Ousmane Sonko: Kí ló fa rògbòdìyàn tó ń wáyé ní Senegal?

Oríṣun àwòrán, AFP
Lati Ọjọru ti wọn ti mu oloselu alatako, Ousmane Sonko, ni ọpọ iwọde ti bẹrẹ ni Senegal, lati pe fun ominira rẹ.
Àmọ́, ki lo n fa wahala to n waye, ati pe àpẹẹrẹ wo ni Ousmane Sonko jẹ fun orilẹ-ede Senegal?
Eeyan meji lo ku, ija ìgboro waye niwaju Fasiti Cheikh Anta Diop ni Dakar, wọn ja awọn ile itaja ati ile epo lole, ti fi mọ biba àwọn dukia ijọba jẹ,wọn tun dana sun ọpọlọpọ ọkọ.
Koda, ko yọ olu ileesẹ àwọn ileesẹ iroyin silẹ.
- Ó ṣòro púpọ̀ láti mọ ayédèrú òṣìṣẹ́ LASTMA ní ìpínlẹ̀ Eko, ṣùgbọ́n..-Agbenusọ àjọ LASTMA
- Àwọn òsìṣẹ́ ètò ìlera ti bẹ̀rẹ̀ sí ń gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní Naijiria, wo ìgbà tí yóò kàn ọ́
- Oral Sex: Bóo bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tóo lè kó lójú ara rẹ
- A ti rí Ọọ̀nì ''crocodile'' 27 nínú àwọn tó sálọ, àmọ́ a ṣì ń wá àwọn tó kù, ẹ̀yin ará ìlú, Ẹ ṣọ́ra!
Awọn nkan yii ko sẹyin wahala ati iwọde to waye ni ọpọlọpọ agbegbe ni Dakar ati agbegbe to yii ka, to fi mọ ìlú Bignona to jẹ ile agbára Ousmane Sonko.
Ni ọjọ Ẹti ọsẹ yii, àwọn ẹgbẹ oṣelu alatako, ati awọn ẹgbẹ́ mii laarin ilu kesi awọn eniyan orilẹ-ede Senegal lati tako igbesẹ ti wọn sapejuwe rẹ gẹgẹ bi ifiyajẹni.
Ni ibẹrẹ oṣu Keji, ni ọmọbinrin kan, ẹni ogún ọdún, to jẹ oṣiṣẹ abani wọ́ ara fi ẹsun ifipabanilopọ kan Ousmane Sonko. O tun ni o n halẹ ikú mọ oun.
Ọpọ igba si ni Sonko ti sọ ni gbangba pe oun ko jẹbi ẹsun naa, bẹ ẹ lo si n tẹnumọ pe Aarẹ Macky Sall lo wa nidi ẹsun naa.
Sugbọn ṣa, aarẹ naa ti sọ pe oun ko mọ nkankan nipa ọrọ ìkọ̀kọ̀ naa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọna ile ẹjọ ti Sonko ti fẹ ẹ lọ jẹjọ lori ẹsun ifipabanilopọ naa lo wa nigba ti wọn mu.
O ti kọkọ kede pe oun ko ni i lọ, pẹlu awijare pe gbigbẹsẹ le ofin imuniti òun ko ba ofin mu.
O ku diẹ ko de ile ẹjọ ni awọn oṣiṣẹ alaabo da òun ati awọn alatilẹhin rẹ duro, ti wọn si sọ fun pe ko gba ọna miran.
Olori ilu Dakar sọ pe bo ṣe kọ̀ lati ṣe bẹ ẹ ni wọn fi mu nitori pe o n da alaafia ìlú rú, to si tun kopa ninu iwọde ti wọn ko gba àṣẹ fun.
Ajọ ajafẹtọ l'agbaye, Amnesty International, sọ pe mímú tí wọn mu Sonko ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ mẹtadinlogun niwaju ile rẹ lọsẹ to kọja, ko ba ofin mu.
Àjọ naa sọ pe inu ọkọ Sonko lo wa nigba ti wọn mu l'Ọjọru.

Oríṣun àwòrán, AFP
Taa ni Ousmane Sonko, ati pe ki lo duro fun?
Oun ni Aarẹ ẹgbẹ oṣelu Pastef, o si tun jẹ ọmọ ile aṣofin lati ọdun 2017.
O si duro gẹgẹ bi àpẹẹrẹ ayipada, fun awọn ajijagbara rẹ.
Ọpọlọpọ igba lati ọdun 2018 si lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu àwọn oloṣelu ni orilẹ-ede naa.
Koda, o ti pẹ wọn ni ọdaran ri, to si sọ pe gbogbo àwọn tó ti dari orilẹ-ede Senegal rí lo yẹ ki wọn o yinbọn mọ.
Ọrọ naa fa awuyewuye, eyi to mu ki Sonko pada yi ọrọ pada pe awọn adari naa le ma jẹ aarẹ, àmọ́ gbogbo ẹni to ti mojuto Senegal ni oun n ba a wi.
Gẹgẹ bi Alamojuto owó orí sísan ni orilẹ-ede naa, Sonko da ajọ aladani kan silẹ lọdun. 2004,lati maa tọ pinpin ijọba.
Lati igba naa si lo ti bẹrẹ si ni bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba, to si tun fi ẹsun kan pe mago-mago ń waye ninu eto isuna.
Lọdun 2014, o da ẹgbẹ oṣelu rẹ, Pastef silẹ, o si bẹrẹ si ni gbèrò lati di aarẹ orilẹ-ede Senegal.

Oríṣun àwòrán, AFP
Lọdun 2016, wọn le e kuro kuro l'ẹnu isẹ ijọba nitori ẹsun pe ko pa àṣírí ijọba mọ.
O dije fun ipo aarẹ lodun 2019, sugbọn ipò kẹta lo ṣe. Àwọn kan ti ẹ pe ni "Trump ti Senegal " nitori iru eeyan to jẹ, ati bo ṣe tako ayọjuran àwọn orilẹ-ede ilẹ okeere.
Gbogbo àwọn oloṣelu to jẹ alatako aarẹ Macky Sall ni wọn ti fi ọwọ rọ sẹyin, àwọn mii bi Karim Wade, to jẹ ọmọ aarẹ nigba kan, Abdoulaye Wade, ti sa kuro niluu lọ si Qatar, lati igba to ti gba ominira kuro ni ẹ̀wọ̀n lọdun 2015.
Nitori naa, Ousmane Sonko nikan ni awọn eeyan n ri gẹgẹ bi alatako gboogi fun Macky Sall.
Lẹyin ti àwọn oṣiṣẹ alaabo mu, ijọba orilẹ-ede Senegal ti fofin de ileesẹ amohunmaworan meji fún wakati mejilelaadọrin, nitori pe wọn ṣe afihan rogbodiyan to waye.
Bakan naa ni ijọba ti kilọ fun awọn ileesẹ iroyin láti sọra ṣe fun ṣíṣe ègbè, eyi to le fa ikorira àti rogbodiyan míì.
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
- "Sọ́jà fi ìbọn gé mi lọ́wọ́ kó lè fipá bámi lòpọ̀"
- Wòlíì Kasali gba Bunmi ìyàwó rẹ̀ àkọ́fẹ́ padà, ìjà parí!
- Buhari ni káwọn agbófinró ó yìnbọn fáwọn tó ń gbé ìbọn AK-47, àwọn ọmọ Nàìjíríà n pariwo "lórí irọ́"
- A ti rí Ọọ̀nì ''crocodile'' 27 nínú àwọn tó sálọ, àmọ́ a ṣì ń wá àwọn tó kù, ẹ̀yin ará ìlú, Ẹ ṣọ́ra!
Lori iṣẹlẹ yii, agbenusọ ijọba, Oumar Gueye koro oju si rogbodiyan to waye lẹyin ti ọwọ tẹ Ousmane Sonko
Bakan naa lo sọ pe awọn alasẹ tí n wadii iku ọkùnrin kan niluu Bignona, lati mu idajọ wá sori àwọn "to da wahala silẹ, àwọn to fa wahala, ati awọn to rán wọn lọwọ".
Ajọ kan to n tọ̀ pinpin ayelujara, Netblocks, sọ pe lilo awọn oju opo ayelujara bi Facebook, WhatsApp, Telegram, ati YouTube, ko ja geere.
Ajọ naa ati awọn eeyan kan si ti bu ẹnu ẹtẹ lu u.
Sugbọn ni owurọ òní,oju opo ayelujara ti dára pada. Ijọba ko si ti i sọ ohunkóhun nipa ọrọ naa.















