Free Salihu Tanko Yakasai Dawisu: Lẹ́yìn o rẹ́yìn, gómínà Ganduje Kano yọ Dawisu ní íṣẹ́ nítorí o sọ̀rọ̀ tako Ààrẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Google
Ijọba ipinlẹ Kano ti sọ idi ti awọn fi yọ olubadamọran pataki fun gomina ipinlẹ Kano, Dawisu ti wọn yọ niṣẹ lẹyin to sọrọ tako ijọba.
Gomina ipinlẹ Kano, Umar Ganduje ni kosi ani-ani lori iyọninipo rẹ, o gbọdọ waye ni wara ṣeṣa.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ko mu iṣẹ rẹ bii iṣẹ nitori oun sọ ọrọ ara rẹ tako ijọba, eleyii to lodi si ofin awọn oṣiṣẹ ijọba.
- Mo kọ̀ láti gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí bẹ̀rù ẹnikẹ́ni nítorí ìjà òmìnira ìran Yorùbá- Igboho
- Mi ò gba kobo ní gbogbo ọ́dún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Osun - Aregbesola
- Èèyàn 341 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ tún lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà
- Wọ́n ní ọkọ̀ bàálù NAF tó mú ẹ̀mí ọmọ mi lọ l'Abuja ti lo ọdún 49 láyé - Bàbá Flight Sergent Olasunkanmi
Ijọba ipinlẹ Kano ni nitori naa ni awọn ṣe yọọ ni iṣẹ nitori ko tọ si lati bu ẹnu atẹ lu aarẹ Buhari.
Ọrọ ti Dawisu ti wọn yọ nipo kọkọ sọ tako ijọba loju ọpọ Twitter rẹ ni pe, igbẹsẹ ijọba lori ọrọ Endsars fihan pe Aarẹ Buhari ko naa ni aarẹ ilu.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Laipẹ yii lo tun sọ wi pe, ọrọ ijinigbe ojoojumọ yii fihan wi pe ijọba to wa lode ko kunjuwọn to.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Lara awọn ọmọ Naijiria to bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba ipinlẹ Kano nipa iyọnipo naa ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹri, Ayo Fayose.
Fayose ninu ọrọ rẹ ni eniyan nla ni Dawisu nitori o sọrọ soke tako ijọba aarẹ Buhari nitori o tẹle ẹtọ rẹ to ni labẹ ijọba tiwantiwa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ta ni Dawisu, olùbádámọ́ràn pàtàkì gómìnà Ganduje tí wọ́n ló sọnù?
Lẹ́yìn wákìtí mẹ́rìnélógún ti Salihu Tanko Yakasai tó jẹ́ olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún gónìmà Kano kọ sójú òpó Twitter rẹ̀ pé, ìjọba APC tí já àwọn ọmọ Nàìjíríà kùlẹ̀, ni ọpọ àwọn ènìyàn lórí Twitter tí n ke tantan pé, àwọn kò gbúro bábá ọlọ́mọ̀ mẹ́tà náà mọ láti bi wákàtí mẹ́rìnlá.

Oríṣun àwòrán, Instagram/dan_tanko
Kìí ṣe ìgbà àkọ́ka rèé tí olùbádámọ̀ràn pàtàkì náà yóò fi ojú òpó Twitter rẹ̀ @dawisu bu ẹnu àtẹ lu ìjọba, ní ǹkan bi oṣù mẹ́rìn ni wọ́n fún ni iwe lọ dúró nílé díẹ̀ náà, nítoró ó sọ pé, Aàré Buhari kò mójú tó ọ̀rọ̀ ìfẹ́hónúhàn EndSars bótitó àti bóti yẹ'.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Kano, DSP Abdullahi Haruna ti BBC bá sọ̀rọ̀ lati mọ̀ bóyá wọ́n gbọ pé wọ́n kò rí Salihu mọ́, sùgbọn ó ni kò sí ǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ báyìí.
" A ti gbọ́ ǹkankan nípa pé ó sọnù."
Bàbá Salihu to jẹ ilúmọ̀ọ́ká olóṣèlú, Tanko Yakasai sọ fun BBC pé, òun gbọ́ ìròyìn pé ọmọ oun wà ni ọgbà DSS.
"Ìròyìn tó tẹ̀ mí lọ́wọ́ báyìí ni pé, ọmọ mi wà lọ́dọ̀ àwọn DSS, ọ̀rọ tó sì wà nílẹ̀ kọjá pé ó kọ ǹkan sójú òpó Twitter lánàá"
" Gẹ́gẹ́ bi ẹbi, à sì n retí ǹkan ti yóò ṣẹ̀lẹ̀ ni oo, sùgbọn mo ní ìgbàgbọ pé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò ti bá àwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀".
"Sáájú àsìkò yìí ni mo ti sọ fún kó yé tako ọ̀rọ̀ ìjọba mọ́, nígbà tí ó kọ́ka kọ èyí ti ìjọba fi fún ni iwé lọ jòkó nílé, mo sọ fun pé, tó bá fẹ́ bú ìjọba, ko kúrò lórí ipò tó dìmú, nítorí níwọn ìgbà tí ó bá ti wà níjọba, wọ́n yóò ri gẹ́gẹ bi ẹsẹ̀ nla ni."
Bákan náà, Abubakar Sadeeq to n mojú tó àwọn ojú òpó ìkànsíraẹni f;un ìpínlẹ Kano fi idí rẹ múlẹ̀ lójú òpó Twitter pé Salihu wa ni ọgbà DSS lọ́wọ́lọ́wọ́.
BBC kan sí ìjọba ìpinlẹ̀ Kano, lásikò ti a pe kọmísọ̀nà ètò ìròyìn, Muhammed Garba láti sọ si ọ̀rọ náà sùgbọn kò gbé aago rẹ̀ bákan náà ni kò fèsì si àtẹ̀jísẹ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.
- Wo oríṣi oúnjẹ márùn ún tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn kan fẹ́ràn púpọ̀ ní Nàìjíríà
- Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé tó ti kópa nínú sáà ìjọba tiwantiwa láti ọdún 1999
- Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè (Customs) tẹ́lẹ̀ tó kú tí wọ́n fẹ̀sùn kíkó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù jẹ kan
- Fáàbàdà! Ìjọba ò sanwó fáwọn ajínigbé láti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé Kagara sílẹ̀- Lai Mohammed
Tani Dawisu?
Salihu Tanko Yakasai ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Dawisu lójú òpó Twitter jẹ́ olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún gómìnà Ganduje ìpínlẹ̀ Kano lori ètò ìròyìn.
Òun ni adarí ètò ìròyìn àti ìbáràẹni sọ̀rọ̀ ni ilé ìjọba Kano tẹ́lẹ̀rí.
Bákan náà lo ti fi ìgbà kan jẹ olùdásílẹ̀ ''Curator of Global Shapers Community'' ti World Economic Forum, ẹka ti ìpínlẹ̀ Kano.
Salihu Tanko jẹ oníròyin gẹ́gẹ́ bi ìṣẹ tó yàn láàyò lówùrọ̀ ọjọ́, o si ti n kọ ìròyìn fún CNN Politico àti Ynaija to jẹ iwe iroyin orí ayélujára.
O ti kawe ni Harvard tẹlẹ̀ rí, o si tú jẹ́ olóṣèlú abẹ́lé láti bi ogún ọdún sẹ́yìn.
- Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé tó ti kópa nínú sáà ìjọba tiwantiwa láti ọdún 1999
- Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè (Customs) tẹ́lẹ̀ tó kú tí wọ́n fẹ̀sùn kíkó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù jẹ kan
- Fáàbàdà! Ìjọba ò sanwó fáwọn ajínigbé láti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé Kagara sílẹ̀- Lai Mohammed
Bákan náà lo ma n ṣiṣẹ́ ìdàgbàsókè fún ìlú.
Nínú Oṣù Kéwàá, ọdún 2020, ìjọba ìpińlẹ̀ Kano ti dádúró lẹ́nu isẹ́ gẹ́gẹ́ bi olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún gómìnà, nítorí o bú ẹnu àtẹ lu ààre Muhammadu Buhari lójú òpó Twitter, pé irú ọwọ́ to fi mú ìfẹhónúhàn ọ̀rọ ìwóde EndSars ko dara tó.
Nínú àtẹ̀jáde ti kọmísọ́nà ètò ìròyìn, Muhammad Garba fí síta, lo tí sọ pé ọ̀kàn lara pàtàkì iṣẹ́ ìlú àti asojú ìjọba ni láti mọ irú ǹkan ti ènìyàn yóò máa kọ síta lórí ayélujára nítori pé, ó máa n dá wàhálà sílẹ̀.
Láìpẹ́ yìí ni ọkùnrin náà kọ sójú òpó Twitter rl pé, bí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ṣe n mu ọ̀rọ ètò ààbò ko dára tó bi àwọn ọ̀daràn ṣe n fi ojojúmọ ji ènìyàn gbé.
Abubakar to jẹ́ alábojúto àwọn opó ìkànsíraẹni ni ìpínlẹ̀ Kano fikdi rẹ múlẹ̀ pé, @diwasu wà ni gbaga àwọn ọtẹlẹ̀m'úyẹ́ DSS

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n mú Dawiksu? Ǹkan ti àwọn ọmọ Naijiria ń sọ nípa #FreeDawisu rèé
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíría ló ti bó sójú òpó Twitter lati fi ẹdun ọkàn wọn hàn pé àwọn àjọ DSS gbé ọkùnrin náà.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter






















