si ni wọn ti jẹwọ pe eeyan meji ni awọn pa ninu ile naa nitori wọn di awọn lọwọ lati sisẹ awọn ninu ile ọhun.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki ti sọ loju opo Facebook rẹ, orukọ ẹni akọkọ ni Saheed Adisa, ti ọpọ eeyan mọ si Adogan.

Adogan yii si ni wọn ti kọkọ gbe oju rẹ sita fun araye lati se idaro iku rẹ bii akọni ọmọ Yoruba to ja fun ominiran iran rẹ.

Ọpọ eeyan si lo ti n naga lati mọ ẹnikeji ti ẹmi rẹ pọ sinu isẹlẹ naa.

Alhaji Fatai

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki/Instagram

Nibayii, Koiki ti wa bọ soju opo Instagram rẹ lati daro eeyan keji to jalaisi nile Igboho lati ọwọ awọn osisẹ DSS.

Oluwarẹ lo pe ni Alhaji Fatai.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ Igboho se wi, Alhaji Fatai yii n kinrun lọwọ ni awọn osisẹ DSS de, ti wọn si ta ni ibọn, eyi to gba ẹmi rẹ.

O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere, ti ọpọ ọmọ Yoruba to da si ọrọ naa si n fi adura sin oku ọrun naa lẹyin.

Àkọlé fídíò, 'Oko ni mo wà lọ́nà "Express" Ilesha tí àwọn agbébọn yìnbọn bá ẹnu mi tí mò fi dà báyìí'