Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, Google
Ijọba ipinlẹ Osun ti ti ileẹ̀kọ́ Ifeoluwa Grammar School pa lẹyin ti awọn janduku ṣe ikọlu si ileẹ̀kọ́ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola to fi idi ọrọ naa mulẹ ni awọn ọdọ to le ni ogun lo yabọ ileẹ̀kọ́ naa pẹlu ada ati ọkọ ti wọn si da rogbodiyan silẹ.
Ọpalọla ni ipe pajawiri ni wọn pe oun, ni ileẹ̀kọ́ naa ti awọn si ko awọn ọlọpaa lọ si ileewe naa.
Opalola ni: ''A fi panpẹ mu afurasi kan pẹlu ada lọwọ, ati eleyii ti wọn ti sa ni ada ni apa ati ori.''
''Iwadii ṣi n lọ lọwọ, amọ o ṣeeṣe ki awọn janduku naa jẹ awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun.''
''Bakan naa ni a ti gbe awọn ti wọn farapa ninu iṣẹlẹ naa lọ si ileewosan ijọba ti Osogbo Central Hospital fun iwosan to peye.
Amọ, Adari ẹka ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ naa, Kehinde Olaniyan sọ wi pe awọn gbe igbesẹ lati ti ileewe naa pa, ki rogbodiyan ma bẹ silẹ nibẹ.
O ni awọn janduku ati awọn ẹlẹgbẹ okunkun ti wọn n ṣe bi akẹkọọ lo yabọ ileewe naa.
''A fẹ kesi awọn obi ati ojulumọ lati sọ fun wọn pe Kọmisọnna fun eto ẹkọ ti paṣẹ ki wọn ti ileewe Ifeoluwa Grammar School fun igba kan naa.;;
''Eyi ni lati ri wi pe omi alaafia ilu ko daru nitori awọn oni jagidijagan yii ti wọn n pe ara wọn ni akẹkọọ''
''Nitori naa ni a fi kesi awọn obi lati jẹ ki awọn ọmọ wọn duro silẹ, titi iwadii yoo fi pari.''
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Osun fikun wi pe awọn ti n tpasẹ awọn janduku naa, ti awọn yoo si fi wọn jofin laipẹ.















