Sim Swap registration: Ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sí ìforúkọsílẹ̀ síìmù ní ìjọba ìbílẹ̀ 774 káàkiri Naijiria

SIM

Oríṣun àwòrán, @Nairametrics

Ijọba apapọ ti fun awọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ laṣẹ lati ṣe agbekalẹ awọn ọọfisi ti wọn ti le maa paarọ siimu fun awọn eeyan ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni Naijiria.

Bẹẹ ni ijọba apapọ tun ṣe afikun iye akoko ti awọn to n fi orukọ siimu silẹ ni aṣẹ lati maa ṣi iṣẹ naa lati ọdun kan si ọdun marun un.

Afikun yii ni igbimọ amuṣẹya to n ri si ọrọ iforukọsilẹ siimu buwọlu niluu Abuja.

Alaga igbimọ naa, minisita eto ibaraẹnisọrọ, Ọmọwe Isa Ali Ibrahim Pantami sọ pe ijọba apapọ gbe igbesẹ ọhun lọna ati mu aye dẹrun fun awọn eeyan ilu.

Pantami ṣalaye pe ojuṣe igbimọ ọhun ni lati gbe ilana tuntun kalẹ fun iforukọsilẹ siimu.

SIM

Oríṣun àwòrán, @Conti_radio

O ni awọn ko ni gba ki irufẹ ohunn to ṣẹlẹ ṣaaju waye, ninu eyii ti awọn ileeṣẹ to n ṣe iforukọsilẹ siimu ti kọkọ da eto naa ru.

Minisita ọhun gboriyi fun awọn ọmọ Naijiria fun suuru wọn lẹyin ti ijọba apapọ paṣẹ tuntun lori siso siimu pọ mọ nọmba idanimọ NIN.

Lẹyin naa lo fi da awọn eeyan ilu loju pe gbogbo igbesẹ ijọpa apapọ lati akoko yii lọ yoo jẹ eyii ti yoo mu aye dẹrun fun wọn.

Ṣaaju n i ijọba apapọ ti kọkọ kede pe ki gbogbo awọn ọmọ Naijiria atawọn ajoji to n fi Naijiria ṣe ibugbe lọ ṣe iforukọsile siimu wọn, ki wọn si so simu naa mọ pọnọmba idanimọ NIN.

Àkọlé fídíò, #EndSars Ogbomoso: Èmí kò ní kí wọ́n pa ọlọ́pàá tó pa Isisaka, ṣùgbọ́n...- Ramota, Iya Isi

Ṣugbọn ikede naa ko dun mọ ọpọ ọmọ Naijiria ninu nitori osiriṣiriṣi iṣoro ti wọn dojukọ ninu akitiyan wọn lati ga nọmba idanimọ NIN.

Awọn miran ẹwẹ tun bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba apapọ lẹyin to gbẹsẹle iforukọ siimu tuntun, eyii to mu ko ṣoro fun ọpọ eeyan lati paarọ siimu wọn lẹyi ti ẹrọ ilewọ wọn kọṣẹ tabi sọnu.

Àkọlé fídíò, NURTW Ondo: Ọ̀pọ̀ èrò ní Akure fi ayọ́ hàn bí Aketi ṣe ni kí NURTW lọ sinmi