NURTW Ondo: Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ NURTW

Àkọlé fídíò, NURTW Ondo: Ọ̀pọ̀ èrò ní Akure fi ayọ́ hàn bí Aketi ṣe ni kí NURTW lọ sinmi

Wo ohun ti awọn awakọ ati ero ati awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ba BBC sọ ni Ondo.

NURTW

Awọn eniyan nipinlẹ Ondo ti fi idunnu wọn han lori lẹyin ti awọn awakọ din owo ọkọ ku kaakiri ipinlẹ naa.

Eyi ko ṣẹyin bi ijọba gomina Akeredolu ṣe fofin de ẹgbẹ awọn NURTW nipinlẹ naa.

NURTW

Ijọba paṣẹ ki wọn ma ṣe gba owo ori lọwọ awọn awakọ mọ, eleyii to mu ki wọn ri owo ọkọ to lọ si ilẹ lowurọ oni.

Akọroyin BBC to kaakiri ilu Akure laarọ oni ni awọn awakọ Taxi ati awọn eniyan to n wọ inu ọkọ fi idunnu wọn han lori igbese ijọba naa.

NURTW

''Owo ọkọ irinajo kekere to jẹ ọgrun naira tẹlẹ ti da aadọta naira laarọ oni''

''Amọ awọn agbegbe to jina naa ni wọn n gbe ni ọgọrin naira si ọgọrun un naira''

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Olùkọ́ Olajide láti Ẹdẹ ló ṣàlàyé nípa Awẹ́ Gbólóhùn fún wa ní kíkún

''Inu awọn awakọ taxi ati awọn ọlọkada dun nitori wọn ko san owo ''tikẹẹti'' mọ ni ilu Akure''

''Amọ, awọn awakọ ni garagi fi aidunnu wọn han nitori ibanujẹ lo jẹ fun wọn''

NURTW

Ọkan ninu awọn awakọ to ba BBC sọrọ ni igbesẹ ijọba ti gba ounjẹ lẹnu awọn nitori ọpọlọpọ ni wọn n jẹ lara ẹgbẹ NURTW naa.

Bakan naa ni wọn sọ wi pe oṣeeṣẹ ki wahala ati iwa ọdaran posi ni igboro nigba ti ọpọ eniyan ko ba ri iṣẹ ṣe mọ.

NURTW

Amọ, ijọba ni awọn ajọ NURTW ko pa owo wọle fun ijọba, eleyii to mu wọn gbe igbeṣẹ naa.

NURTW

A ti wi pe awọn ẹgbẹ naa ma n gbe ijọba kalẹ fun awọn ẹlomiran, ti ijọba tuntun ba ti wọle ni ipinlẹ naa, eleyii ti o ma n mu ẹmi ọpọ eniyan lọ nitori rogbodiyan to ma n waye lasiko igbajọba lọwọ ara wọn naa.

Àkọlé fídíò, Mother tongue day 2021, Akomolede, YSAN: A ti parí iṣẹ́ lórí èdè ìperí Meta-Language Yorùb