"Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"

Foga

Oríṣun àwòrán, others

Gbajugbaja fọganaisa ni ilu Ado Ekiti to maa n mura bii alakọwe ti ṣalaye awọn ohun meremere to ti gbe ṣe nidi iṣẹ naa.

Olwadare kehinde sọ pe oun ti kọ ile meji, ti oun si tun ti ran awọn ọmọ oun lọ si fasiti nidi isẹ fọga ọhun.

Arakunrin naa gbajumọ ni ilu Ado nitori bo ṣe maa n wa ni imọtoto, to si maa n mura bii alakọwe.

Fun apẹẹrẹ, aṣọ alakanpọ suutu ti awọn oṣiṣẹ ile ifowopamọi maa n wọ ni okunrin naa maa n wọ lọjọ Aje, ti bata ẹsẹ rẹ yoo si maa dan yinrinyin.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Bo tilẹ jẹ pe wọn kan gbagbọ pe iṣẹ idọti ni iṣẹ awọn to maa n fẹ taya ọkọ ti okunrin naa yan laayo, imura rẹ fi han pe ko si iṣẹ kankan ti eeyn ko le fi apọnle si bo ti wu ko idọti to.

Àkọlé fídíò, Oba Sunday Oyediran ṣàlàyé kíkún nípa ìṣẹ̀ṣe, ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn tí kò dí ará wọn lọ́wọ́

Olawadare sọ pe o ti le logun ọdun ti oun ti n ṣe iṣẹ naa bọ ati pe inu oun dun pe iṣẹ ọhun ni oun yan laayo.

O ni "Mo ti n ṣe iṣẹ yii bọ bayii, o ti le logun ọdun, Ọlọrun lo si yan iṣẹ naa fun mi."

Foga

Oríṣun àwòrán, others

Oluwadare ni: "Iṣẹ ori ran mi lati ode ọrun wa niyii, ohun lo si ti n bọ emi atawọn ẹbi mi lati ọdun pupọ sẹyin, o si tẹ mi lọrun."

Nigba to n ṣalaye awọn ohun to ti gbe ṣe nidii iṣẹ fọga, Oluwadare ni "lagbara Ọlọrun, mo ti kọ ile nla meji, mo si ti ran awọn ọmọ mi lọ si fasitinidii is.ẹ yii."

Àkọlé fídíò, Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èy

O ni iṣẹ naa da oun loju to bẹ ti oun ba ri anfani lati lọ si ilu Amẹrika, iṣẹ naa ni oun yoo lọ ṣe lọhun.

Fọganaisa naa pari ọrọ rẹ pe oun ti ṣe awọn owo kan sẹyin, bii taya ọkọ tita, ki oun to pinnu lati maa tun taya ọkọ ṣe.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award'ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀