“Lẹ́yìn ọdún méjì tí ogun lé mi kúrò ní Ukraine, mo ṣetán láti padà síbẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ mi”

Oríṣun àwòrán, Courtesy of Haifa Juma
- Author, Esther Kahumbi
- Role, BBC News
Inu oṣu Kẹsan an, ọdun to kọja ni Haifa Juma pinnu lati pada si orilẹ-ede Ukraine lati tẹsiwaju ẹkọ imọ eto ilera rẹ lẹyin ti ogun le kuro nibẹ lọdun meji sẹyin.
Ọmọ orilẹ-ede Tanzania naa ni o ṣoro fun oun lati pada, nitori oun ko mọ ohun ti oun yoo ba nibẹ latari pe ogun ṣi n lọwọ amọ oun pinnu lati pada.
Oṣu yii gan lo pe ọdun meji gbako ti orilẹ-ede Russia kogun lọ ba Ukraine.
Nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgbọn araalu lo ti ba ogun naa lọ nigba ti ọpọ di alairilegbe.
Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Juma.

Oríṣun àwòrán, AFP
Gẹgẹ bii awọn akẹgbẹ rẹ lati orilẹ-ede mii, Haifa sa kuro lorilẹ-ede naa latari ogun to bẹ silẹ nibẹ.
O gba akẹkọọ ọhun ni ọpọlọpọ oṣu ki awọn obi rẹ to yi ọkan wọn pada pe ko pada silẹ naa fun itẹsiwaju ẹkọ rẹ ọhun.
O ni “Ori ẹrọ ayelujara ni mo ti n ka iwe mi lati Tanzania, mo si ti pari awọn to jẹ alakọsilẹ, ki n si to le yege, mo ni lati sẹ ipele to kan, eyii ti mo gbọdọ ṣe lojukoju. Mmo ni lati wa nibẹ.
“Awọn ẹbi mi ti na obitibiti owo lori ẹkọ mi, mi o si le duro lai ṣe nnkankan titi ti ogun yoo fi pari.
Ipele kẹrin ni Haifa wa bayii nile ẹkọ Sumy State University, ireti si w ape yoo oari ẹkọ rẹ lọdun 2027 ni ẹka imọ gynaecology.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ Centre for International Education (USCIE) ni Ukraine ni oun ko le sọ ni pato bayii iye akẹkọọ to ti pada wọ ile naa pada lati ilẹ adulawọ fun itẹsiwaju ẹkọ wọn.
Ṣaaji ogun naa, nnkan bii ẹgbẹrun mẹrindinlogun akẹkọọ lati Afrika lo n kawe ni Ukraine.
Lọwọ yii, ẹgbẹrun marun un abọ akẹkọọ lati Afrika lo n kawe ni Ukraine, ti ọpọ ninu wọn si wa lati Morocco, Nigeria atiTanzania.
Agbẹnusọ USCIE sọ fun BBC pe awọn akẹkọọ naa funra wọn ni wọn pinnu lati pada si Ukraine.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹkọ lati ori ayelujara
Lodi si igbesẹ Haifa yii, ọpọ awọn ọmọ ilẹ adulawọ ni ko fẹ pada si Ukraine mọ.
Ṣaaju ogun, ẹgbẹrun mẹrindinlogun akẹkọọ lati Afrika lo n kawe ni Ukraine kaakiri orilẹ-ede naa.
Wayi o, igbagbọ wa pe nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa ninu awọn akẹkọọ naa ti ogun le kuro nibẹ ni ko fẹ pada mọ.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn akẹkọọ naa lo pada silẹ baba wọn ni Afrika, awọn mii ti gba awọn ilẹ Yuroopu miran lọ.
Lara awọn orilẹ-ede mii ti wọn lọ ni Netherlands, Portugal ati Finland.

Oríṣun àwòrán, AFP
Akẹkọ mii, Aisha, n gbiyanju lati kawe ni Netherlands lẹyin to kuro ni Ukraine amọ o ṣoro.
Eyii ko ṣẹyin bi ijọba orilẹ-ede naa ṣe sọ pe gbogbo akẹkọọ gbọdọ ni iwe irinna akẹkọọ ‘student visa’ ki wọn to le maa gbe nilẹ na.
Bo tilẹ jẹ pe Aisha ti wa ni ipele karun un ṣaaju ogun Ukraine, ti ko ba ri iwe irinna akẹkọọ naa gba, yoo ni lati pada si Naijiria nibi ti yoo ti ṣoro fun lati tẹsiwaju.
Gẹgẹ bii ohun ti ẹni ọdun marundinlọgbọn naa sọ, ko ṣetan lati pada si Najiria, bẹẹ si ni ko fẹ pada si Ukraine.
Amọ o ni iwa ti wọn n wu si awọn nibi ti oun wa ko ṣe e fẹnusọ nitori o buru jọjọ.

Oríṣun àwòrán, Courtesy of Isaac Awodola














