Ilé ẹjọ́ Sharia ní Kaduna tú ìgbéyàwó ká nítorí àìbọ̀wọ̀ fún àna

Oríṣun àwòrán, others
Yoruba ni orò ni ana, ti a kii ri i fin, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹ ẹ fun ọkùnrin onisowo kan ati iyawo rẹ.
Ile ẹjọ Sharia kan to wa ni agbegbe Magajin Gari nipinlẹ Kaduna, ti tu igbeyawo ka laarin ọkùnrin onisowo kan, Abdulrauf Musa ati iyawo rẹ, Jamila Yusuf.
Ituka naa ko sẹyin bi iyawo ṣe pe ọkọ rẹ l'ẹjọ pe o sọ ọrọ abuku si oun, to si tun ṣe àìgbọràn si awọn obi iyawo.
- Ta ni Ousmane Sonko, tí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ ní Senegal lẹ́yìn tí ìjọba fòfin mú u?
- Ó ṣòro púpọ̀ láti mọ ayédèrú òṣìṣẹ́ LASTMA ní ìpínlẹ̀ Eko, ṣùgbọ́n..-Agbenusọ àjọ LASTMA
- Àwọn òsìṣẹ́ ètò ìlera ti bẹ̀rẹ̀ sí ń gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní Naijiria, wo ìgbà tí yóò kàn ọ́
- Oral Sex: Bóo bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tóo lè kó lójú ara rẹ
Adajọ ile ẹjọ naa, Ọgbẹni Murtala Nasir pàṣẹ fún ọkọ iyawo, Musa, pe ko gbọdọ lọ si ile Jamila mọ, nibi ti wọn jọ gbe nigba ti wọn jẹ tọkọtaya.
Yatọ si eyi, adajọ tun pasẹ pe ki Jamila lo ẹgbẹrun mẹwa Naira, owo ori ti ọkọ rẹ san, lati fi pese oúnjẹ fun awọn ọmọ wọn titi di ipari oṣu Kẹta.
Adajọ naa gba tọkọtaya ni imọran lati tẹle ilana to yẹ labẹ ofin lori ẹni ti yoo ko awọn ọmọ sọdọ, to ba wu wọn lati ṣe bẹ ẹ.
Jamila Yusuf bẹ ile ẹjọ lati pàṣẹ fun Musa pe ko san ẹgbẹrun marun-un fun ikọọkan awọn ọmọ mẹjọ ti wọn bi.
Ileesẹ akọroyin NAN jabọ pe ile ẹjọ ti kọkọ sun igbẹjọ siwaju ni ireti pe tọkọtaya yoo yanju ọrọ wọn nile, sugbọn òfo ni igbiyanju naa jasi si.














