Sunday Igboho: Aago kan ààbọ̀ òru ní àwọn agbébọn gúnlẹ̀ láti sun ilé mi

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajo yajo ti kede pe awọn agbebọn kan ya bo ile ajijagbara fun ilẹ Yoruba, oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho.

Iroyin naa fikun pe se ni iro ibọn n dun lakọ lakọ niwaju ile Sunday Igboho ni oru mọ̀ju ọjọ Aje, ti gbogbo agbegbe Soka, ti ile ajijagbara naa wa, ko si fara rọ̀ laajin oru.

Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, agbẹnusọ fun Igboho lorilẹede Naijiria, Dapo Salami salaye pe deede aago kan oru ni awọn eeyan naa gunlẹ sinu ile naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Salami ni awọn alatilẹyin Sunday Igboho to wa ninu ile pẹlu rẹ gbena woju awọn eeyan to wa se ikọlu naa, ti wọn si le wọn danu.

" A ko le sọ iye eeyan to wa loru mọju lati wa kọlu ile Sunday Igboho amọ wọn pọ, ti a ko si tun mọ iru awọn eeyan to fi oru boju wa.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

A ko mọ boya janduku ni wọn tabi ọmọ ologun sugbọn wọn wa pẹlu ọpọ kẹẹgi pẹtiroolu, o si foju han pe wọn wa lati sun ile mọ Igboho lori ni.

Ọpẹlọpẹ awọn ọmọ ẹyin igboho to tako awọn eeyan yii lati sisẹ laabi wọn, ti wọn si fi ẹsẹ fẹ.

Dapọ Salami wa fi ọwọ gbaya pe ko si ohunkohun to se ajijagbara fun ilẹ Yoruba naa, saka ni ara rẹ da.