Coronavirus in Nigeria: Abẹ́rẹ́ àjẹsára, Covid 19 ti balẹ̀ bàgẹ̀ sí orílẹ̀èdè Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter
Abẹrẹ ajẹsara covid 19 lati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus ti de si orilẹede Naijiria.
Ilu Abuja ni ọkọ afurufu to gbẹ abẹrẹ ajẹsara naa balẹ si, awọn eleto ilera si wa nibẹ lati ri wipe gbogbo rẹ lọ daradara.
Nibayii, Ijọba ti ni awọn elto ilera ni yoo kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara naa.
- Èèyàn 360 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ tún lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà
- 'Tinubu kò ṣe nǹkan ètùfù tó lè fi máa kíyèsí ẹ̀yìnkùlé nítorí EFCC'
- Ọ̀jọ̀gbọ́n Ijeoma ní òun kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́, South Africa tó yàn dípò bá tún lé e jáde
- Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
Ti awọn oloṣelu yoo si bẹrẹ si ni gba lati Ọjọ Ajẹ, ọṣẹ too n bọ.
O ti le ni ẹgbẹrun eniyan ti aarun Coronavirus ti mu ẹmi wọn lọ lorilẹede Naijiria.
Wo alakalẹ lati pin abẹrẹ ajẹsara Covid-19
Ni bayii ti ijọba apapọ ti n reti abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Naijiria, ọpọ eeyan lo ti n woye bi wọn ṣe le ri abẹrẹ naa gba, ati ibi ti wọ ti le gbaa.
Ṣaaju ni minista eto ilera, Ọlọruninbẹ Mamora ti kọkọ kede pe awọn oṣiṣẹ eto ilera to n ṣetọju awọn to ti lugbadi arun na ni yoo kọkọ gba abẹrẹ ọhun.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto ilera alakọbẹrẹ, iyẹn National Primary Health Care Development Agency, NPHCDA, ti kede bi awọn ṣe le gba abẹrẹ naa.
- Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó dá mi lọ́nà lọ́jọ́ Ẹtì fẹ́ pa mí ni -Sunday Igboho
- Nítorí 'áfúsá', àwọn nọ́ọ̀sì bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì l'Ondo
- NYSC Portal.ng: Ọjọ́ Kẹtà, oṣù yíì ní NYSC yóò ṣí ojú òpó fún àgùnbánirọ̀ Batch A, ẹ̀kúnrẹ̀rẹ́ wà ní ìbí...
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
Ninu atẹjade ti wọn fi lede loju opo Twitter wọn, NPHCDA ni awọn eeyan le lọ fi orukọ silẹ lati gba abẹrẹ naa lori ikanni www.nphcda.gov.ng.
Bawo ni ẹ ṣe le fi orukọ silẹ fun abẹrẹ naa?
Ti ẹ ba ti de ori ikanni nphcda.gov.ng, ẹ lọ si abala ti ẹ ti le fi orukọ silẹ fun abẹrẹ naa ni igun apap ọtun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ẹ o ri awọn imọran kan nibẹ pẹlu awọn nọmba ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti ẹ le pe nipa abẹrẹ ọhun.
Lẹyin naa ni ẹ o ri fọọmu iforukọsilẹ abẹrẹ ajẹsara ọhun.
Lara awọn awọn ohun ti wọn yoo bere ninu fọọmu naa ni orukọ yin, ẹrọ ibaraẹnisọrọ, email, nọmba ile ti ẹ n gbe, ọjọ ibi yin, ibi ti ẹ ti fẹ gba abẹrẹ naa atawọn ohun miran to ṣe pataki nipa yin.
Ti ẹ ba ti tẹ awọn alaye yin sinu fọọmu naa tan, ki ẹ fi ranṣẹ si ajọ NPHCDA.
Ti ẹ ba ti ṣe eyii tan, NPHCDA yoo fun yin ni nọmba idanimọ kan gẹgẹ bii nọmba abẹrẹ ajẹsara yin.
Ẹ wo àwọn tí yóò kọ́kọ́ gba abẹ́rẹ́ àjẹsárá Covid-19 to bá dé sí Naijiria...

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba orilẹede Naijiria ti fi lede awọn ti yoo kọkọ ni anfaani lati gba abẹrẹ ajẹsara ti yoo koju aarun Coronavirus ni Naijiria.
Ninu atẹjade ti wọn fi lede pẹlu ajọṣepọ Ajọ eto Ilera Lagbaye, WHO ati Ajọ UNICEF ni wọn ti gbe alakalẹ naa jade.
Ijọba ni awọn ti yoo kọkọ ni anfaani si abẹrẹ ajẹsara niiṣe pẹlu bi o ṣe pọn dandan si fun awọn eniyan, ti awọn onimọ nipa eto ilera si lewaju wọn.
- Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ Sunday Igboho, ṣùgbọ́n....- Oba Olugbọn
- Ẹ tú ìgbéyàwó wa ká, níṣe n'ìyàwó mi máa ń gbá mi létí- ọkùnrin kan sọ fún iléẹjọ́
- Irọ́ ni o! A kò tíì rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó lé ní 300 tí wọ́n jí gbé ní GGSS Jangebe - Ìjọba Zamfara
- Èèyàn 240 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ tún lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà
Ijọba ni awọn ti bẹrẹ si ni kọ awọn eleto ilera bi wọn yoo ṣe bẹrẹ si ni pin awọn abẹrẹ ajẹsara naa.
Bakan naa ni awọn ẹrọ amohuntutu ti wọn nilo ti wa ni pese kaakiri awọn ojuko ti wọn yoo lo.
Eyi ni igba akọkọ ti orilẹede Naijiria yoo ma gba abẹrẹ ajẹsara Coronavirus to to miliọnu mẹrin fun awọn araalu lati koju aarun naa.
Amọ orilẹede Naijiria ni orileede kẹta lẹyin Ghana ati Cote d'lvoire ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara naa ni ẹkun iwọ oorun ilẹ Afrika.
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tó tó 4 milionu yóò bàlẹ̀ sí Nàìjíríà
Orilẹede Naijiria yoo gba abẹrẹ ajẹsara covid -19 wọle si orilẹede yii bẹrẹ lati Ọjọ Keji, Oṣu Kẹta, ọdun 2021.
Akọwe ijọba orilẹ-ede Naijiria, Boss Mustapha lo kede bẹẹ ninu atẹjade ti wọn fi lede.
Mustapha ni Ajọ to n risi eto ẹkọ lagbaye, UNICEF ni yoo gba abẹrẹ ajẹsara naa wọle lati ileeṣẹ COVAX.
- Isinkan-Akure regent: Mo pa màálù, àgùtàn àti àwọn ètùtù míì kí ń tó di Adelé Oba ní Isinkan- Adelé Florence Aladetoyinbo
- Àwọn jàndùkú ajínigbé fẹ́ẹ̀ lù wá pa nínú igbó, ọ̀rọ̀ rèé lẹ́nu àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ìlú Kagara
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa Dawisu tí gómínà Kano yọ ní íṣẹ́ nítorí o sọ̀rọ̀ tako Ààrẹ Buhari
- Mo kọ̀ láti gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí bẹ̀rù ẹnikẹ́ni nítorí ìjà òmìnira ìran Yorùbá- Igboho
''Abẹrẹ ajẹsara wa kuro ni India ni Ọjọ Kini, Oṣu Kẹta, ọdun 2021 ni alẹ, ti yoo si de ilu Abuja ni ọjọ kẹji ni nkan bi aago mọkanla, ni iyalẹta.
'' A n reti bii miliọnu mẹrin abẹrẹ ajẹsara lati ileeṣẹ COVAX ''
''Kini Osu kẹrin to pe, a n rẹti bii abẹrẹ ajẹsara bii miliọnu ọgọta, ti yoo si ju bẹẹ lọ ki ọdun to pari.''
O damiloju pe oogun abẹrẹ ajẹsara naa yoo wa lati ileeṣẹ apoogun AstraZeneca, eleyii to dara lati gbe pamọ di igba ti wọn ba n fun awọn eniyan''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni ileeṣẹ to n risi ọrọ oogun ati ounjẹ lorilẹede Naijiria, NAFDAC ti buwọlu abẹrẹ ajẹsara AstraZeneca pe o dara lati lo ni orilẹede Naijiria.
Amọ akọwe ijọba Naijiria naa fikun un pe awọn ilana to de aarun Coronavirus naa yoo si wa ni ṣẹpẹ lẹyin abẹrẹ ajẹsara naa.

Oríṣun àwòrán, EPA
Bakan naa lo ni ida ogoji Naijiria ni awọn yoo fun ni abẹrẹ ajẹsara ni ọdun 2021, ti ida ọgbọn yoo gba ti wọn ni ọdun 2022.
















