Omoyele Sowore: Ìpakájà, Ìrọ́kẹ́, Ode àti àwọn ǹkan míràn tó fọnrere òòtọ́ inú Babaláwo- Fagbenle Adedayo, Agesin Adimula Ila Orangun

Oríṣun àwòrán, The guradian Nigeria
Bí ẹ ṣe lè dá babaláwo tòótọ́ àti òfégè mọ̀ rèé
Ẹ̀yin tí ẹ ń pariwo babaláwo tẹ̀lé Sowore lọ sílé ẹjọ́, bí ẹ ṣe lè dá babaláwo mọ̀ rèé
Ni ọjọ Iṣẹgun ti eekan ajafẹtọ, Ọmọyẹle Ṣoworẹ lọ si ile ẹjọ, arameeri iran lo waye nigba ti eeyan kan ninu aṣọ ti o kun fun owo ẹyọ ti wọn ta sii lara tẹle wọ ile ẹjọ.
Imurasi arakunrin naa fa ọpọ ariyanjiyan ati gbọyisọyi lori iru ẹni gan an ti arakunrin naa jẹ.
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
- Wo ohun tí Ńo-Fly Zone' túmọ̀ sí
- Ewú ńbẹ! tí ìjọba ìpínlẹ̀ bá sàkóso gbèndéke owó oṣù òṣìṣẹ́,wọ́n ò ní san N30,000, N10,000 ní wọ́n má á san -NLC
- Nǹkan dé, Igboho ní káwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá lọ múra ògùn jọ nítorí ohun tó ń bọ̀ lọ́nà
- Chimamanda Adichie pàdánù bàbá, ìyá láàrín ọdún kan, kíló ṣẹlẹ̀?
Eyi lo mu ki BBC News Yoruba tọ awọn agba onimọ lọ lori ọna ti a fi lee da Babalawo mọ.
Ninu ọrọ to sọ, Baba Agẹṣin Adimula ti ilu Ila Ọrangun, Oloye Fagbenle Adedayọ ṣalaye pe lati igba iwaṣẹ, bẹrẹ lati ori Ọrunmila to jẹ Babalawo akọkọ ni awọn babalawo ti ni ilana imura wọn.
Ipakaja:
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ko si aṣọ ti Ọrunmila ko lee wọ, to ba ji, o lee wọ aṣọ pupa, to ba ji o le wọ aṣọ dudu, ṣugbọn aṣọ funfun ati aṣọ alaro ni ọrunmila to jẹ Babalawo akọkọ maa n saba wọ ju.
Amọṣa ohun ti a fi maa n daa mọ gẹgẹ bi Orunmila ni pe yoo pa kaja.

Oríṣun àwòrán, facebook/ifayemi elebuibon
Pipa kaja tumọ si riro aṣọ nla ti a wa so ọwọ rẹ si ibi ejika kan. Apẹrẹ pipa kaja ni bi Kabiyesi Ọọniriṣa ṣe maa n mura.
Babalawo to ba jẹ onifa maa pakaja aṣọ bi o ti le wu ki aṣọ to wọ o ri. Aṣọ to ba wu babalawo lo lee wọ si isalẹ, ṣugbọn ohun kan ti ko gbọdọ maa ṣe ni pipakaja sori aṣọ bẹẹ.
Ohun idanimọ akọkọ fun awọn alawo ni pe bi o ti le wu ki aṣọ ti wọn ba wọ o ri, o gbọdọ da aṣọ bora lati pa kaja.

Oríṣun àwòrán, facebook Ifayemi elebuibon
Irọkẹ
Lẹyin ti babalawo ba ti pakaja rẹ tan, o gbọdọ mu irọkẹ dani.
Ki ni ohun ti Yoruba n pe ni irọkẹ? Irọkẹ ni igi kekere kan bayii ti wọn maa n sin. Igba miran si wa ti wọn si maa n lo eyin erin atawọn igi kan ni igbo ti awọn agba mọ.
Irọkẹ yii ni babalawo maa fi n lu oju ọpọn ifa kere-kere ti wọn ba ti n da ifa tabi ki ifa lọwọ.
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
- Àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin gbé ní Zamfara fẹ́ yẹ̀yẹ́ Ìjọba Buhari ni- Hadi Sirika
- Ewú ńbẹ! tí ìjọba ìpínlẹ̀ bá sàkóso gbèndéke owó oṣù òṣìṣẹ́,wọ́n ò ní san N30,000, N10,000 ní wọ́n má á san -NLC
- Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó dá mi lọ́nà lọ́jọ́ Ẹtì fẹ́ pa mí ni -Sunday Igboho
- Nǹkan dé, Igboho ní káwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá lọ múra ògùn jọ nítorí ohun tó ń bọ̀ lọ́nà

Oríṣun àwòrán, Others
Ode:
Ohun miran ti a fi n da babalawo mọ ni iduro ni ode ifa. Babalawo gbọdọ ni ode ifa lọwọ.
Gẹgẹ bi Oloye Fagbenle Adedayọ, Agẹsin Adimula ilu Ila Ọrangun ṣe sọ, ode ifa yii da bi iyun tabi ilẹkẹ ti o maa n ni awọ eweko (green) ati awọ ilẹ (brown). Ode yii ni wọn maa n so mọ ọwọ.
Gẹgẹ bi ẹsẹ ifa ṣe sọ, ode yii duro fun iwalaaye ẹda lori ilẹ. Idi niyi ti o fi yan awọ eweko ati awọ ilẹ.
Agẹṣin Adimula ilu Ila Ọrangun ṣalaye pe kii ṣe ọpa ti a sin nii fi eniyan han bi babalawo, gẹgẹ bi ọpọ ti maa n rii ninu awọn sinima agbelewo gbogbo.
O ni babalawo yoo mura daadaa gẹgẹ bi o ti yẹ, kii ṣe aṣọ ti wọn ko ogun si yannayanna lawọn babalawo maa n wọ.

Oríṣun àwòrán, facebook/Ifayemi Elebuibon
Agesin Adimula ni: "Awọn to n wọ aṣọ ogun, awọn la n pe ni oniṣegun"
Bakan naa lo fi kun un pe babalawo kii di irun ori rẹ, oniṣegun ati ọlọya lo maa n di irun ori wọn.
"Bi babalawo ba fa ori tan wọn le da irun kekere kan silẹ ni aarin ori ti wọn n pe ni aso ifa lawọn iha ibikan nilẹ Yoruba
"Ohun to ba fi le yatọ si eyi, (kii ṣe babalawo) gbogbo awọn baba ti a ni ẹ o ri bẹẹ nitori pe wọn kii ṣe oniṣegun.
Gbogbo ohun ti a ba fẹ sọ inu ifa lo ti n jade. Ifa o ki n di nnkan mọra, ọrọ ni Ifa"
- Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
- Wo ohun tí Ńo-Fly Zone' túmọ̀ sí
- Ẹ kó àwọn ọkọ̀ yín tó ti dẹnukọlẹ̀ kúrò lójú popo tàbí kí a gbẹ́sẹ̀lé wọn- FRSC sí àwọn awakọ̀
- Ohun tó yẹ kí ó mọ̀ nípa oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ ìbàdí rè é
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Ẹ wo bí ìyàwó Pasitọ Adeboye ṣe sàpèjúwe rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @Sowore
Ẹni tó tẹ̀é mi lọ sílé ẹjọ́ ti ayé ń pariwo kìí ṣe Aláfọ̀ṣẹ rárá bíkòṣe...- Sowore
Ẹni to tẹlẹ mi lọ sile ẹjọ ti aye n pariwo kii ṣe Babablawo bikoṣe arakunrin to wa ṣatilẹyin fun mi- Sowore.
Bo ṣe wu eeyan lo ṣe le mura lọ sile ẹjọ lati ṣatilẹyin fun mi ni ọrọ ti Sowore kọkọ fi fesi ibeere irufẹ ẹni ti arakunrin naa jẹ.
Omoyele Sowore to n jẹjọ nile ẹjọ ni Abuja ti ba BBC sọrọ lori akọni to wa lẹyin rẹ nibi igbẹjọ ni ana.
Oludari ikọ #Revolution now, Omoyele Sowore to dije dupo aarẹ ni Naijriia lọdun 2019 ti sọrọsoke.
O salaye nipa arakunrin kan to tẹlẹ e lọsile ẹjọ ni Abuja ni ana.
Omoyele Sowore ni ọkunrin naa kii ṣe babalawo tabi onisegun rara.
Koda, o ni ki ṣe alafọṣẹ bi awọn kan ṣe n sọ kiri lori ayelujara.
Sowore ni arakunrin naa jẹ akọni ọmọ ilẹ Adulawọ to ṣafihan igbagbọ rẹ ninu imura rẹ.
O ni eyi ko si tako ofin ilẹ Naijiria nitori pe bi o ba ṣe wu ni ni a n ṣe imale ẹni ati imura ẹni.

Omoyele Sowori to jẹ oludasile ile isẹ iroyin Sahara Reporters ni idi ti arakunrin naa fi mura bẹẹ ni pe o kan fẹ fi han awọn eniyan kan ti wọn maa n tabuku imura ibilẹ ni.
O ni awọn aṣa imura ati igbagbọ ilẹ wa kan ni ẹsin ajoji ati imura atọhunrinwa ti gbọn dani lọwọ wa ni eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Sowore sọ fun BBC pe ọkunrin naa wa ṣe atilẹyin fun oun gẹgẹ bii akọni ẹlẹru ni.

Oríṣun àwòrán, @Aisha
Ati pe Bi Pasitọ ati Aafa ati Wooli eeyan ṣe le wa pese iranlọwọ atilẹyin fun un lasiko iṣoro naa ni ọkunrin naa wa ṣe fun oun.
Lati igba ti wọn ti yọ sile ẹjọ ni awọn eeyan ti n sọ oriṣiriṣi nipa imura arakunrin naa.
- Ọ̀jọ̀gbọ́n Ijeoma ní òun kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́, South Africa tó yàn dípò bá tún lé e jáde
- Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
- Ẹ kó àwọn ọkọ̀ yín tó ti dẹnukọlẹ̀ kúrò lójú popo tàbí kí a gbẹ́sẹ̀lé wọn- FRSC sí àwọn awakọ̀
- Ohun tó yẹ kí ó mọ̀ nípa oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ ìbàdí rè é
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?

















