Pantami resign: Àtẹ̀jádé ìjọba apapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pantami fihàn pé wọ́n ń káànú ìgbésùmọ̀nmí- PDP

Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ní Nàìjíríà, People's Democratic Party (PDP) ni àtẹ̀jáde tí ìjọba Buhari kọ síta lórí mínísítà ètò ìbanisọ̀rọ̀ àti oko-òwò orí ayélujára, Isa Pantami fihàn kò dárá tó.
PDP ni pé ìṣèsí wọ́n fẹ́ràn láti dáàbò bo àwọn olólùfẹ́ ìgbésùmọ̀mí, èyí to fi hàn lójú ilẹ̀ òkèèrè pé ìjọba Nàìjíríà ń fọwọ́ ra ìwà ìgbésùmọ̀mí lórí Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi dúró gìdìgbà lẹ́yìn Pantami t'áráàlú ní kó fipò sílẹ̀
Nínú àtẹ̀jáde mííràn tí akọ̀wé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Kola Ologbodiyan fọwọ́ sí sọ pé "ìjákulẹ̀ ló jẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà pé ìjọba àpapọ̀ lé máa ṣe àwáwí láti gbè ti àwọn agbésùmọ̀mí lẹ́yìn.
àti fífí ọwọ́ sọ̀yà pé ẹ̀yìn Isa Pantami tí ó fẹ̀nu rẹ̀ jẹ́wọ́ pé gbágbáágbá ni òun wà lẹ́yìn àwọn ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí bí Al-Qaida àti Taliban ni awọn wa."
- Báwo ní Nàíjíríà ṣe ná $30m fún ààbò akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yin ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́ Chibok?
- "Ajínigbé ní tí a kò bá tètè sanwó, àwọn yóò gbé ọmọ mi sálọ, tí yóò sì kọ́ ìbọn yínyìn"
- Ohun mẹ́rin tó ṣẹ̀lẹ̀ ní Nàíjíríà nígbà tí Buhari kò sí nílé
- Kọmíṣọ́nnà Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ gbọ́dọ̀ fí ipò sílẹ̀ nítórí ó kùnà láti dẹ́kun ìpàníyàn ní Ibarapa - Gani Adams
PDP ni: "Ó bani lọ́kàn jẹ́ pé, ìgbésẹ̀ ìjọba Buhari yìí tún bu omi tútù sí ọ̀pọ lọ́kàn tó sì fi hàn pé, ọ̀dàlẹ̀ ni ìjọba Buhari àti pé òun gan an ló ǹ kún ìwà ìgbésùmọ̀mí lọ́wọ́.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni ó tí hàn gbangba idí tí ìjọba ààrẹ Buhari kò ṣe lé gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí ìwà ìgbésùnmọ̀mí àti ọdaran, ìjánigbe àti ìpànìyàn.
PDP tẹpẹlẹ mọ ọ pé Isa Pantami ti kọ́kọ́ ṣẹ́ pé òun kò ni òhunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn àgbésùmọ̀mí tẹ́lẹ,
Ṣugbọ̀n nígba tí àwọn onírúurú ẹ̀rí jẹ́yọ lórí ìkópa rẹ̀ ló tó sọ pé o ti pẹ sẹyin àti pé ó tí lé ni ogun ọdún tí òun tí fi gbogbo irú ìròrí bẹ́ẹ̀ sílẹ̀.
Ẹgbẹ́ náà ni òun fi gbogbo ọwọ́ sọyà pé, Isa wà nínú ẹgbẹ́ alákatakítí ẹ̀sìn Islam, àti pé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tí wà ní ìgboro, mínísítà ìjọba Nàìjíríà yìí mú kí dátà àwọn ará ìlú bọ́ sọ́wọ́ àwọn tí kò yẹ kí ó bọ́ sí lọwọ.
Bákan náà ló fẹ́sùn kan pé àwọn tíì kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà pẹ̀lú ló n fórúkọ sílẹ̀ láti gbà nọ́mbà ìdánimọ̀, "a fẹ́ kí ilé iṣẹ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ṣe ìwádìí gbogbo èyí.
Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ PDP ṣe sọ, wọ́n rọ ààrẹ Muhammadu Buhari láti túbọ̀ fí ọ̀kan ará ìlú balẹ̀ lasiko yii.
PDP ni ki ijọba Buhari yọ àtẹ̀jáde rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Isa Pantami kí ó sì fún mínísítà náà ní ìwé lọ rọ́ọkún nílé, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ akin láti lé gbogbo àwọn tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn agbésùnmọ̀mí.
- Àwọn olórí orílè-èdè ilẹ̀ Áfíríkà mẹ́fà tó rọ́pò òbí wọn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.
- Dangote àti iléeṣẹ́ méjì ló ń ta símẹ́ntì, ìjọba gbọdọ̀ wá ńkan ṣe sí ọ̀wọ́n-gógó yìí- Aṣòfin
- Kíni ìdí ti àwọn ọmọ ogun fi n ṣọ́ àwọn Imaam ni Mecca?
- Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi dúró gìdìgbà lẹ́yìn Pantami t'áráàlú ní kó fipò sílẹ̀
- Kí ló ń fa rúgúdù láàrín àwọn òṣìṣẹ́ fásitì EKSU àti ìjọba Ekiti?
- Wo ìpínlẹ̀ 14 ní Nàìjíríà tí America kílọ̀ pé kí àwọn eèyàn rẹ̀ má dé ...

Oríṣun àwòrán, @Pantami
Pantami resign: Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi dúró gìdìgbà lẹ́yìn Pantami t'áráàlú ní kó fipò sílẹ̀
Ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti yi ọrọ awọn ọmọ Naijiria to n pe fun ikọwefipo silẹ minisita eto ibaraẹnisọrọ, Isa Pantami danu.
Ẹsun ti wọn fi kan Pantami ni pe o n ṣatilẹyin f'ẹgbẹ agbesunmomi pẹlu awọn ọrọ kan to ti sọ sẹyin ki o to di minisita.
Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ aarẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu fi sita, ileeṣẹ aarẹ ni pipe fun ikọwefipo silẹ Pantami kii ṣe nitori oun to sọ ni bii ogun ọdun sẹyin.
- Kí ni ìdí tí àwọn ọmọ Naijiria ṣe fẹ́ kí Isa Pantami kọ̀wé fi ipò sílẹ̀?
- Buhari, pàṣẹ fún Pantami kó lọ tọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ aṣọ lórí ìforúkọsílẹ̀ NIN-SERAP
- N kò ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Boko Haram àti Al-Qaeda, ẹbu ìròyìn ló jáde síta - Mínísítà
- Èrò ọmọ Nàìjíríà sọ̀tọ̀tọ̀ lórí fàákájáa láàrin Abike Dabiri-Erewa àti mínísítà ètò ìbárẹ̀nisọrọ̀,
Shehu ni awọn eeyan kan ni wọn fẹ ki minisita naa dawọ iṣẹ ribi ribi to n ṣe fawọn ọmọ Naijiria duro ki wọn le ri ti wọn ṣe
"Minisita eto ibaraẹnisọrọ ti tọrọ aforijin lori ọrọ to sọ nipa awọn agbesunmomi ni bii ogun ọdun sẹyin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lootọọ ni pe awọn ọrọ naa buru jai ṣugbọn ko ni sọ iru rẹ mọ," Shehu ṣalaye.
Ki lo fa awuyewuye yii gan an?
Awọn eeyan bẹrẹ si ni pe fun ikọwefipo silẹ Pantami lẹyin ti fidio kan nibi to ti n kaanu awọn alakatakiti ẹsin lu ori ayelujara pa.
Pantami kọkọ sọ pe oun ko ni nkan ṣe pẹlu awọn agbesunmomi, o ni ibanilorukọ jẹ lọrọ naa foun.
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn àdúgbò tó ta lẹ́nu jùlọ nílùú Ibadan
- Ẹlẹ́wọ̀n tó pẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n jùlọ ní Amerika gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn ọdún 68 lẹ́wọ̀n
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ibi ọmọ níí ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ ọmọ láyé? Kínni pàtàkì ibi ọmọ?
- Wo bí àwọn gbájúẹ̀ ṣe lu ìyá ẹni ọdún 90 ní jìbìtì $32 mílíọ́nù dọ́là
- Àwọn agbébọn pa ọmọ ikọ̀ Amọtẹkun kan ni ìpínlẹ̀ Oyo
- Baba Ijesha kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀
- Dangote àti iléeṣẹ́ méjì ló ń ta símẹ́ntì, ìjọba gbọdọ̀ wá ńkan ṣe sí ọ̀wọ́n-gógó yìí- Aṣòfin
Ṣugbọn minisita naa pada gba pe otitọ loun sọrọ atilẹyin fawọn ẹgbẹ agbesunmomi, amọ oun ti ko awọn ọrọ naa jẹ.
"Ọjọ ori mi si kere nigba ti mo sọ awọn ọrọ yii, fasiti ni mo si wa nigba naa, ọdọ langba ni mi," Pantami lo sọ bẹẹ.
Ẹwẹ, ileeṣẹ aarẹ ni minisita eto ibaraẹnisọrọ lo gbogun ti bi awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ti maa n ja owo awọn eeyan lọna aitọ.
Garba ni ijọba Buhari duro gidigba lẹyin Pantami ko le tẹsiwaju pẹlu iṣẹ takuntakun to n ṣe lati ri pe ko si ẹni to n yan awọn ọmọ Naijiria jẹ mọ lẹka eto ibaraẹnisọrọ.
- Wo àwòdamiẹnu àwòrán Mọ́ṣáláṣí Ànọ́bì ní Medina!
- Ẹlẹ́wọ̀n tó pẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n jùlọ ní Amerika gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn ọdún 68 lẹ́wọ̀n
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn àdúgbò tó ta lẹ́nu jùlọ nílùú Ibadan
- Irọ́ lásán ni pé èèyàn 25 bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé ní òpópónà Igboọra sí Eruwa - Ọlọ́pàá Ọyọ
- Wo àwọn 'App' tó ń ba fóònù jẹ́ ní Nàìjíríà
- Ṣé òtítọ́ ni pé ikú apanilẹ́ẹ̀rín Ada Jesus lọ́wọ́ ayé nínú?
- Kíni ìdí ti àwọn ọmọ ogun fi n ṣọ́ àwọn Imaam ni Mecca?

















