#PantamiMustResign, Isa Pantami: Àwọn ọmọ Naijiria ń fẹ́ ìyọnípò mínístà fún ọ̀nà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nítorí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa àwọn agbésùnmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, @NewsWireNGR
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n pe fun ikọwefiposilẹ minisita fun ọna ibaraẹnisọrọ, Isa Pantami lori ayelujara pẹlu ami #PantamiMustResign.
Igbesẹ naa ko ṣẹyin ẹsun ti wọn fi kan pe o n sọrọ atilẹyin fun ẹgbẹ agbesunmọmi bii Al-Qaeda ati Taliban.
Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin ori ayelujara kan ti kọkọ jabọ pe ijọba ilẹ Amẹrika ti fi orukọ Pantami sara awọn eeyan ti wọn n ṣọ loju-lẹsẹ nitori pe o n ṣe atilẹyin fun awọn agbẹsunmọmi, ṣugbọn ilesẹ iroyin naa ti yi ohun pada.
- A ti ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún òmìnira ilẹ̀ Yoruba, a ò níbi kankan ti a fẹ́ sálọ - Ọba Adetokunbo Tejuosoho
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
- Màálù 250 tasẹ̀ agẹ̀rẹ̀ wọ oko ní Ilaramọkin, ní ikọ̀ Amotekun bá sọ Màálù àti olówó rẹ sí gbaga
- Ṣé o fẹ́ lọ sí ọ̀run rere? Wo bí Naira Marley ṣe le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wọlé
Pantami ti ṣe awọn waasi kan lawọn ọdun diẹ sẹyin, nibi ti wọn ni o ti sọrọ atilẹyin fun ikọ agbesunmọmi Al-Qaeda ati Taliban, eyii to da rogbodiyan silẹ lori ayeluja.
Ọrọ naa mu ki ọpọ awọn ọmọ Naijiria sọ pe ko kọwe fi ipo silẹ tabi ki Aarẹ Muhammadu gba iṣẹ lọwọ rẹ, nigba ti awọn eeyan miran si sọ pe Pantami ko ṣe si ofin kankan.
Pantami funra rẹ, to jẹ onimọ nipa ẹsin Musulumi ti fesi pe oun ko ni nkankan ṣe pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi kankan.
Yatọ si awọn ọmọ Naijiria to n lọgun pe ki wọn gba iṣẹ lọwọ Pantami lojo opo Twitter, eeyan kan gboogi to n jẹ ọrọ naa lẹnu ni Reno Omokri, to jẹ amugbalẹgbẹ Aarẹ ana, Goodluck Ebele Jonathan.

Oríṣun àwòrán, @Living__death
Bi ẹ ko ba gbagbe, Omokri yii lo lewaju awọn ọmọ Naijiria kan to n ṣe ifẹhonuhan niwaju ile ijọba Naijiria ni London lasiko ti Aarẹ Muhammadu Buhari lọ ṣayẹwo ilera ara rẹ lọsẹ diẹ sẹyin.
Yatọ si Omokri, ẹgbẹ oṣelu PDP naa ti sọ pe ki minisita naa kọwe fi ipo silẹ lori ọrọ ọhun.
PDP sọ ninu atẹjade kan pe ominu n kọ awọn nitori ipo ti Pantami wa ni Naijiria, ati pe ewu n bẹ loko longẹ to ba jẹ pe lootọ ni o n ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ agbesunmọmi.
PDP tun sọ pe iroyin nipa awọn araalu to wa ni ikawọ Pantami nipasẹ eto iforukọsilẹ nọmba idanimọ NIN ko jẹ ki awọn ni igbagbọ ninu rẹ mọ, nitori naa o yẹ ko fi ipo silẹ lẹyin ti awọn araalu ti sọ pe ko ṣe bẹẹ.
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé
- Wo ọ̀rọ̀ tí TB Joshua sọ tó mú kí Youtube àti Facebook kọjú ìjà sí i?
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Makinde pàṣẹ pé kí wọ́n wó iléègbé àwọn òṣìṣẹ́ BCOS ní Ibadan?
- Wo àwọn àmì mẹ́jọ ti o lè fi mọ̀ pé ọkọ tàbí aya rẹ ti ń ṣe ìta
Ẹwẹ, ibeere ti ọpọ eeyan n bere bayii ni pe, ṣe Pantami yoo kọwe fipo silẹ ni tabi Aarẹ Muhammadu Buahri yoo fi ọwọ osi juwe ile fun un tabi yoo maa wo o niran?.
Ko si ẹni to tii le sọ ohun to le ṣẹlẹ.
- Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
- Aṣọ tí mo wọ̀ lọ sí 'Headies Award' ló sún mi débi oríire ipò aṣojú LAWMA- Eniola Badmus
- Sanwo-Olu àti Osinbajo ẹ gbà mí o, mo ti jẹ gbèsè - Iyabo Ojo figbe ta




















