Ramadan Fast 2021: Pásítọ̀ pín ounjẹ iṣínu àwẹ̀ fún àwọn Músùlùmí

Ramadan Fast: Pásítọ̀ pí ounjẹ iṣínu àwẹ̀ fún àwọn Músùlùmí

Oríṣun àwòrán, Channels

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Bísọ̀ọ̀bù àgbà nígbà kan rí nílùú Abuja, John Onaiyekan tí pín ounjẹ́ tó lé ni igba fún àwọn músùlùmí bí ẹgbẹ̀rún méjì ní mọ́sálásí Al-Habibiyah ní agbègbè Guzape nìlùú Abuja tíí ṣe olúùlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Lásìkò tí wọ́n péjọ láti ṣinu ààwẹ̀ ní òun àti àwọn onígbàgbọ́ míírà sàbẹ̀wò sí mọ́sálásí náà.

Ilé iṣẹ́ ìròyìn Channels gbé àwọn fótò bí Bísọ̀ọ̀bù àgbà ọ̀ún ṣe ń pín ounjẹ náà fún àwọn mùsùlùmí láti ṣínu.

Ramadan Fast: Pásítọ̀ pí ounjẹ iṣínu àwẹ̀ fún àwọn Músùlùmí

Oríṣun àwòrán, Channels

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ lásìkò tó n pín, ó ṣàlàyé pé Ọlọ́rùn fẹ́ràn kí krìstẹ́nì fi ìfẹ́ hán nítòrí ìfẹ́ ni òun fúnra rẹ̀, àti pé àwọn ń ṣe èyí láti jẹ́ kí àláfíà kó jọba láàárín krìsẹ́ní àti Musulumi.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Imaamu Mọ́sálásí Al- Habibyyah Fuad Adeyemi sọ pé, ǹkan tí adarí krìtẹ́nì ṣe yìí fi hàn pé ẹ̀sìn méjèèjì lé jọ́ jùmọ̀ gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àti ni ìgbé àlàfíà.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ramadan Fast: Pásítọ̀ pí ounjẹ iṣínu àwẹ̀ fún àwọn Músùlùmí

Oríṣun àwòrán, Channels