Kókó nǹkan méje tí Chimamanda ń béèrè lọ́wọ́ ilé ìwòsan Euracare lórí ikú ọmọ rẹ̀

Chimamanda Adiche wọ aṣọ ankara, o si di irun to rẹwa

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Jeff Overs

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ogbontarigi onkọwe n ni, Chimamanda Adiche, ti fun Ile ìwòsan Euracare lọjọ meje lati pese gbogbo àkọsílẹ tí wọn bá ni lori ọmọdekunrin rẹ, Nkanu Nnamdi, to ku sile iwosan naa niluu Eko.

Adiche fẹsun kan ile iwosan Euracare pe iwa aibikita awọn oṣiṣẹ ile iwosan ọhun lo jẹ ki ọmọ oun, Nkanu ku.

Amọ, ile iwosan naa sọ pe ọrọ ko ribẹ rara.

Chimamanda sọrọ yii lẹyìn tó kede lọjọ keje oṣù Kínní yii pe Nkanu ti kú sile iwosan Euracare.

Gbajugbaja onkọwe naa sọ pe ile iwosan Euracare kùnà láti ṣe àwọn nnkan to yẹ kí wọn ṣe lasiko toun gbe Nkanu debẹ fun itọju.

Iroyin sọ pe awọn dokita lati ile iwosan Atlantis lo ni kí wọn gbe ọmọ naa lọ sí Euracare fun ayẹwo kan ti o nilo ki o le lanfaani lati rìnrìn àjò lọ sí oke okun fun itọju tó péye.

Amọ, lasiko ti wọn n se eleyii lọwọ ni ọmọ naa ku.

Ileeṣẹ amofin Kemi Pinheiro to jẹ agbẹjọro fun ẹbi Chimamanda ti fi iwe oniruuru ẹsun ti ẹbi naa fi kan ile iwosan ọhun ranṣẹ sí wọn.

Ẹbi ọmọ naa sọ pe ẹni tó fún un ní abẹrẹ iṣẹ abẹ at'awọn oṣiṣẹ míi nile iwosan naa ṣe oniruuru aṣiṣe.

Chimamanda tun fẹsun kan ile iwosan naa wi pe wọn o ni awọn irinṣẹ ti wọn fi le ji alaisan to bá dákú.

Bakan naa lo tun sọ pe wọn o tẹle ilana lori gbigbe alaisan lati ile iwosan kan si omiran.

Ẹbi Nkanu tun sọ fún ile iwosan Euracare pe ki wọn tọju gbogbo ẹri lori nnkan to sẹlẹ pamọ.

Ẹbi naa tun beere fún fídíò CCTV to ṣafihan bi wọ́n ṣe n gbe ọmọ naa lati wọọdu kan sí omiran nile iwosan ọhun.

Àwọn mọ̀lẹ́bí Chimamanda Ngozi Adichie ní àìbìkítà ilé ìwòsàn ló fa ikú ọmọ rẹ̀

Chimamanda Ngozi Adichie

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn mọlẹbi onkọwe agbaye nni, Chimamanda Ngozi Adichie, ti fẹsun kan ile iwosan aladani kan niluu Eko lẹyin iku ọmọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun kan ati oṣu mẹsan an.

Ọmọdekunrin naa, Nkanu Nnamdi ku sile iwosan niluu Eko lẹyin aisan ranpẹ, eyii to da omi tutu sọkan awọn mọlẹbi rẹ.

Awọn mọlẹbi ọhun ti fẹsun kan ile iwosan Euracare pe aibikita wọn lo ṣokunfa iku ọmọ kekere jojolo naa.

Lara ẹsun ti wọn fi kan ile iwosan naa ni pe wọn ko fun oloogbe ni afẹfẹ 'oxygen' to yẹ ko mi simu bẹẹ ni wọn tun fun ni oogun orun to pọ lapọju, eyii to mu ki ọkan rẹ ṣadede kọṣẹ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti fi erongba wọn lede lẹyin iṣẹlẹ naa ti pupọ ninu wọn so pe 'Naijiria ti ṣẹlẹ' si ọmọ ọhun.

A ba mọlẹbi kẹdun amọ a ko ṣe aibikita kankan – Ile iwosan Euracare

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, ile iwosan Euracare ti ọmọde naa ku si sọ ninu atẹjade kan pe awọn oṣiṣẹ oun ko ṣe aibikita kankan to yọri si iku ọmọ naa ṣugbọn awọn ba awọn mọlẹbi Adichie kẹdun.

Ile iwosan naa ni awọn akọṣẹmọṣẹ oṣiṣẹ lo n tọju awọn alaarẹ lọdọ oun, awọn oṣiṣẹ naa si n ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bii awọn ojugba wọn mii lagbaye.

Atẹjade Euracare ṣalaye pe aisan to n ṣe ọmọ naa ti wọ ọ lara daadaa ki wọn to gbe de akata oun amọ iwadii n lọ lọwọ lati mọ ọfintoto ohun to gbẹmi rẹ ni pato.

Mọlẹbi ọkọ Adichie, Anthea Nwandu, sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ Arise TV pe ọga agba ile iwosan naa sọ fun Adichie pe "oogun orun ti wọn fun ọmọ naa ti pọ ju' eyii to mu ki ọkan rẹ ṣadede kọṣẹ.

Nwandu tun fẹsun kan oṣiṣẹ ile iwosan naa pe wọn fi ọmọ ọhun silẹ lai tọju rẹ, wọn ko fun ni afẹfẹ oxygen, bẹẹ ni wọn ko gbe bo ṣe yẹ ki wọn gẹgẹ bii ilana itọju awọn alaarẹ.

Mọlẹbi naa sọ pe airi afẹfẹ oxygen mi simu lo ṣakoba fun ọpọlọ ọmọ naa to fi tete dakẹ.

Ọmọ to dagbere faye naa jẹ ọkan lara awọn ibeji ti Adichie bi fun ọkọ rẹ, Ivara Esege.

Laarin wakati mẹrinlelogun ti ọmọ naa dele iwosan lo dagbere faye.

Ijọba ipinlẹ Eko bẹrẹ iwadii

Wayi o, ijọba ipnlẹ Eko ti sọ pe oun yoo gbe iwadii dide lẹyin iku ọmọ naa.

Olubadamọran pataki si gomina ipinlẹ Eko lori eto ilera, Kemi Ogunyemi, sọ ninu atẹjade kan pe ijọba ipinlẹ naa ti bẹrẹ iwadii kiku lori iṣẹlẹ ọhun.

O ni "ẹnikẹni tabi ileeṣẹ ki ileeṣẹ to ba jẹbi aibikita tabi tapa si ofin bo ṣe yẹ ko ṣiṣẹ yoo foju wina ofin."

Lẹyin naa lo rọ awọn araalu ki wọn ṣọra fun aheso ọrọ lasiko ti iwadii naa n lọ lọwọ.