Tí Trump bá ṣèkọlù sí Iran, a ṣetán láti gbẹ̀san lára Amẹrika - Ìjọba Iran

Adari orilẹede Iran, Ayatollah Ali Khamenei, wọ aṣọ ibilẹ orilẹede rẹ, Donald Trump Amẹrika wọ kootu ati tai olomi buluu lọrun

Oríṣun àwòrán, EPA/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Adari ile igbimọ aṣofin orilẹede Iran, Mohammad Baqer Qalibaf, ti kilọ fun Aarẹ Donald Trump Amẹrika, wi pe ti o ba ṣekọlu si orilẹede naa; Iran naa yoo gbẹsan.

Qalibaf ni Iran naa yoo da a pada fun Amẹrika to ba le gbe igbesẹ lati ṣeranwọ fawọn oluwọde ti wọn n tako ijọba.

Adari ile sọ fawọn akẹgbẹ rẹ nile wi pe Iran ṣetan lati ṣe ikọlu si ibudo ologun Amẹrika to wa lẹkun Middle East ati si Israel, ti Amẹrika ba le ṣekọlu si Iran.

Lanaa ọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ kẹwaa oṣu Kinni yii ni Trump sọ loju opo X rẹ pe Amẹrika ṣetan lati ṣe iranwọ fawọn ọmọ Iran to n wa ominira.

Iroyin sọ pe Amẹrika ti pinnu nnkan ti yoo ṣe tawọn ẹṣọ eleto aabo ba le ṣekupa awọn olufẹhonuhan ni Iran.

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati Iran sọ pe ọpọ eeyan to n ṣe ifẹhonuhan lo ti farapa latari bawọn ẹṣọ eleto aabo ṣe n gbiyanju lati pana ifẹhonuhan ọhun.

Ijọba ṣetan lati jiroro pẹlu awọn olufẹhonuhan – Aarẹ Iran

Ẹwẹ, Aarẹ Masoud Pezeshkian orilẹede Iran ti sọ pe ijọba oun ti ṣetan lati jiroro pẹlu awọn olufẹhonuhan lati mọ nnkan ti wọn n beere fun gan an.

Nigba to n sọrọ lori ẹrọ tẹlifisan, Aarẹ Pezeshkian sọ pe awọn alatako oun lo wa nidi rogbodiyan to n ṣẹlẹ lọwọ yii ni Iran.

Aarẹ Pezeshkian sọ iyatọ to wa laarin awọn olufehonuhan toootọ ati awọn ayederu oluwọde.

Aarẹ ni agbesunmọmi lawọn to n pe ara wọn ni oluwọde ṣugbọn ti wọn n da rogbodiyan silẹ kaakiri orilẹede Iran.

Lara nnkan tawọn oluwọde n se ifẹhonuhan le lori ni iṣoro to n koju eto ọrọ aje Iran.

Ọpọ lo si ti n pe fun ki ijọba islam to wa lode lorilẹede Iran wo lulẹ lati igba ti ifẹhonuhan naa ti bẹrẹ.