Yoruba-Fulani crisis: Ọlọrun má jẹ́ kí a jẹ́ gbèsè lókù báyìí tí a kò kó ọjá lọ sílẹ̀ Yorùbá mọ́- Hausa Oníṣòwò

oja

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ẹgbẹ olounjẹ ati ẹlẹran ọsin ni Naijiria lati ariwa ti amọ si AUFCDN n tẹsiwaju ninu iyanṣẹlodi wọn.

Egbe yii ti apeja orukọ wọn n jẹ: Amalgamated Union of Foodstuff and Cattle Dealers of Nigeria (AUFCDN) ni wọn kede pe ohun gbogbo ti gba ọpọ bayii nilẹ Hausa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Gbogbo awọn agbẹ ti ọrọ kan ni apa ariwa Naijiria ti wọn ti n ko ohun eelo ọbẹ bii ata, tomati, alubọsa, iresi ati bẹẹ bẹẹ lọ ti n pariwo gbese..A ò ní kó oúnjẹ lọ sílẹ̀ Yorùbá láì jẹ́ pé ààbò wà fáwọn Fulani níbẹ̀- Miyetti Allah

Wọn ni ọpọ ti ko ni ere rara ni awọn fi n ta nkan ọbẹ bayii ki wọn ma baa bajẹ mọ ori igba ati inu oko awọn.

Awọn miran ni ọrọ naa ko le tii aynju bayii laisi awọn igbesẹ kan;

Oja

Koda, ọpọ eeyan lo ti fidi ẹ mulẹ pe ọpọ ni apẹrẹ Tomati ati rodo bayii ni awọn ipinlẹ to wa ni ariwa ati ni Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn kan ṣe lọ di opopona ti wọn n gba ko nkan oko wọle wa si iwọ oorun guusu Naijiria lati ariwa

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Ọpọ awọn eeyan lori ayelujara lo ṣalaye pe ohun to ṣokunfa gbese ọlọpọ yanturu ni ariwa yii ko ṣẹyin pe awọn ata ti pọ ju nibẹ nitori pe wọn ko ri wọn ko lọ si awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba ati Igbo.

Bẹẹ awọn eeyan ti n sọrọ lori ayelujara:

Oja

Bawo ni ọmọ ṣe sọri lọja ilẹ Yoruba ati Igbo bayii?

Ni iṣọ ẹlẹran ìso ni ọja Alaba ni ipinlẹ Eko ni owo ẹran agbo ti di ilọpọ mẹta bayii.

Akọroyin BBC to lọ sibẹ ni koda, niṣẹ ni gbogbo ọja naa da waiwai ti ero ko si pọ rara.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

O ni bẹẹ si ni gbogbo ẹran ọsin ati awọn nkan miran gbowo lori jọjọ.

Mallam Tanimu Bulama to jẹ Waziri alaba Rago ṣlaye fun BBC pe: Eran agbo ti wọn n ta ni N30, 000 tẹlẹ ti di N95,000 bayii nitori pe Niger ati ilẹ Sudan gba ilẹ Hausa ni awọn n gab ko ẹran wọle ju.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ero awọn Yoruba to n ra ọja ọwon naa yatọ bayii:

Oja

Mallam Umar to tun ba BBC sọrọ ṣalaye pe ironu ti ba ọpọ awon agbẹ ati Oniṣowo ni ariwa Naijiria nitori pe nkan ti n bajé si ori igba wọn.

O ni bayii awọn ti n ta tomati apẹrẹ ti wọn n ta ni N2,100 tẹlẹ ni N800 nitori pe wọn ti n bajẹ.

Eran

Oríṣun àwòrán, @Awal Ahmad

Se lootọ ni wọn n ko ọja pamọ?

Awọn miran ni awọn ọlọja nilẹ Yoruba n ko ọja pamọ nitori pe ọja mii ko de lati ilẹ Hausa.

ẹran

Sugbọn Emir ọja Alaba, Alhaji Umaru Goggo ni irọ ni eyi.

O parọwa pe asiko ti to ki wọn fopin si aṣẹ ma ko ọja wọle lati ariwa yii.

O ni o n ṣakoba fun ati Hausa ati Yoruba ati Igbo ni bayii.

Koda, Emir naa ke si aarẹ Naijiria lati wa ojutu si iṣoro yii ki nkan ma lọ bajẹ tan.

Àkọlé fídíò, NURTW Ondo: Ọ̀pọ̀ èrò ní Akure fi ayọ́ hàn bí Aketi ṣe ni kí NURTW lọ sinmi