Mọ́kálíkì dèrò ilé ẹjọ́ lẹyin tó jí ọkọ̀ gbé

Oríṣun àwòrán, Pixabay
Ọwọ palaba Abubakar mọkaliki segi nibi to ti fẹ ji ọkọ gbe lAbuja
Arakunrin mọkaliki kan, Abubakar Kelly, ti foju ba ile ẹjọ onipele kinni kan ni Mpape, l'Abuja lori ẹsun pe o fẹ ji ọkọ Toyota Highlander kan gbe.
Agbẹjọro ijọba to fẹsun kan an, D.F Abah sọ fun ile ẹjọ pe losu Kejila ọdun 2020 ni wọn mu Abubakar nibi to ti fẹ ji ọkọ naa ti wọn gbe kalẹ si bareke ologun Mogadishu to wa ni Asokoro gbe.
Abah ni Umar Mohammed to ni ọkọ naa mu ọrọ ọhun to ileesẹ ọlọpaa Asokoro leti.
Labẹ ofin, iwa ti Abubakar wu yi tapa si ofin Abuja, ti ijiya to tọ si wa fun.

Oríṣun àwòrán, Pixabay
Nigba ti Abubakar de iwaju adajọ, o ni oun ko jẹbi ẹsun naa.
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
- Alhaja Muslimot Salami tí àwọn darandaran kọlù ní Ogun tí padà jẹ́ Olorun nípè!
- Àìṣàtìpó rí ló ń da Ejiogbe láàmú, àsìkò ìjọba tèmi ló dé- Alhaji Mukaila Auxilliary
- Ṣé lóòtọ́ ni omidan yìí ya wèrè ní kété tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní òun fẹ́ fi ṣaya?
Adajọ Salihu Ibrahim si ti ni ki wọn gba oniduro rẹ pẹlu miliọnu meji Naira ati oniduro toun naa ni owo to to bẹẹ.
Wọn ti sun ẹjọ ọhun siwaju titi di ọjọ Kejilelogun, osu Keji, ọdun yii.



















